INEC: Ọjọ́ Satide ọ̀sẹ̀ yì ni ìdìbò gbogboògbò yóò wáyé.

Oríṣun àwòrán, AFP
Ile isẹ Ajọ to n bojuto eto idibo lorilẹede Naijiria, INEC ni ipinlẹ Plateau ti gbana ti ọpọlọpọ ohun elo idibo si baa lọ.
Ọjọ Satide ọsẹ yii ni idibo gbogboogbo yoo waye.
Ile isẹ INEC ni ipinlẹ naa ninu atẹjade ti wọn fi lede sọ wi pe gbogbo ohun to wa ni inu ile naa lo jọna patapata.
Adari eto iforukọsilẹ ati ipolongo fun Ajọ INEC ni ipinlẹ naa, Osaretim Imaehorobo to fi ọrọ naa mulẹ, sọ wi pe asọle ọmuti kan lo fa ijamba ina naa, ati wi pe iwadii n tẹsiwaju lori isẹlẹ naa.
INEC: Ẹ tètè forúkọ àwọn aṣojú ẹgbẹ́ yín sílẹ̀ láàrin ọjọ́ kan, bí bẹ́ẹ̀ kọ́...
Ajọ eleto idibo INEC ti ni awọn ko ni gba orukọ awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu ti ko ba tẹle ilana ofin ṣaaju eto idibo.
Ọsẹ kan niyii lẹyin ti gbedeke ti ajọ INEC fun wọn ti pe lati forukọ awọn ti yoo ṣoju ẹgbẹ oṣelu kọọkan ni ibudo idibo fun ti idibo aarẹ ati awọn aṣofin agba.
Nitorinaa, loju opo Twitter ajọ INEC, wọn ti ni awọn ti ko ba tii mu orukọ ati ohun gbogbo to yẹ ko kun un fun iforukọ silẹ awọn aṣoju wọn, ki wọn rii pe wọn ṣe bẹẹ ki ago iṣẹ ijọba to pari lọjọ aje ọjọ kọkanla oṣu keji.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Bakan naa, fun iforukọsilẹ awọn aṣoju ti idibo gomina ati awọn aṣojuṣofin ipinlẹ, aṣoju ajọ INEC ni awọn diẹ lo tii ṣe gẹgẹ bi ilana ofin.
Lafikun, INEC sọ pe awọn orukọ mii ti wọn fi sọwọ ni ko ni aworan ati ibuwọluwe awọn aṣoju naa eyi ti ofin beere fun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ikilọ ajọ INEC yii waye nilu Abuja lọjọ abamẹta nibi ti oludari agba ẹka iroyin ati ẹkọ fun awọn oludibo ni ajọ INEC, Ọgbẹni Festus Okoye sọ pe nibi ipade plua awọn alaga ipinlẹ, awọn ṣe agbeyẹwo igbaradi wọn fun idibo gbogbogbo ti yoo bẹrẹ lọjọ kẹrindinlogun oṣu keji ti yoo si pari ni ọjọ keji oṣu kẹta ọdun 2019.
Nibi ipade naa ni wọn ti tun jẹ ko di mimọ fun awọn ẹgbẹ oṣelu ohun ti ofin sọ nipa iforukọsilẹ orukọ awọn aṣoju wọn.













