Ọwọ́ tẹ afurasí olórí ikọ́ ISWAP tó lọ́wọ́ nínú ìkọlù sí ilé ìjọsìn Owo, l'Ondo

Aworan lati ikọlu Owo

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ikọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ti mu ọkan gboogi olori ikọ agbebọn ISWAP to lọwọ ninu ikọlu ọjọ Karun un oṣu Keji ọdun 2022 si ile ijọsin Aguda St Francis ni Owo nipinlẹ Ondo.

Afurasi naa, ni wọn pe orukọ rẹ ni Sani Yusuf, to si jẹ afurasi kẹfa ti ọwọ tẹ pe wọn ni nnkan ṣe pẹlu ikọlu to gba ẹmi ogoji eeyan, ti ọpọ si tun farapa.

Awọn afurasi to wa ni atimọle DSS bayii ni — Idris Omeiza (25), Al Qasim Idris (20), Jamiu Abdulmalik (26), Abdulhaleem Idris (25), ati Momoh Otuho Abubakar (47) — fun ẹsun pe wọn lọwọ ninu ikọlu to ṣekupa ọpọ eeyan.

Ileeṣẹ momaworan orilẹede Naijiria, NTA ni DSS ṣalaye pe ọwọ tẹ afurasi naa ni ilu Iguosa ni ijọba ibilẹ apa ariwa Ovia nipinlẹ Edo.

Yoo pe ọdun mẹrin bayii, ti awọn agbebọn kọlu ile ijọsin kan niluu Owo, nipinlẹ Ondo, nibi ti wọn ti ṣeku pa eeyan to le ni ogoji, ti ọpọ si tun farapa.

Awọn agbebọn naa kọlu ile ijọsin St. Francis Catholic Church, ni owurọ ọjọ isinmi, ọjọ karun-un, oṣu Kẹfa, ọdun 2022, lasiko ti ijọsin n waye.

Lẹyin ọdun meji, awọn ti iṣẹlẹ naa kan ẹbi wọn, ijọ Ọlọrun, ati ilu Owo, ṣi n beere fun idajọ ododo.

Oore-ọfẹ ni alufaa n ṣe lọwọ nigba ti iro ibọn akọkọ dun. Adura oore-ọfẹ to si yẹ ko jẹ adura ipada lọ sile lẹyin isin, pada di adura a gba lọ si ọrun fun ọpọ ọmọ ile ijọsin St Francis Catholic Church, niluu Owo.

Ado oloro dynamite ti awọn agbebọn to yabo ile ijọsin naa fi fọ ilẹkun ṣọọṣi ọhun ni nnkan bi aago mọkanla aabọ owurọ ọjọ isinmi ọhun lo fa ere a sa pajude, ẹni ori yọ, o di le.

Bi awọn eeyan ṣe n gbiyanju lati sa jade, ni wọn n ko awọn agbebọn lọna, bẹẹ ni iro ibọn tun n dun lakọ-lakọ.

Awọn ti isẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe, ko din ni aadọta oku eeyan ti awọn ka, lara eyi ti awọn ọmọde ati arugbo wa.

Ọpọ farapa, bẹẹ ni ẹjẹ n ṣan bi omi lori pẹpẹ ati ilẹ ile ijọsin naa.