Wo nǹkan tí Tunji Disu sọ lẹ́yìn tó gba ọ̀pá àṣẹ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Naijiria

Oríṣun àwòrán, Bayo Onanuga
Adele ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa tuntun, Tunji Disu, ti koroju si bi awọn eeyan ṣe n ki i ku oriire lẹyin ti Aarẹ Bola Tinubu yan na sipo naa.
Disu ni asiko ko tii to fun ikini ku oriire bayii nitori ẹru to wa ni ejika oun pọ lasiko yii, ti oun si ni lati bẹrẹ iṣẹ lẹsẹ kẹsẹ.
O sọ eyi kete ti Aarẹ Tinubu wọ aṣọ fun un gẹgẹ bii ọga agba ọlọpaa kẹtalelogun fun ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ni Ọjọbọ, ọjọ kẹdọgbọn oṣu Keji ọdun 2026.
Disu lo rọpo Kayode Egbetokun, ẹni to kọwe fipo rẹ silẹ lati le mojuto ẹbi rẹ.
Wo awọn nnkan ti Disu sọ pe oun fe ṣe gẹgẹ bii Ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa
Tunji Disu ni o ṣe koko fun oun lati fọwọ sowọ pọ pẹlu Aarẹ Bola Tinubu ati awọn araalu lati ri pe aabo to peye wa fun ẹmi ati dukia fun gbogbo ọmọ orilẹede Naijiria pata.
Disu ni bi awọn eeyan ṣe n ki oun ku oriire ni oun koroju si nitori iṣẹ to pọ wa ni ejika oun.
"Mo gbagbọ pe asiko ko tii to lati maa gba atẹjisẹ oriire nitori ẹru to wa lọrun mi ati awọn yooku mi pọ.
"Asiko yii kọ nitori a gbọdọ ri pe a ṣe ohun to yẹ, a ni lati ṣe kọja nnkan ti wọn ni ki a ṣe."
Disu tun jẹ ko di mimọ pe oun fẹ ki awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa mọ pe Tunji Disu, ti ọpọ ma n pe oun, kọkọ jẹ ọlọpaa ko to di pe o di ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa Niajiria.
O tẹsiwaju pe oun mọ pe ọpọ iṣoro lo n ba awọn ọlọpaa Naijiria finra, bi awọn araalu ko ṣe fi ọkan tan wọn, iṣe atijọ, bi ko ṣe ohun ija to peye ati pe bi awọn ibi kan, ọpọ nnkan ti ko da tib a orukọ ileeṣẹ ọlọpaa jẹ.
"Awọn nnkan yii jẹ nnkan ti a ni lati koju pẹlu erongba pe a o tun ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Naijiria ṣe, ti a o si ni afikun awọn ọlọpaa ti araalu le fi ọkan tan."
Disu wa ṣe ileri mẹta wi pe "a o gbe ileeṣẹ ọlọpaa lọ sibi to yẹ ko wa ni ti igbalode.
Bi a o ṣe maa ṣe iṣẹ wa ni yoo kun fun ọpọ iwadii to muna doko, lilo ẹrọ igbalode ati ẹri ti yoo ran igbesẹ wa lọwọ.
"A o ri pe irọnu de ba awọn to n ṣe iṣẹ yii, ọlọpaa to lọgbọn, to n ṣe iṣẹ lasiko, lo jẹ ohun agbara ti nilo lati dena de iwa ibajẹ.
"Mo fẹ fi nnkan da yin loju, asiko ti nnkan yoo kan lọ lai si iwadii ti dopin.
Asọ wa yi wa fun igbagbọ araalu, ẹnikẹni to ba ṣe ohun to kọja ofin yoo rija ofin."
Mọ mọ awọn nnkan to ti Disu gbe ṣe – Tinubu
Aarẹ Bola Tinubu ni oun gbe igbesẹ lati yan Tunji Disu gẹgẹ bii ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa nitori oun mọ awọn iṣẹ to ti ṣe ati iha to kọ si bi o ṣe ti ma n ṣe iṣẹ rẹ.
Tinubu ni oun mọ ipa Tunji Disu nigba to n ṣiṣẹ niluu Eko lasiko ti oun jẹ Gomina ipinlẹ naa.
"Jẹ olori rere, ri daju pe aabo wa fun ẹmi ati dukia araalu . Mo mọ pe o le ṣe eyi, o si ni atilẹyin mi."
Awọn iṣoro wo lo wa niwaju Tunji Disu?
Gẹgẹ bii Tunji Disu ṣe sọ lasiko to n sọrọ lẹyin ti Aarẹ Tinubu wọ aṣọ fun ni pe oun yoo ri pe awọn araalu ni igbagbọ ninu ileeṣẹ ọlọpaa lasiko rẹ.
Eyi awọn iṣoro ti Tunji Disu yoo ma koju
- Eto idibo 2027
Idanwo akọkọ fun Tunji Disu lo jẹ eto idibo gbogbo ti ọdun 2027. Disu ni lati ri pe gbogbo ọmọ ogun ileeṣẹ ọlọpaa kaakiri Naijiria lo ti gbaradi ṣaaju eto idibo yii lati le jẹ ki eto idibo naa lọ lai si wahala tabi rogbodiyan .
Ẹ ma gbagbe pe eto idibo ipinlẹ Osun ati Ekiti naa yoo waye ṣaaju eto idibo gbogbo ti ọdun 2027.
- Owo oṣu awọn ọlọpaa
Ni ọdun 2018, aarẹ ana, Oloogbe Buhari fi owo kun owo oṣu ileeṣẹ ọlọpaa ṣugbọn iwọde si n waye. Ọpọ ipe lo ti jade pe ki afikun de bao wo oṣu awọn ọlọpaa.
Tunji Disu ni lati ri pe eyi waye fun ileeṣẹ ọlọpaa lasiko rẹ.
- Ki araalu fi ọkan tan ọlọpaa
Ọpọ eeyan lo gbagbọ pe o yẹ ki ileeṣẹ ọlọpaa da wa lati le ṣe iṣẹ wọn daada lai si pe wọn ṣe magomago
Tunji Disu ni lati wa ọna abayọ ti yoo fi ọkan araalu balẹ lori ileeṣẹ ọlọpaa.
Akọsẹmọṣẹ nipa aabo, Auwal Durimin Iya ni iṣoro meji ni Tunji Disu yoo koju.
O ni ohun akọkọ ni ifọkantan ati eto aabo lorilẹede Niajiria

























