Afurasí mẹ́fà tó ń ṣe ayédèrú iṣẹ́ ìyanu kó sí gbaga ọlọ́pàá l'Ondo

Oríṣun àwòrán, Police ondo state/ getty images
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti tẹ afurasi mẹfa lori ẹsun wi pe wọn n ṣe ayederu iyanu niluu Idanre nipinlẹ naa.
Ọjọ kẹrindinlogun oṣu Keji lawọn ọlọpaa fọwọ ofin mawọn eeyan naa lẹyin iṣẹ iwadii ti wọn ṣe.
Orukọ awọn afurasi naa ni Fadahunsi, Kolade, Tijani, Iyanuoluwa, Arijesulola ati Ademola.
Iroyin kan fidi rẹ mulẹ pe awọn mẹfẹẹfa fun ara awọn ni iṣẹ, ti gbogbo wọn si jọ n ṣiṣẹ pọ.
Iwadii ọlọpaa yoo to fi han iye awọn eeyan ti wọn ti lu ni jibiti ati awọn eeyan mii to n ṣiṣẹ pọ pẹlu wọn.
Awọn afurasi mẹfa naa si wa latimọle ọlọpaa, wọn o foju ba ile ẹjọ laipẹ lẹyin ti ọlọpaa ba ti pari iwadii lori ọrọ naa.
Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọndo ti rọ araalu wi pe ki wọn ṣọra fawọn eeyan to n ṣe ayederu iyanu lati fi le tu araalu jẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa rọ araalu pe ki wọn kiye sara ti ẹnikẹni ba beere owo lọwọ wọn fun iṣẹ iyanu.
Ọlọpaa ni ki wọn mu ẹjọ iru eeyan bẹẹ lọ si agọ ọlọpaa to ba sun mọ wọn.
Ileeṣẹ ọlọpaa wa sọ pe awọn ko ni beṣu bẹgba lati ri pe awọn ọdaran nipinlẹ Ondo foju wina ofin.
























