Kí ló ṣẹlẹ̀ láàárín Wale Akorede Okunnu àti Olasco Films tí wọ́n fi ń tahùn síra lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún?

Oríṣun àwòrán, Wale Akorede Okunnu
Gbas-gbos ti n waye laarin gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Wale Akorede, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Okunnu, ati gbagbajugba oniṣowo fiimu, Olasco Films.
Okunnu fi ẹsun kan Olasco Films pe ko fun oun lowo fiimu kan ti wọn ya lọpọ ọdun sẹyin.
Amọ oniṣowo fiimu naa ti sọ pe ọrọ ko ri bẹẹ latari pe oun ko jẹ Okunnu lowo kankan.
Bi gbas-gbos naa ṣe bẹrẹ
Ọrọ naa bẹrẹ lẹyin ti Okunu sọ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu Olugbenga Oropo Valentine lori eto Saworo pe Olasco ko san owo fiimu kan ti oun gbe jade lọpọ ọdun sẹyin fun oun.
Gẹgẹ bii Okunnu ṣe sọ, Olasco kọ lati fun oun lowo ilaagun oun lẹyin iṣẹ naa.
Wale Akorede sọ pe oun loun kọ fiimu naa, oun loun dari rẹ, koda oun loun tun ko ipa to ṣe pataki julọ ninu rẹ amọ oun ko gba owo kankan lori fiimu ọhun.
O ni "Emi ti ṣe fiimu fun Olasco to jẹ pe omi naira marun un mi o mu (lori owo ti wọn pa lori rẹ) titi di oni yii.
"Emi ni mo kọ, emi ni mo gbe jade, emi ni mo ko ipa to ṣe pataki ju ninu rẹ. Nigba ti yoo jade, apa kinni ati apa keji lo jade.
"Ti mo ba wa ni mo pa naira kan ninu oogu oju mi, irọ ni mo pa, koda mo tun jẹ gbese ni."
Fidio irọfọwerọ naa milẹ titi lori ayelujara ti ọpọ awọn ololufẹ Okunnu si n sọ erongba wọn lori rẹ.
Alaimoore ni Okunnu, miliọnu meji naira ni mo fun – Olasco
Wayi o, Olasco funra ti fesi pada fun Okunnu pe ọrọ ko ri bo ṣe sọ.
Ninu ifọrọwerọ miran lati wẹ orukọ ara rẹ mọ ni Olasco ti sọ pe irọ ni Okunnu pa mọ oun, koda o ni miliọni meji naira loun fun Akorede fun iṣẹ naa ṣaaju ki wọn to bẹrẹ,
O ni Mr Latin gan loun fẹ lo fun fiimu ọhun ki wọn to pada lo Okunnu fun ere naa.
O ni "Lẹni ti mo ko miliọnu meji naira fun lati lọ fi ṣe fiimu... oun lo gba owo lọwọ mi, miliọnu meji naira, lati lọ fi ṣe fiimu wa fun mi."
Olasco ni kii ṣe pe Wale Akorede lo gbe owo fiimu naa silẹ, amọ oun funra oun loun gbe owo kalẹ pe ko ṣe fiimu fun oun.
Lẹyin gbogbo gbas-gbos yii, Okunnu ti sọ pe oun ṣi maa tu kulẹkulẹ ohun to ṣẹlẹ lori fiimu naa ti asiko ba ti to.

























