Ajìjàgbara Yoruba Nation kú sí àhámọ́ n'Ibadan, àwọn mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n míì fojú ba ilé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, Others
Ọkan lara awọn ajijagbara to n pe fun idasilẹ orilẹede Yoruba, Ọgbẹni Adejumo Lateef, ni a gbọ pe o ti kun si ahamọ bayii nigba tawọn mẹtadinlọgbọn mii farahan nile ẹjọ giga to wa lagbegbe Ring Road, niluu Ibadan l’Ọjọru.
Awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn lo sọ fun ile ẹjọ nipa iku Ọgbẹni Lateef ṣaaju ifarahan awọn yoku rẹ.
Oloogbe naa ni olujẹjọ kejidinlogun ninu ẹjọ to n lọ laarin ipinlẹ Oyo ati awọn ajijagbara Yoruba Nation.
Awọn eeyan naa n jẹjọ lori ẹsun wi pe wọn yabo ile ijọba ipinlẹ Oyo l’Agodi niluu Ibadan lọjọ kẹtala oṣu Kẹrin ọdun 2024 yii lati kede idasilẹ orilẹede Yoruba.
Lara awọn ti wọn jọ n jẹjọ ni Adeyemo Peter, Adeyemo Joseph, Amos Ogundeji, Ayanwale Rofiat, Olalere Mathew, ati Ismaila Peter.
Ẹsun onikoko marun-un ni wọn fi kan awọn ajijagbara Yoruba Nation naa
Ẹsun onikoko marun un to da lori lilo ibọn lai gbaṣẹ lọwọ ijọba, igbimọpọ lati ditẹ mọ ijọba ati ikorajọpọ to lodi sofin ni wọn fi kan wọn.
Ẹjọ naa eyi ti ijọba ipinlẹ Oyo pe ti Ọgbẹni S.O. Adeoye si jẹ adari igbimọ olupẹjọ fun ni ijọba sọ pe ohun tawọn ajijagbara naa ṣe lodi si ẹka 37(2) iwe ofin ipinlẹ Oyo ọdun 2000.
Igbẹjọ ko le bẹrẹ nigba ti ijọba gbe awọn ajijagbara naa lọ ile ẹjọ tori ọpọ ninu wọn ni ko ni agbẹjọro to le ṣoju wọn nile ẹjọ.
Lẹyin o rẹyin, amofin Adebola Ogungbe lo ṣoju olujẹjọ kẹta, ikẹrin, ikẹsan an ati olujẹjọ kejila.
Amofin Toluwase Ogundeji lo ṣoju olujẹjọ kẹẹdogun ni tiẹ.
Amọ, amofin Yomi Ogunmola ati S.A. Sanmi fi ara wọn silẹ lati ṣoju awọn olujẹjọ miran ti wọn ko ri agbẹjọro ti yoo ṣoju wọn nile ẹjọ.
Awọn olujẹjọ kẹfa, ikẹtalelogun ati ikẹrinlelogun sọ fun ile ẹjọ wi pe awọn yoo ba ẹbi awọn sọrọ na kawọn to le gba agbẹjọro ti yoo ṣoju awọn nile ẹjọ.
Ninu idajọ rẹ, adajọ K.B. Olawoyin sun igbẹjọ olujẹjọ kẹfa, ikẹjọ ati ikẹtala siwaju.















