Àlàyé mi rèé lórí ìdí tí mo ṣe kọ́wé sí UK àti ìdúnkookò tí ìjọba àpapọ̀ ṣe lórí rẹ̀ - Sunday Igboho

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Gbajúmọ̀ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ìdásílẹ̀ orílẹ̀ èdè Yoruba Nation, olóyè Sunday Adeyemo tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Sunday Igboho ti sọ fún ìjọba láti má fún ogun mọ́ aṣojú orílẹ̀ èdè United Kingdom, UK sí Nàìjíríà, Richard Montgomery lórí ìwé ẹ̀sùn tí òun kọ sí ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

Ní òpin ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni Sunday Igboho kọ ìwé ẹ̀sùn alábala mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n sí ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lórí ìdásílẹ̀ Yoruba Nation tó ń bèèrè fún.

Ọfíìsì olóòtú ìjọba UK, Keir Starmer tó wà ní ojúlé Kẹwàá, òpópónà Downing ní ìlú London ni Sunday Igboho gbé ìwé náà lọ.

Lẹ́yìn tí Sunday Igboho ṣàgbékalẹ̀ ìwé ẹ̀sùn náà ni Mínísítà fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèrè Nàìjíríà, Yusuf Tuggar ránṣẹ́ pe Montgomery láti wá ṣàlàyé òun tí ìwé ẹ̀sùn náà túmọ̀ sí.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ Tuggar fi síta ní Montgomery ní ìwé ẹ̀sùn Sunday Igboho kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ àti pé ipa rẹ̀ kìí ṣe ohun tó lágbára rárá.

Montgomery ní kò sí àjọ ìjọba UK tàbí ilé aṣòfin UK tó fọwọ́ sí ìwé ẹ̀sùn náà.

"Bí ìjọba àpapọ̀ ṣe ránṣẹ́ pe aṣojú UK sí Nàìjíríà lórí ìwé ẹ̀sùn tí mo kọ, kò bójúmu, wọ́n kàn fẹ́ kó mi láyà jẹ ni"

Ẹ̀wẹ̀, àtẹ̀jáde kan tí Sunday Igboho buwọ́lu fúnra rẹ̀ júwe bí ìjọba àpapọ̀ ṣe ránṣẹ́ pe Montgomery lórí ìwé ẹ̀sùn náà bí ohun tí kò bójúmu àti pé wọ́n kàn fẹ́ kó o láyà jẹ ni.

Ó ní òun kò ní jẹ́ kí nǹkan tí ìjọba àpapọ̀ náà ń ṣe kó àárẹ̀ ọkàn bá òun lórí jíjà fún ìdásílẹ̀ Yoruba Nation.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ó sàlàyé pé ìdí tí òun fi kọ̀wé sí ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kò ṣẹ̀yìn pé àwọn ni wọ́n mú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà sìn, tí wọ́n sì fún wa ní òmìnira lọ́dún 1960.

Ó ní dída ẹkùn gúúsù àti àríwá Nàìjíríà pọ̀ lọ́dún 1914 kò ṣẹ̀yìn ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, tó sì pọn dandan lábẹ́ òfin láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àwọn ní ẹ̀tọ́ láti sọ pé àwọn fẹ́ pínyà lẹ́yìn tí a ti lo ọgọ́rùn-ún ọdún papọ̀.

Igboho fi kun pé ìbáṣepọ̀ Yorùbá àtàwọn ẹ̀yà yòókù lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà kò tẹ́ àwọn lọ́rùn mọ́ ni àwọn ṣe ń bèèrè fún ìdásílẹ̀ orílẹ̀ èdè tí yóò jẹ́ ti ìran Yorùbá nìkan.

Ó ní ohun kan pàtàkì tí àwọn fi kọ̀wé ránṣẹ́ sí UK ni pé àwọn fẹ́ kí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́rìí fáwọn níwájú àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, UN nígbàkúgbà tí ọ̀rọ̀ ìdásílẹ̀ Yoruba Nation bá dé ibẹ̀.

Ó ní òun fi da gbogbo ọmọ Yorùbá lójú pé òun kò ní jẹ́ kí àwọn nǹkan tí ìjọba Nàìjíríà ń ṣe da omi tútù sáwọn lọ́kàn lọrí ìjà fín ìdásílẹ̀ orílẹ̀ èdè Yoruba Nation tí àwọn ń jà náà.

Ó fi kun pé gbogbo ọ̀nà àláfíà tí òun bá mọ̀, láì fa wàhálà tàbí jàgídíjàgan láti fi jẹ́ kí ìdásílẹ̀ Yorùbá Nation wáyé ni àwọn máa gbà.

Àkọlé fídíò, Ikiso River: Odò yìí kìí gbẹ lásìkò ẹ̀ẹ̀rùn, kìí gbé èèyàn lọ, ó ń fa òjò, bí ọ̀dá bá wà

''Sunday Igboho kàn fẹ́ ‘trend’ ni pẹ̀lú ìwé tó kọ sí Olóòtú ìjọba UK lórí ìdásílẹ̀ Yoruba Nation''

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho/Instagram

Amofin agba, Monday Ubani, SAN ti sọ pe Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ eeyan mọ si Sunday Igboho kan n fi akoko ara rẹ ṣofo lasan an ni lori iwe to kọ sọ Olootu ijọba Ilẹ Gẹẹsi lati dasi ọrọ ọrọ idasilẹ orilẹede ẹya Yoruba.

Lopin ọsẹ to kọja ni ajijagbara ọmọ Yoruba n ni, Igboho ooṣa,kọwe si Olootu ijọba ilẹ Gẹeṣi lori ọrọ ọhun.

Amọ, amofin agba Ubani sọ fun BBC Yoruba wi pe ‘’bo ya Igboho fẹ kawọn eeyan kan mọ wi pe o n ṣiṣẹ ti wọn gbe le e lọwọ lo jẹ ko gbe iru igbesẹ yii.

Nitori o ni lati kọwe si ibi to yẹ lori iru ọrọ bayii ti o ba n pe fun idasilẹ orilẹede Yoruba ni toootọ.

Iwe ti Igboho kọ yii da bi ẹni pe eeyan n kọ lẹta ifẹ si ololufẹ rẹ ni.’’

Amofin agba Ubani ṣalaye wi pe ile igbimọ aṣofin ilẹ Gẹẹsi kom lagbara kankan lati ṣe ohun kohun lori nkan ti Igboho beere fun.

Ubani sọ pe ibeere to yẹ kawọn eeyan beere ni pe eeyan meloo ninu awọn ọmọ Yoruba lo fẹnuko wi pe ki Igboho ṣoju awọn lati kọ lẹta fun iyapa Yoruba lara Naijiria.

O ni ko ṣee ṣe ki Igboho sọ pe gbogbo ọmọ Yoruba ni oun n ṣoju lori idasilẹ orilẹede Yoruba.

Ubani sọ pe niwaju ajọ iṣọkan agbaye UN lo yẹ ki Igboho kọ iru lẹyii si.

Sunday Igboho kọ̀wé sí Olóòtú Ìjọba UK, nítorí ìdásílẹ̀ ‘Yoruba Nation’

Aworan Sunday Igboho ati Olayomi Koiki pẹlu iwe naa ni UK.

Oríṣun àwòrán, Olayomi Koiki / X

Ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyemo tawọn eeyan mọ si Igboho ooṣa, ni a gbọ pe o ti kọwe si Olootu ijọba ilẹ Gẹeṣi(United Kingdom) lati da si ọrọ idasilẹ orilẹede Yoruba nikan.

Atẹjade kan lati ọdọ Olayomi Koiki, agbenusọ Igboho, fidi igbesẹ yii mulẹ.

Loju opo X Koiki lo ti kede pe Igboho ti mu lẹta naa de ọdọ Keir Starmer ti i ṣe Olootu ijọba UK.

O ni lorukọ Ọjọgbọn Banji Akintoye, olori ẹgbẹ ajijagbara Yoruba Movement, ni Igboho mu lẹta naa lọ.

Kí ni ẹgbẹ́ tó ń jà fún Yoruba Nation ń fẹ́ lọ́dọ̀ ìjọba Gẹ̀ẹ́sì?

Aworan awọn ọmọ ẹgbẹ Yoruba Nation pẹlu iwe naa ni UK

Oríṣun àwòrán, Olayomi Koiki/ X

Àkọlé àwòrán, Aworan awọn ọmọ ẹgbẹ Yoruba Nation pẹlu iwe naa ni UK

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ẹgbẹ naa n fẹ ki ijọba Gẹẹsi da si imuṣẹ Yoruba Nation, eyi ti Igboho, Ọjọgbọn Akintoye ati awọn ọmọ ẹgbẹ yooku gbe dani.

Koda, laipẹ rara ni wọn fẹ ki Keir Starmer ati ijọba rẹ gbeja Yoruba Nation ja.

Wọn fẹ ki Olootu ijọba UK ati ijọba rẹ da si bi orilẹede kan yoo sẹ wa, ti yoo jẹ ti ẹya Yoruba nikan ṣoṣo ni Naijiria.

“Ni deede aago meji ọsan, Ọmọwe Oloye Sunday Igboho, fi iwe ẹbẹ le Olootu Ijọba UK lọwọ, lorukọ Ọjọgbon Banji Akintoye, olori ẹgbẹ Yoruba Nation; ati Olayomi Koiki, agbẹnusọ rẹ, lojule kẹwaa, opopona Downing.”

Bẹẹ ni Koiki ṣe kọ ọ si oju opo X rẹ

Ẹ o ranti pe o pẹ ti Sunday Igboho ti n lewaju ninu ero rẹ lati ri i pe Yoruba Nation waye.

Bakan naa si ni Ọjọgbọn Akintoye naa ti figba kan sọ pe ijọba Naijiria n wa ọna ti wọn yoo fi pa Igboho lẹnu mọ nipa Ilẹ Olominira Yoruba ti awọn gbiyanju rẹ.