Tinubu dásí ọ̀rọ̀ Super Eagles, Libya fẹ́ gbé Nàìjíríà lọ ilé ẹjọ́

Aworan awọn agbaọọlu Super Eagles

Oríṣun àwòrán, Super Eagles/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Aarẹ Bola Tinubu ti dasi ọrọ ikọ agbabọọlu Super Eagles Naijiria to pada sile lana lẹyin ti Libya dawọn duro si papakọ ofurufu fun bii ọjọ lai si ounjẹ ti wọn le jẹ tabi ibi ti wọn le sun si.

Nigba ti wọn pada si Naijiria lalẹ ana ọjọ Aje ni Aarẹ Tinubu gboṣuba kare lai fawọn ikọ agbabọọlu naa.

Tinubu sọ ninu atẹjade ti oludamọran aarẹ lori eto iroyin, Bayo Onanuga, fi lede loju opo X rẹ pe o ṣeni laanu pe awọn agbabọọlu orilẹede Naijiria ni iriri to buru jai ni Libya.

Tinubu ni oun fẹ ki ajọ CAF ṣe iwadii to munadoko lori iṣẹlẹ naa, ki o si fi ijiya to tọ jẹ ẹnikẹni to jẹbi tabi to ti tapa sofin ajọ CAF lori iṣẹlẹ naa.

Aarẹ Tinubu fẹ ki ileeṣẹ ijọba to n ri sọrọ ere idaraya ati eyi to n ri si ọrọ ilẹ okeere lati ṣiṣẹ lori ọrọ naa.

Aarẹ orilẹede Naijiria ko ṣai lu awọn agbabọọlu Super Eagles lọgọ ẹnu fun igboya wọn bo tilẹ jẹ pe Libya foju wọn ri maabo.

Tinubu ni ere bọọlu wa lara awọn nnkan to n mu iṣọkan wa laarin ọmọ Naijiria, aarẹ ni ṣiṣe ọmọ Naijiria baṣubaṣu nibi kibi gẹgẹ bi orilẹede Libya ti ṣe awọn Super Eagles tako nnkan ti ere bọọlu tumọ si.

Tinub wa kepe awọn tọrọ kan lati ṣe atunṣe ki iru iṣẹlẹ ma ba le ṣẹlẹ mọ lọjọ iwaju.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Libya fẹ gbe Naijiria lọ ile ẹjọ

Ajọ LFF to n ri si ọrọ ere bọọlu lorilẹede Libya ti koro oju si bi ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ṣe pada wale lai kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ ati pegede fun idije AFCON 2025 to yọ ko waye lonii ọjọ Iṣẹgun niluu Benghazi.

Ajọ LFF ni oun ṣetan lati gbe Naijiria lọ sile ẹjọ lọrọ naa.

Ninu atẹjade to fi sita, ajọ LFF sọ pe ẹgbẹ agbabọọlu Libya gba lati kopa ninu ere bọọlu to waye niluu Uyo, bo tilẹ lẹ jẹ pe Naijiria foju awọn ri maabo ṣaaju ọjọ ti ifẹsẹwọnsẹ naa waye.

Ajọ naa sọ pe awọn agbabọọlu awọn ko tori iyẹn sọ pe awọn o ni kopa ninu ere bọọlu ọhun.

Ajọ LFF ni ohun toju awọn agbabọọlu awọn ri Naijiria ju nnkan ti ikọ Super Eagles sọ pe Libya ṣe fawọn lọ.

Oriṣiiriṣii fọto to n ṣafihan bawọn agbabọọlu Super Eagles ṣe sun sori aga ni papakọ ofurufu ni wọn fi lede sori ayelujara fawọn eeyan lati ri ohun to n ṣẹlẹ.

Super Eagles bínú padà wálé lẹ́yìn tí wọ́n dúró sí pápákọ̀ òfurufú ní Libya fún wákàtí méjìlá 'láì jẹun tàbí mu omi'

Aworan Super Eagles

Oríṣun àwòrán, Super Eagles/Facebook

Ikọ agbabọọlu Super Eagles Naijiria ti pada wale lẹyin ohun ti oju wọn ni papakọ ofurufu lorilẹede Libya nibi ti wọn wa lai fi omi tabi ounjẹ kan ẹnu fun bii wakati mejila.

Balogun ẹgbẹ agbabọọlu naa, William Troost-Ekong lo fidi ọrọ yii múlẹ pe awọn ti pada si orilẹede Naijiria lalaafia.

Troost-Ekong ni fun bi ọdun mẹwaa toun ti n ṣoju Naijiria bayii pe oun ko tii ni iru iriri bayii ri.

Ninu ọrọ rẹ to fi lede lori itakun ayelujara X pẹlu awọn okele ati ọbẹ ẹgusi niwaju rẹ, Troost-Ekong sọ pe oun ti n wo ifẹsẹwọnsẹ oṣu Kokanla to kan ninu idije ati pegede fun ere bọọlu Afcon 2025.

O ni erongba awọn bayii ni lati ṣoju orilẹede Naijiria daadaa, amọ, oun ni lati fi nkan sinu lọwọ yii.

Ajọ CAF bu ẹnu ẹtẹ lu iriri Super Eagles ni Libya

Ẹwẹ, ajọ CAF to n ṣakoso ere bọọlu nilẹ Afirika ti bu ẹnu ẹtẹ lu orilẹede Libya ṣe ṣe ikọ Super Eagles lorilẹede naa.

Ajọ CAF sọ pe oun ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ ọhun eyi to mu ẹgbẹ agbabọọlu binu pada lọ ile lẹyin ti wọn ti de si Libya tan.

CAF ni oun yoo fiya jẹ ẹnikẹni to ba ṣẹ sofin ajọ naa lori iṣẹlẹ ọhun.

Ajọ CAF ni oun ṣetan lati kan si Naijiria ati Libya lori iṣẹlẹ naa.

Ẹwẹ, ajọ to n ri si ere bọọlu lorilẹede Libya ti sọ pe orilẹede naa ko mu Super Eagles ni igbekun gẹgẹ bi wọn ṣe sọ.

‘’Ó dàbí ẹni pé ẹ̀wọ̀n ni a wà,’’ Super Eagles láwọn ò ní kópa nínú eré bọ́ọ̀lù pẹ̀lú Libya mọ́

Aworan awọn agbabọọlu Super Eagles

Oríṣun àwòrán, William Troost-Ekong/X

Awọn agbabọọlu Super Eagles Najiria ti dunkoko lati ma kopa ninu ere bọọlu ati pegede fun idije Afcon 2025 to yẹ ko waye lọla ọjọ Iṣẹgun lorilẹede Libya.

Idi ni wi pe papakọ ofurufu ni ikọ agbabọọlu naa sun mọju aarọ yii lẹyin ti wọn ti de si Libya lati ọjọ Aiku.

Ilu Banghazi lorilẹede Libya lo yẹ ki baalu to gbe Super Eagles ba si lana ọjọ Aiku, amọ, ilu Al Abraq to le ni igba kilomita si ibi ti ere bọọlu naa yoo ti waye ni wọn dari baalu naa si.

Ajọ NFF to n ri si ere bọọlu ni Naijiria sọ fun BBC Sport Africa wi pe ni ṣe ni wọn fi awọn agbabọọlu Najiria ọhun silẹ ni papakọ ofurufu ti ẹni kankan ko si da si wọn.

Balogun ikọ Super Eagles, William Troost-Ekong, sọ loju opo X rẹ pe ‘’gbogbo awa agbabọọlu ti fẹnu ko wi pe a o ni kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ yii mọ.

Mo ti ni oriṣiiriṣii iriri nipa gbigba bọọlu kaakiri orilẹede Afirika, amọ, ohun ti oju mi ri ni Libya yii buru jai.’’

Iṣẹlẹ yii waye lẹyin ti Libya fẹsun kan Naijiria wi pe wọn o ṣe ikọ agbabọọlu awọn daadaa nigba ti wọn wa si Naijiria lati koju Super Eagles ninu ifẹsẹwọnsẹ ti Naijiria ti jawe olubori pẹlu ami ayo kan sodo niluu Uyo lọjọ Ẹti to kọja.

Awọn alaṣẹ ajọ to n ri si ere bọọlu ni Libya fẹsun kan ajọ NFF pe wọn dari baalu to gbe ẹgbẹ agbabọọlu Libya wa Naijiria lọ si ilu Port Harcourt dipo Uyo ti ere bọọlu naa maa ti waye.

Ṣugbọn NFF sọ pe irọ ti jina si otitọ ni gbogbo ẹsun ti Libya ka silẹ.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

‘’Ó dàbí ẹni pé ẹ̀wọ̀n ni a wà,’’

Agbẹnusọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles, Promise Efoghe ti ṣalaye wi pe ajọ to n ri si ere bọọlu ni Libya ko sọ idi ti wọn fi dari baalu to gbe ikọ Super Eagles lọ si ilu Al Abraq.

‘’Awọn eeyan ko ran wa lọwọ rara, nigba ti NFF tun gbiyanju lati ṣeto mii, ni ṣe ni wọn ti wa mọ inu papakọ ofurufu.

O dabi ẹni pe inu ẹwọn ni a wa ni,’’ Efoghe ṣalaye.

Ẹlẹsẹ ayo, Victor Boniface, sọ pe ni ṣe ni wọn fi awọn silẹ lai si ounjẹ tabi ibi tawọn le sun.

Troost-Ekong to jẹ Balogun ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ni ọgbọn ati ṣakoba fun Naijiria nibi ere bọọlu ọjọ Iṣẹgun ni gbogbo ohun ti Libya n ṣe.

Efoghe ni olu ileeṣẹ Naijiria to wa niluu Tripoli ko le ṣe nkan kan lori ohun to n ṣẹlẹ tori awuyewuye to n ṣẹlẹ lagbo oṣelu orilẹede Libya.

Troost- Ekong ni awọn ko ni wọ ọkọ lọ si ilu Benghazi nibi tawọn ti maa gba bọọlu naa tori o lewu.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 3