Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko sọ̀rọ̀ lórí ilé alájà méjì tó dàwó lágbègbè Orile-Iganmu lọ́jọ́ Ajé

Oríṣun àwòrán, Lagos State Government/X
Ijọba ipinlẹ Eko ti sọrọ lori ile alaja meji to dawo lopopona Amusu, Baale, lagbegbe Orile-Iganmu niluu Eko lọjọ Aje.
Ninu atẹjade kan ti ijọba fi lede loju opo X rẹ ni o ti sọ pe ko si ẹni kankan to ku ninu iṣẹlẹ naa.
Ijọba ni lati bii ọsẹ meji loun paṣẹ wi pe kawọn eeyan to wa ninu ile ọhun ko kuro.
Koda, ijọba ni oun tun ti ṣe amin sile naa lara fun wiwo ko to di pe o wa dawo fun ra rẹ lọjọ Aje.
Kete ti ile naa wo lulẹ ni ajọ LASEMA to n ri si iṣẹlẹ pajawiri, ileeṣẹ panapana, ajọ to n ri si ile kikọ atawọn ọlọpaa ti lọ sibẹ lati dena ipalara fun ẹnikẹni.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Kẹwàá ilé náà ṣàdédé dàwó.
Níṣe ni fídíò tó ń ṣàfihàn bí ilé náà ṣe ń dàwó gba orí ayélujára lọ́jọ́ Ajé táwọn èèyàn sì ń sá àsálà fún ẹ̀mí wọn.
Adarí ẹ̀ka tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ àwìjọ fún àjọ tó ń rí sí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Eko, Nosa Okunbor tó fìdí ìròyìn náà múlẹ̀ ní kò sí ẹ̀mí kankan tó bá ilé náà lọ.
Nínú àtẹ̀jáde kan í wọ́n fi léde, LASEMA ní ilé náà dàwó fúnra rẹ̀ ní nǹkan bíi aago mẹ́sàn-án ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún lọ́jọ́ Ajé.
Wọ́n ní àwọn èèyàn tó ń gbé ilé náà ni wọ́n ti kúrò níbẹ̀ kó tó di pé ilé dàwó.
LASEMA ní àwọn òṣìṣẹ́ àjọ àwọn náà wà ní ilé náà láti ri dájú pé ààbò wà fáwọn tó wà ní agbègbè náà.
Ìgbà àkọ́kọ́ kọ̀ nìyí tí ilé yóò máa dàwó ní ìlú Eko. Ní ọdún 2024 yìí nìkan, ilé tó ti dàwó kò níye.
Ní oṣù Karùn-ún, ilé alájà mẹ́rin kan dàwó ní agbègbè Iga Iduganran ní ẹ̀gbẹ́ ààfin Ọba Eko, tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì há sábẹ́ rẹ̀.












