Àwọn ọ̀dọ́ rí òkú àti ọ̀pọ̀ eegun èèyàn ní àgbàlá olórí agbègbè kan, wọ́n dáná sun ọ̀pọ̀ ilé, ṣọ́ọ̀bù àti àgọ́ ọlọ̀pàá

Oríṣun àwòrán, Others
Ṣe ni ohun gbogbo pakasọ nilu Agenebode nipinlẹ Edo lọsan ọjọ Aiku ana nigba ti ọpọ eeyan jade laye lori ẹsun ijinigbe ati ipaniyan eyi tawọn ọdaran kan n se lagbegbe naa.
Koda, se ni awọn ọdọ to n fẹhonu han lori iwa ọdaran yii tun dana sun agọ ọlọpaa atawọn ọkọ to wa nibẹ.
Awọn olufẹhonuhan naa lo n fi apa janu pe awọn osisẹ ọlọpaa lo n gbabọde fun awọn onisẹ ibi nilu ọhun.
Bakan naa ni awọn ọdọ tinu n bi yii salaye pe awọn gunle iwọde naa lati fi ẹhonu awọn han lori bi awọn ọdaran se n ji awọn eeyan gbe, ti wọn si tun n pa wọn ni ipakupa, bẹẹ ni wọn n yọ ẹya ara wọn ta.
Bawo ni asiri isẹlẹ naa se tu?
Awọn ọdọ naa ni awọn tọpinpin ẹrọ ayelujara afurasi ajinigbe kan pẹlu imọ ẹrọ igbalode, ti ọwọ si tẹ afurasi naa, ẹni ti awọn fa le ileesẹ ọlọpaa lọwọ.
Ẹrọ ibaraẹnisọrọ ti wọn tọpasẹ rẹ naa si ni wọn tọpinpin rẹ de ọdọ olori agbegbe kan nilu ọhun.
“Nigba ti ọwọ ti ileesẹ ọlọpaa fi mu isẹlẹ naa ko tẹ wa lọrun, idi ree ti awa ọdọ fi ya bo agọ ọlọpaa, ti a si mu afurasi naa lọ.
Afurasi yii si lo mu wa lọ sile asaaju agbegbe kan to n sisẹ fun, nibẹ lo si ti jẹwọ nipa ọpọ iwa ijinigbe ati ipaniyan ti wọn ti se.
Bakan naa ni afurasi naa tun jẹwọ pe awọn maa n yọ ẹya ara awọn ti ba pa, ti awọn si maa n ta wọn fun awọn eeyan to ba nilo ẹya ara eeyan.
Afurasi naa tun sọ fun wa pe inu koto nla kan ni awọn maa n da oku awọn eeyan ti wọn ba pa naa si.”
"Awọn ọdọ ri oku ọmọdekunrin kan to n jẹra lọwọ ninu agbala olori agbegbe to n se agbodegba fawọn afurasi apaayan naa"
Alaye afurasi yii si lo gbe awọn ọdọ de ibi ti wọn maa n sin awọn eeyan tawọn afurasi ajinigbe naa pa si, ti wọn si hu ilẹ naa.
Nibẹ si ni awọn ọdọ ti ri oku ọmọdekunrin kan to n jẹra lọwọ ninu agbala olori agbegbe to n se agbodegba fawọn apaayan naa.
Bi olori agbegbe naa se ri pe akara ti tu sepo, ni oun ati awọn mọlẹbi rẹ ba fi ẹsẹ fẹ, ti awọn ọdọ to n wa ilẹ kaakiri agbala afurasi naa si ri ọpọlọpọ egungun eeyan kaakiri.
Eyi lo mu ki awọn ọdọ yii fa ibinu yọ, ti wọn si jo ile olori agbegbe naa kanlẹ, to fi mọ ibudo ikowo ọpọ eeyan nilu naa.
Bakan naa ni wọn pa diẹ lara awọn eeyan ti wọn furasi pe o lọwọ ninu iwa ijinigbe naa, ki wọn to morile agọ ọlọpaa lati sọ ina sibẹ.
Ki ni ọlọpaa ati alaga ijọba ibilẹ sọ nipa isẹlẹ naa?
Alaga ijọba ibilẹ ila oorun Etsako ti ilu Agenebode wa labẹ rẹ, Arabinrin Benedicta aya Atoh ni ẹnu ya oun pupọ nipa isẹlẹ naa, koda, oun ko tii le sọrọ nipa isẹlẹ ọhin.
Wayi o, Igbakeji ọga agba ọlọpa ni ẹkun karun, Arungwa Udo ati kọmisana ọlọpaa nipinlẹ Edo, Nemi Edwin-Iwo ti sabẹwo si agbegbe ti isẹlẹ naa ti waye lati da alaafia pada sibẹ.
Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ṣekúpa olùdíje sípò káńsílọ̀ l'Ogun

Oríṣun àwòrán, Others
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti ni awọn ti bẹrẹ si i dọdẹ awọn eeyan kan ti wọn pe ni ọmọ ẹgbẹ okunkun, ti wọn yinbọn pa Adeleke Adeyinka, ondupo kansilọ l’Abeokuta.
Ijọba ibilẹ Guusu Abeokuta ni Oloogbe Adeleke ti gbiyanju lati jẹ kansilọ nigba aye rẹ, ni wọọdu kẹẹẹdogun.
Idibo ijọba ibilẹ ti yoo waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla ọdun 2024 yii ni Oloogbe Adeyinka ti fẹẹ dije bi awọn yooku rẹ, ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni.
Ṣugbọn lọjọ Satide, ọjọ kejila, oṣu Kẹwaa ọdun 2024, awọn eeyan kan ti wọn pe ni ọmọ ẹgbẹ okunkun, ya bo o pẹlu mọto ti ko ni nọmba ti wọn gbe wa.
Agbegbe Jide Jones, Oke Ilewo l’Abeokuta ni wọn ti ba Adeleke, a gbọ pe wọn da ibọn bo o, wọn si ri i pe o dagbere faye lẹsẹkẹsẹ ni aarọ Satide naa.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, SP Omolola Odutola, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, ṣalaye pe kọmandi ọlọpaa Ogun ti bẹrẹ iṣẹ lori rẹ.
O ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun lo yinbọn pa Adeleke Adeyinka, awọn si t bẹrẹ si i dọdẹ wọn lati f’ọwọ ofin mu wọn.
Ẹni ogoji ọdun geerege ni Oloogbe Adeleke Adeyinka.
Ṣaaju iku rẹ, gareeji ọkọ to wa ni Panseke, l’Abeokuta, la gbọ pe o ti n ṣiṣẹ gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ ọlọkọ.














