Mo fi owó Òbí mi jóná, mo fi àkókò mi ṣòfò, àfi bíi pé wọ́n yàn mi jẹ ni- Lydia akẹ́kọ̀ọ́ Benin Republic

Naijiria kede pe wọn ti fofin de ayederu iwe ẹri awọn kan to lọ kawe nilẹ okeere ni eyi to kan ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria to n kẹkọọ gboye ni Togo ati ilẹ Olominira Benin.
“ Mi kò mọ́ bi ọjọ́ ọ̀la mi á ṣe ri" ni ọrọ Lydia Aduragbemi, ọkan lara awọn ọmọ Naijriia ti ko le tẹsiwaju mọ lataari ikede lati Naijiria pe ayederu ni iwe ẹri to ba jade ni fasiti to ti n kawe ni Benin Republic.
Loṣu kẹjọ ọdun 2024 yii ni Ọjọgbọn Tahir Mamman to jẹ minista fún eto ẹkọ ni Naijiria kede pe akẹkọọ to le ni ẹgbẹrun mọkanlelogun ni wọn n gbe ayederu iwe ẹri kiri lati Togo ati Benin Republic.
Mamman kede pe Naijiria ko ni gba iwe ẹri ti wọn ba gba lati ọdun 2019 si asiko yii ati pe ile ẹkọ giga marun un ni awọn gba pe o kun oju oṣuwọn to ni Benin Republic ati mẹta ni orilẹ-ede Togo.
O ni pe awọn to ti n ṣiṣe pẹlu iwe ẹri lati awọn ile ẹkọ giga ti Naijiria ko fọwọ si wọnyii ni wọn yoo gba iṣẹ lọwọ wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kini o ṣẹlẹ ki wọn to fofin de awọn ileẹkọ giga wọnyii?
Ṣaaju ni akọroyin kan, Umar, dibọn lọ si ile ẹkọ giga Ecole Supérieure de Gestation et de Technologies (ESGT), ni Benin Republic to si kẹkọọ gboye imọ ijinlẹ jade laarin ọsẹ mẹfa.
Iroyin ayederu Iwe ẹri to sọ pe oun na N600,000 ($358: 60) lati fi gba jade lo jẹ ki Ileeṣẹ ijọba apapọ Naijiria to n mojuto eto ẹkọ gbe igbimọ tẹẹkoto kan dide lati lọ ṣe iwadii sii nipa awọn ileẹkọ giga ni Benin Republic.
Abajade iwadii wọn lo fihan pe awọn ileẹkọ giga kan ko ni aṣẹ lati ṣe awọn kọ́ọ̀sì kọọkan nigba ti awon miran ko tilẹ kunju oṣuwọn to.
Ogbẹni Godwin Odimoko tó jẹ akọwe agba ajọ Naijria to n mojuto awọn eeyan wọn nilẹ okeere, iyẹn Nigerians in Diaspora, Republic of Benin (Queme / Plateau) fidiẹ mulẹ fun BBC pe awọn ileẹkọ giga ti ijọba Naijiria gba iwe ẹri pe wọn pegede ni Benin Republic ni:-
-Universitè D’ Abomey-Calavi,
-Universitè De Parakou,
-Universitè Nationale Des Sciences, Technologist Ingenieve Et Mathematiques,
-Universitè Nationale D’ Agriculture and
-Universitè Africaine De Development Cooperatif.
Bakan naa lo sọ pe o to ida marun-un-dinlaadọrin ninu ọgọrun-un awọn ọmọ Naijriia to n kawe kaakiri ile ẹkọ giga to le ni aadọrun-un ni orilẹ-ede Olominira Benin lọwọlọwọ ti ọrọ yii kan.
Kini o ti ṣẹlẹ ṣeyin?
Eyi kii ṣe igba akọkọ ti ijọba Naijiria yoo kọminu lori ayederu iwe ẹri lati awọn ile ẹkọ kọọkan lati ilẹ okeere.
Lọdun 2019 ni Ọjọgbọn Abubakar Rasheed Adamu to jẹ akọwe agba ajọ to n mojuto fasiti ni Naijiria iyẹn Nigeria’s National Universities Commission (NUC) kilọ fawọn akẹkọọgboye lati ṣọra fun ayederu iwe ẹri lati Benin Republic.
O sọ pe ajọ NUC ti ri awọn ayederu ile ẹkọ kan lawọn orilẹ-ede kan ni Afrika ti wọn n fun awọn akẹkọọ Naijiria ni iwe ẹri PhD laari ọdun kan pere pẹlu nkan bii ẹgbẹrun mẹta naira nigba naa, NG N3,000. ($1:80).
Loṣu kẹta lọdun 2021 ni ajọ to n risi ọrọ agunbanirọ ni Naijiria ti a mó si:- National Youth Service Corps (NYSC) yọ orukọ fasiti mẹjọ kan pe ko saaye fawọn akẹkọọgboye lati ibẹ lati kopa ninu sisinru-ilu ni Naijriia nitori pe ayederu iwe ẹri ni wọn n pin nibẹ. Marun un ninu awọn ile ẹkọ giga naa wa ni Benin Republic.
Koda, loṣu kẹjọ lọdun 2021 ni ajọ NUC tun kede pe fasiti ti Applied Sciences and Management, Porto-Novo, Benin, ati ti African University for Cooperative Development (AUCD) Cotonou, Benin ko kunju oṣuwọn to ati pe awọn ọmọ Naijiriia to ba lọ kawe nibẹ ṣeeṣe lati ma kọ ẹkọ to bo ti yẹ.
Titi di asiko yii ni ileeṣe ijọba apapọ to n ri si eto ẹkọ ni Naijriia sọ pe ọpọ ọmọ Naijiria lo ṣi n kẹkọọ lawọn ile ẹkọ giga tijọba ko gba wọle ni Benin.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kini eyi tumọ si fawọn Akẹkọọ, Obi ati Fasiti ti ọ̀rọ̀ kan?
Lydia Aduragbemi to n kẹkọọ nipa imọ awọn to n mojuto ọrọ oṣiṣẹ ni ọkan lara awọn fasiti ti Naijiria fofin de sọ fun BBC pe oun kabamọ pe oun wa kawe nilẹ okeere.
O fomije ni: “O ba mi lọkan jẹ gidi, o dabi pe a yan mi jẹ ni; koda, mi o mọ bi Iya mi ṣe fẹ la asiko yii kọja pẹlu gbogbo gbese to ti jẹ, bẹẹ mi o mọ ohun ti yoo ṣẹlẹ si mi lọjọ ọla”.
Bose Nwachukwu to jẹ Obi ọkan lara awon akẹkọọ ti ọrọ naa kan sọ fun BBC pẹlu omije pe: “ni ṣe lo dabi pe òfò nla lo ṣe mi bi mo ṣe gbọ iroyin naa lori ayelujara tori mo tii na gbogbo owo ti mo ni nipamọ lati ran ọmọ mi lọ kawe nireti ọjọ ọla to dara”.
Aarẹ ẹgbẹ awọn olukọ Naijiria ti wọn fi Benin Republic ṣe ibujoko, Omowe Gabriel Kona ṣalaye pe wọn ko lodi si pe ki ijọba Naijiria fọ abawọn eto ẹkọ mọ ni Togo, Benin ati Naijiria ṣugbọn ko yẹ ki a ba awọn alaiṣẹ naa wi mọ awọn to ṣẹ.
O ni: “Bi eto ẹkọ Naijiria ṣe mọnyan lori naa ni o wa ni Benin ati Togo ati kaakiri, ati pe, eto kikẹkọgboye ọlọdun mẹta ti wọn n ṣe lọdọ wọn dabi ti ọlọdun mérin ti Naijiria ni eyi to wa ni ibamu pẹlu ilakalẹ European Credit Transfer and Accumulation System ti wọn n lo kaakiri”.
Kona tun sọ pe ijọba Olominira Benin faaye gba ki akẹkọọ kẹkọọ gboye pẹlu ede Oyinbo nibẹ.
Bakan naa ni akọwe agba NDC, Godwin tun parọwa fun awọn ti ọrọ kan lati maṣe ṣe iwọde tabi ki wọn ba ọkan jẹ ju nitori pe wọn ti n ṣiṣẹ papọ lati yanju ọrọ naa ni ibamu pẹlu ilana UNESCO ati ajọ United Nations lori eto ẹkọ ile ẹkọ giga ki ijọba Naijiria le fontẹ lu awọn fasiti to ba ti ṣe atunṣe bo ṣe yẹ.
Ẹgbẹ Coalition of stakeholders in Education (CSE) to jẹ ẹgbẹ awon Obi, Olukọ ati akẹkọọ ni Benin Republic naa tun fidiẹ mulẹ pe awọn ti n sọrọ pẹlu awọn alaṣẹ lati tun ọrọ naa ro ni eyi ti won si n reti esi lati ọdọ ijọba Naijiria.
Ileeṣẹ eto ẹkọ Naijiria sọ fun awọn ọmo Naijiria pe ki wọn maa lọ si ile ẹkọ ti ijọba ba fontẹ lu pe o pegede ti iwe ẹri wọn ko si ki n ṣe ayederu.
Imọran fun yiyan fasiti to dara lati lọ kawe nilẹ Okeere:-
-Wa eto ẹkọ to ba imọ to wu ọmọ rẹ julọ nilẹ okeere.
-Wa ile ẹkọ giga to n ṣe irufẹ kọọsi to wu ọmọ rẹ pẹlu bi wọn ṣe n huwa si awọn alejo ati ẹya miran si.
-Se iwadii boya ileẹkọ naa jẹ eyi ti ijóba fontẹ lu lati ileeṣẹ to n mojuto ọrọ ilẹ Okeere bii Nigeria Embassy tabi Nigeria Diaspora Commission nibẹ.
-Wadii boya ọmọ rẹ nilo lati kọ ede ilu ibi ti ile ẹkọ naa wa lorilẹ-ede ọhun.
-Ṣe iṣiro iye owo too nilo fun ọmọ rẹ ki o si ronu ọna ti wa a fi ṣeto iṣuna naa laisi ipalara.
-Ṣe iwadii kikun boya ọmọ rẹ le ri ẹkọ ọfẹ abi eto san owo diẹdiẹ ki o si tete bẹrẹ si ni fowo pamọ bayii.
-Wadii ọna eto ilera to kunju oṣuwọn fun ọmọ rẹ nibẹ ati eto adojutofo eto ilera to peye.
-Ri i pe o wa alabojuto kan fun ọmọ rẹ to n gbe nitosi ibẹ ti ọmọ rẹ le lọ maa ba lasiko iṣẹlẹ pajawiri.
-Tọ ọmọ rẹ sii lojuna to fi le da duro laibẹru.
-Gba iwe irinna fun ọmọ rẹ ki o si wadii boya o nilo awọn lẹta miran tabi ko san lara owo ile ẹkọ rẹ ko to kuro lọdọ rẹ.
-Ma a tẹtileko lori awọn iṣẹlẹ to n ṣẹlẹ ni orilẹ-ede ti ọmọ rẹ n lọ.
Ikadii:
Ọ̀pọ̀ akẹkọọ lo n la ohun ti Lydia n la kọja lasiko yii ti wọn ko si mọ ohun to le ṣẹlẹ lọjọ ọla, ṣugbọn ohun to ṣe pataki julọ bayii bi awọn alaṣẹ ṣe n wa ojutuu siṣoroa naa ni pe- Awọn Obi gbọdọ ṣe iwadii to gbooro ki wọn to na owo nla lati ran ọmọ wọn lọ kawe nilẹ okeere lasiko ọgbẹlẹ yii.












