"Ọkùnrin mẹ́rin sí márùn-ún ni mo ń wọ́ ara fún lójúmọ́, àwọn míràn sì máà ń bèèrè ‘ìtura’ lẹ́yìn ara wíwọ́"

Àkọlé fídíò, Damilola Apena: Ọ̀pọ̀ èèyàn ń rò pé Oníṣìná ni àwa tí à ń ṣiṣẹ́ ara wíwọ́ àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀
"Ọkùnrin mẹ́rin sí márùn-ún ni mo ń wọ́ ara fún lójúmọ́, àwọn míràn sì máà ń bèèrè ‘ìtura’ lẹ́yìn ara wíwọ́"

Yoruba ni bi ojumọ se n mọ ni aye n yi nitori ọlaju ti gba ile aye kan.

Ọpọ awọn isẹ oojọ kan si wa ni ode oni ti ko si ni aye igbaani.

Lara awọn isẹ igbalode naa ni isẹ ara wiwọ, ti awọn oloyinbo n pe ni Massage Theraphy.

Ọpọ eeyan ni isẹ ọhun ko fi bẹẹ ye, ti wọn si n beere pe ki lo le mu ki ọkunrin gbe ara silẹ, ki obinrin maa ba wọ ara tabi ki obinrin gbe ara silẹ, ti ọkunrin kan yoo maa baa wọ ara.

Eyi lo mu ki BBC Yoruba tọ ọkan lara awọn eeyan to n sisẹ ara wiwọ, Damilola Apena lọ lati mọ ohun ti isẹ naa wa fun.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Damilola salaye ni ẹkunrẹrẹ nipa isẹ ara wiwọ, anfaani rẹ ati awọn ipenija to wa nidi isẹ naa.

Damilola Apena, Onisẹ ara wiwọ

“Orisirisi wiwọ ara lo wa eyi to niii se pẹlu egungun ati rirẹ ara”

Ninu alaye rẹ pẹlu BBC Yoruba, Damilola Apena salaye pe nipa orisi isẹ iwọ ara to wa, eyi ti wọn n sisẹ le lori.

“Orisirisi iwọra lo wa, ọkan wa ti a maa fi n jẹ ki adinku ba rirẹ ara eyi ti wọn n pe ni Swedish Massage.

Bakan naa, Deep Tissue wa eyi ti wọn maa fi n wọ inu egungun lọ nigba ti ara ba n ro eeyan kan, ti wọn yoo si sisẹ lori ibi ti ara riro naa wa.”

Damilola Apena, Onisẹ ara wiwọ

“Ọpọ si lo maa n ro pe awa ti a n se isẹ ara wiwọ maa n se sina, eyi ko ri bẹẹ rara”

Bakan naa, Damilola salaye pe nipa iye onibara to maa n ni ni ojumọ kan ati bi ibasepọ wọn lẹnu isẹ naa se ri.

“Ni ojumọ kan, mo le fi ọwọ kan ọkunrin mẹrin si marun, niwọn igba ti wọn ko ba ti fi ọwọ kan mi pada, emi kii se onidọti, isẹ ti mo n se niyẹn.

Isẹ wa la n se, ọpọ si lo maa n ro pe awa ti a n se isẹ ara wiwọ maa n se sina, eyi ko ri bẹẹ rara.

Niwọn igba ti wọn ko ba ti n fi ọwọ kan mi pada, emi kii se onidọti.

Lootọ ni mo n fi ọwọ kan wọn, amọ n ko se eyi lasan, mo n wa ojutu si isoro aye wọn ni tori isẹ ti emi yan ni aayo niyẹn.”

“Awọn ọkunrin miran maa n beere daadaa pe “ka mu inu awọn dun” lẹyin isẹ ara wiwọ”

Ọpọ ibeere lo maa n gba ọkan awọn eeyan to ba n wo obinrin kan to n wọ ara ọkunrin ti kii se ọkọ rẹ tabi ọkunrin kan to n wọ ara obinrin ti ki se iyawo ile rẹ.

Lara ibeere naa si ni pe se ara irufẹ oju ara obinrin tabi nnkan ọkunrin ti wọn n wọ ara fun ko ni gbe fukẹ lasiko ti wọn ba n wọ ara fun wọn?

Niwọn igba to jẹ pe ẹlkẹran ara ni gbogbo wa, ti awọn nnkan ẹya ara yii ba gbe soke, ki ni yoo sẹlẹ laarin ẹni to n wọ ara fun ni ati ẹni ti wọn n wọ ara fun?

N jẹ ibasepọ maa n waye laarin awọn osisẹ to n wọ ara ati awọn onibara wọn bi lẹyin ara wiwọ̀?

Nigba to n dahun sawọn ibeere yii, Damilola Apena salaye lẹkunrẹrẹ lati dahun awọn ibeere naa.

“Lẹyin ti a ba pari wiwọ ara tan, lootọ ni awọn ọkunrin kan maa n beere fun “Happy Ending” (eyi to tumọ si pe ko tu awọn lara lori nnkan ọkunrin to gbe soke tabi ki wọn ni ibalopọ lati tu onibara naa ninu)

A ko le fẹ iyẹn ku ni ẹnu isẹ yii, fun apẹrẹ, ni ọsẹ yii, ọkunrin kan pe mi pe oun fẹ wọ ara oun.

O ni oun mọ pe emi kii se Happy Ending amọ o ni oun maa fun mi ni ẹgbẹrun lọna igba Naira lati fi se nnkan kekere fun, mo dẹ ni pe n ko se.

O ni oun ko se ri, ki wọn wọra fun oun tan, ki oun ma wa gba itura, oun ko se iru rẹ ri.

Mo si sọ fun pe ko lọ si ọdọ awọn to maa n fun ni itura lẹyin ti wọn ba wọra fun tan.

Awọn eeyan maa n beere fun itura yii amọ o wa ku si iwọ lọwọ lati se e tabi ko maa se e.

Ọdun keje ti mo ti n sisẹ ara wiwọ naa ree, ko si ọkankan ninu awọn onibara mi to le sọ pe oun ti se nkan pẹlu mi ri lẹyin ti mo wọ ara fun tan.

Damilola Apena, Onisẹ ara wiwọ

“Afojusun mi tẹlẹ ni lati jẹ Oluyẹwe owo wo, ti a mọ si Auditor tori rẹ ni mo se ka imọ nipa ọrọ Aje nile ẹkọ”

Nigba to n sọrọ lori afojusun rẹ nile aye, Damilola Apena ni isẹ oluyẹwe owo wo ti a mọ si Auditor lo wu oun lati se, idi si ree ti oun fi lọ kọ imọ nipa ọrọ aje ti a mọ si Economics.

“ Mo ti se awari isẹ ara wiwọ lasiko naa, mo si nifẹ isẹ naa, n ko tiẹ mọ pe wọn maa n gba owo nidi isẹ naa.

Idi ti mo fi gbajumọ isẹ naa ni pe mo ni onibara to pọ, ko si jẹ ki n raye lati sisẹ miran.

Ko rọrun rara nigba ti mo bẹrẹ isẹ ara wiwọ, ọpọ eeyan ni ko si ba mi sọrọ mọ amọ mo jẹ ki eyi jẹ iwuri fun mi lati tẹ siwaju.

Mo si maa n ranti lọpọ igba pe awọn kan wa ti wọn n duro pe ki n subu lẹnu isẹ yii amọ nigba to ya, wọn n tẹwọgba isẹ mi yii.

Koda, ati ẹbi, ara, Pasitọ ati iyawo Pasitọ ti faramọ isẹ ti mo n se.”

Nigba to n fi imọran fun awọn akẹẹgbẹ rẹ nidi isẹ iwọra, Damilola ni “ẹni to ba n sisẹ naa gbọdọ mọ nnkan to n se lai jẹ ki owo wọ ọ loju.

Ti awọn obi ba ni ki o ma sisẹ yii, se isẹ naa, se idanilẹkọ nipa rẹ, ki o si maa polowo ọja rẹ.”