Wo nnkan tí iye ìgbà tí ò ń ṣe ìgbọ̀nsẹ̀ ń sọ nípa ìlera rẹ

Àwọn onímọ̀ ní ṣíṣe àyẹ̀wò ìgbẹ́ dára láti ṣàwárí ìyàtọ̀ kankan tí o nílò láti bá dókítà rẹ̀ sọ

Oríṣun àwòrán, Emmanuel Lafont/ BBC

Àkọlé àwòrán, Àwọn onímọ̀ ní ṣíṣe àyẹ̀wò ìgbẹ́ dára láti ṣàwárí ìyàtọ̀ kankan tí o nílò láti bá dókítà rẹ̀ sọ
    • Author, Jasmin Fox-Skelly
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ṣé ẹni tó máa ń lọ ilé ìgbọ̀nsẹ̀ ní ẹ̀ẹmẹ̀ta lójúmọ́ ni ìwọ ni àbí ẹni tó jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kan láàárín ọjọ́ mẹ́ta ni ìwọ máa ń ṣe gá? Ní pàtàkì, kí ni iye ìgbà tí ò ń ṣe ìgbọ̀nsẹ̀ ń sọ nípa ìlera rẹ?

Jókòó, kí o fara balẹ̀ ka ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì nípa ìgbẹ́.

Iye ìgbà tí èèyàn máa ń ṣe ìgbọ̀nsẹ̀ yàtọ̀ síra. Gbogbo ìgbà tí a bá jẹun, àwọn ẹ̀yà àrà tó wà nínú ìfun máa ti oúnjẹ lọ sí ibi tí wọ́n ti máa fọ́ oúnjẹ sí wẹ́wẹ́. Èyí ló máa ń ṣokùnfà tí èèyàn fi máa ń mọ̀ pé òun fẹ́ yàgbẹ́. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń mú èyí mọ́ra tó fi jẹ́ pé èèyàn kìí yàgbẹ́ ju ẹ̀ẹ̀kan lọ lójúmọ́.

Martin Veysey, onímọ̀ ìṣègùn òyìnbó ní ilé ìwòsàn Canberra Hospital, Australia ní ọ̀pọ̀ èèyàn ni kìí fẹ́ yàgbẹ́.

Ṣáájú àsìkò yìí, onírúurú àwọn ìgbàgbọ́ ló wà nípa iye ìgbà tó yẹ kí èèyàn yàgbẹ́ lójúmọ́ tàbí lọ́sẹ̀ àmọ́ ìwádìí àwọn onímọ̀ bíi Ken Heaton, onímọ̀ ìṣègùn òyìnbó ní Bristol Royal Infirmary, UK ṣàfihàn pé iye ìgbà tí èèyàn le yàgbẹ́ yàtọ̀ síra.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó gbajúmọ̀ ni pé kí èèyàn yàgbẹ́ ní ẹ̀ẹ̀kan lójúmọ́, ìdá ogójì (40%) àwọn ọkùnrin àti ìdá mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33%) àwọn obìnrin nínú àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló máa ń ṣe èyí.

Àwọn mìíràn kìí yàgbẹ̀ ju ẹ̀ẹ̀kan lọ lọ́sẹ̀, àwọn mìíràn ẹ̀ẹ̀mẹta lójúmọ́. Ohun tí ìwádìí náà fẹnukò lé lórí ni pé ó dín ní ìlàjì àwọn èèyàn tó wà láyé tí wọ́n ń yàgbẹ́ bó ṣe yẹ.

Àwọn èèyàn tó bá máa ń yàgbẹ́ rírọ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹrin láàárín ọ̀sẹ̀ kan ni ó ṣeéṣe kí wọ́n tètè jáde láye láàárín ọdún márùn-ún ju àwọn tí wọ́n máa ń yàgbẹ́ bó ṣe yẹ ní ẹ̀èméje láàárín ọ̀sẹ̀ lọ.

Èyí nìkan kọ́ ni ìdásí Heaton, ó ṣe àgbékalẹ̀ ẹ̀rọ ìwọ̀n kan tó pè ní "The Bristol Stool Form Scale" tó máa ń ṣe ìrànwọ́ fáwọn dókítà láti mọ̀ nípa àwọn tí wọ́n bá ń kojú ìṣòro tí oúnjẹ wọn kìí fọ́ sí wẹ́wẹ́ bó ṣe yẹ.

Ẹni tó wà lórí àpótí ìgbọ̀nsẹ̀

Oríṣun àwòrán, Emmanuel Lafont/BBC

Ẹkùn "goldilocks/ goldiplops"

Àjọ tó ń rí sí ètò ìlera ní UK àtàwọn àjọ ìlera míì gbà wí pé yíyàgbẹ́ ní ẹ̀ẹ̀mẹta lójúmọ́ tàbí ẹ̀ẹ̀mẹta lọ́sẹ̀ jẹ́ ohun tó dára àmọ́ pé ó dára kò túmọ̀ sí ìlera pípé. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kò sọ pàtó iye ìgbà tó yé kí èèyàn yàgbẹ́ lójúmọ́ síbẹ̀ wọ́n gbà pé ìgbẹ́ le sọ bí ìlera èèyàn ṣe pé sí.

Bí àpẹẹrẹ, ìwádìí kan tí wọ́n ṣe fáwọn èèyàn 14,573 ní Amẹ́ríkà lọ́dún 2023 ṣàfihàn pé àwọn èèyàn tó máa ń yàgbẹ́ ní ẹ̀ẹmèje lọ́sẹ̀ ló pọ̀ jùlọ àti pé irú ìgbẹ́ tí kò le tí kò sì rọ̀ ló pọ̀ jùlọ.

Àwọn olùwádìí ṣàyẹ̀wò àwọn èèyàn yìí láti mọ̀ bóyá ìgbẹ́ wọn ní nǹkan ṣe pẹ̀lú bí wọ́n ṣe le pẹ́ láyé sí. Àwọn èèyàn tó bá máa ń yàgbẹ́ rírọ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹrin láàárín ọ̀sẹ̀ kan ni ó ṣeéṣe kí wọ́n tètè jáde láye láàárín ọdún márùn-ún ju àwọn tí wọ́n máa ń yàgbẹ́ bó ṣe yẹ ní ẹ̀èméje láàárín ọ̀sẹ̀ lọ.

Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn tí kìí sábà yàgbẹ́ ni ó ṣeéṣe kí wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn sọ́wọ́ àìsàn jẹjẹrẹ àbí àìsàn tó nííṣe pẹ̀lú ọkàn.

Àwòrán inú

Oríṣun àwòrán, Emmanuel Lafont/ BBC

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iye ìgbà mélòó ló yẹ kí èèyàn yàgbẹ́ jẹ́ ìbéèrè wà lọ́kàn Sean Gibbons, onímọ̀ microbiology ní ilé ẹ̀kọ́ Institute for Systems Biology tó wà ní Seattle, US. Lọ́dún 2024, Gibbons ṣaájú ìwádìí kan níbi tí wọ́n ti pín àwọn èèyàn 1,400 sọ́nà mẹ́rin látara bí wọ́n ṣe ń yàgbẹ́ sí.

Gibbons ṣàwárí rẹ̀ pé àwọn èèyàn tí wọ́n máa ń yàgbẹ́ ní ẹ̀ẹ̀kan sí ẹ̀ẹ̀mẹta lójúmọ́ ní àwọn kòkòrò àìfojúrí 'bacteria' tó dára nínú ikùn wọn ju àwọn tí kìí yàgbẹ́ déédé lọ. bákan náà lọ ṣàwárí rẹ̀ pé àwọn tí kìí yàgbẹ́ tó ẹ̀ẹ̀mẹta lọ́sẹ̀ ní àìsàn kan nínú ẹ̀jẹ̀ wọn èyí tí wọ́n máa ń rí lára àwọn àìsàn kíndìnrín àti Alzheimer.

Ó gbàgbọ́ pé ìdí táwọn èèyàn tí kìí sábà yàgbẹ́ fi máa ń ní àwọn kòkòrò tí kò da lára ni ni pé, ìgbẹ́ tó yẹ kí wọ́n yà máa wà nínú wọn fún ìgbà pípẹ́, táwọn kòkòrò àìfojúrí yóò sì máa jẹ wọ́n.

Èyí ni wọ́n ló máa ń fa àwọn nǹkan olóró sínú ẹ̀jẹ̀ tó lè ba ẹ̀yà ara bíi kíndìnrín àti ọkàn jẹ́.

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn onímọ̀ sọ pé yíyàgbẹ́ ní ẹ̀ẹ̀mẹta lọ́sẹ̀ tàbí ẹ̀ẹ̀mẹta lójúmọ́ dára, ìwádìí fi hàn pé àwọn tí wọn kò yàgbẹ́ ní iye ìgbà tó yẹ ni wọ́n ní àwọn ohun olóró nínú ẹ̀jẹ̀ wọn.

Gibbons fi kun pé bí ó tilẹ̀ ṣòro láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn tí àwọn ṣe ìwádìí wọn ṣe àìsàn lọ́jọ́ iwájú, ó ní ìwádìí ti fi hàn pé àwọn tó ń yàgbẹ́ déédé ní àlááfíà tó péye ju àwọn tí kìí yàgbẹ́ déédé.

Lára àwọn ọ̀nà tí èèyàn fi lè mọ̀ pé àwọn ẹ̀yà ara tó máa ń fọ́ oúnjẹ sí wẹ́wẹ́ ń ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ ni iye ìgbà tí óunjẹ bá fi di ohun tí èèyàn ń yà ní ìgbẹ́.

Onímọ̀ sáyẹ́ǹsì míì, Emily Leeming, onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ní King's College London, fura pé àwọn èèyàn tí ìgbẹ́ wọn máa ń pẹ́ nínú ìfun wọn kìí jẹ oúnjẹ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ pèsè, tí wọ́n sì máa ń jẹ ohun tí wọ́n bá kàn rí.

Ìwádìí yìí wà ní ìbámu pẹ̀lú nǹkan tí wọ́n mọ̀ nípa kí oúnjẹ má ma dà bó ṣe yẹ, tó sì ní nǹkan ṣe pẹ̀lú àwọn àìsàn tó lágbára tó fi mọ́ jẹjẹrẹ inú ikùn.

Jíjẹ èso àti ẹ̀fọ́ máa ń jẹ́ kí èèyàn yàgbẹ́ dáadáa

Oríṣun àwòrán, Emmanuel Lafont/ BBC

Àkọlé àwòrán, Jíjẹ èso àti ẹ̀fọ́ máa ń jẹ́ kí èèyàn yàgbẹ́ dáadáa

"Àmọ́ à ń rí àwọn ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà ara míì. Bá àpẹẹrẹ , àwọn èèyàn tó ní àìsàn Parkinson le ní àìsàn kí oúnjẹ má dà fún ogún ọdún kó tó di pé ó hàn," Leeming sọ.

Veysey ẹ̀wẹ̀, tọ́ka sí àsopọ̀ bí ẹ̀yà ara inú ikùn ṣe ń ṣiṣẹ́ sí, èyí tó le mú ewu níní polyps sínú ikùn tó sì lè di jẹjẹrẹ inú ikùn.

Kí ni ìgbẹ́ ẹ̀ rẹ ń sọ nípa à rẹ?

Dípò wíwo iye ìgbà tí èèyàn ń yàgbẹ́ lọ́sẹ̀ – èyí tó yàtọ̀ sí èèyàn kan sí ẹlòmíràn, Leeming sọ pé ohun tí èèyàn gbọdọ̀ máa wòye rẹ̀ ni ìyàtọ̀ tó bá máa ń wáyé nínú iye ìgbà tí èèyàn máa ń yàgbẹ́ tí kò ṣe é ṣàlàyé.

Bákan náà ló ní ó dára láti mọ bí èèyàn ṣe máa ń yàgbẹ́ sí láti mọ ohun tó tọ́ nípa èèyàn.

"Ó dára láti máa wo ìgbẹ́ wa nítorí ó dàbí àyẹ̀wò bí ọ̀fun èèyàn ṣe rí," Leeming sọ. Kìí ṣe iye ìgbà tí èèyàn bá lọ sí ilé ìgbọ̀nsẹ̀ nìkan, irú àwọ̀ ìgbọ̀nsẹ̀ àti bí ìgbọ̀nsẹ̀ náà ṣe rí náà ṣe pàtàkì.

Tí o bá rí àwọ̀ dúdú tàbí pupa nínú ìgbẹ́ rẹ túmọ̀ sí pé ẹ̀jẹ̀ wà nínú rẹ̀. Ó ṣeéṣe kí àlàyé wà fún èyí, ó lè túmọ̀ sí àmì àpẹẹrẹ àìsàn jẹjẹrẹ, tí èèyàn sì nílò láti rí dókítà ní kíákíá.

Ó nílò láti lọ rí dókítà rẹ̀ nígbà tí ó bá máa ń ní jẹ̀díjẹ̀dí ní gbogbo ìgbà tàbí tí ìgbẹ́ máa ń déédé gbọ̀n ọ́ tàbí tí inú bá máa ń run ọ́ ní gbogbo ìgbà.

Ní ìkẹyìn, àwọn èèyàn tí wọ́n máa ń ṣe ìgbọ̀nsẹ̀ bó ṣe yẹ máa ń jẹ èso àti ẹ̀fọ́ dáadáa, tí wọ́n sì máa ń mu omi, tí wọ́n sì máa ń kópa nínú lílọ bíbọ̀.