'Ibà Lassa tó mú mi dàbí ọ̀run àpáàdì l'áyé'
Laipẹ yii ni Ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun ni Naijiria, NCDC ti kede iku dokita kan to padanu ẹmi rẹ sọwọ aisan iba Lassa.
Dokita naa, ẹni ti wọn pe ni ẹni ọdun mọkanlelọgbọn lo wa lati ipinlẹ Ondo, to si jade laye ni igba to pada si orilẹede Naijiria lati ilẹ UK.
Ọga agba fun ajọ NCDC, Dokita Jide Idris, ṣalaye pe awọn ami to jẹyọ lara oloogbe naa nigba to wa ni ile iwosan aladani lo jẹ ki wọn lọ se ayẹwo.
Dokita naa pada jade laye lọjọ kinni, oṣu Kẹta saaju ki ayẹwo ilera ti wọn se fun to jade sita ni ọjọ kẹrin, oṣu Kẹta ọdun 2025.
Amọ kii ṣe dokita to di oloogbe nikan ni aisan yii mu tabi gba ẹmi rẹ nipinlẹ Ondo.
Orilẹede Naijiria se akọsilẹ awọn to le ni ẹgbẹrun meji to ṣeeṣe ki wọn ni aisan Lassa ṣugbọn 535 ti ni i lati igba ti ọdun 2025 ti bẹrẹ.
Eeyan mejidinlọgọrun si jade ni awọn ipinlẹ mẹrinla—Ondo, Bauchi, Edo, Taraba,Ebonyi ati awọn mii.
Ọkan lara iru awọn eeyan bẹẹ, amọ ti ori pada ko yọ ni Ọgbẹni Michael Olonite.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC, Ọgbẹni Michael Olonite, ṣalaye pe bii igba ti oun wa ni ọrun apaadi ni iriri ti oun ni lọwọ aisan iba ọrẹrẹ, ti wọn n pe ni Lassa Fever.
O ni niṣe ni oun daku, oun ko ri oorun sun, bẹẹ ni ko le jẹun.
"A le pe iba Lassa ni ọrun apaadi laye."
Lati bi ọdun meji ti aisan yii ti n tan kaakiri ni Naijiria, o ti pa to eeyan to le ni ẹgbẹta, botilẹ jẹ pe o ti wa fun igba pipẹ.
Lọdun 2024 nikan, o le ni ẹẹdẹgbẹta eeyan to ku nitori aisan naa.
Ọkan lara awọn onimọ sayẹnsi to n ṣewadii nipa aisan naa, Ọjọgbọn Sylvanus Okogbenin, sọ pe aisan naa ti tan ju bi iroyin ṣe n gbe e lọ.
"Idi ni pe, o ṣoro lati mọ koko iye eeyan to n mu ni iwọ oorun Africa.
Bakan naa ni ẹni to jẹ minisita fun eto ilera ni Naijiria, Ọjọgbọn Ali Pate sọ pe ijọba n ṣa gbogbo agbara rẹ lati pana aisan naa ni Naijiria.
Pate sọ pe ijọba n ṣe eyi nipa pipese awọn ohun elo ati irinṣẹ to yẹ fun awọn oṣiṣẹ eleto aabo.
Kí ló ń fa Iba Lassa?
Iba Lassa jẹ arun kan to maa n waye lati ara kokoro aifojuri ti a mọ si Virus.
Kokoro yii maa n de ara eeyan lati ara ounjẹ tabi nnkan eelo ti ekute to ni kokoro lara naa ba tọ si, tabi to ṣe igbọnsẹ si .
Ajọ eleto ilera agbaye, World Health Organisation (WHO), sọ ọ di mimọ pe iba Lassa pọ ni apa Iwọ Oorun Africa, paapaa ni Naijiria, Liberia, Mali, Togo, Guinea, Ghana, Sierra Leone ati Benin.
Bakan naa, iba Lassa yii tun maa n tàn lati ara ẹnikan si ikeji, nibi ti ko ba ti si idaboobo ati itọju to peye.
Gẹgẹ bi NCDC ṣe wi, arun Lassa n lagbara si i , pẹlu bo ṣe jẹ pe onka awọn to n kọlu n pọ si i.
Nipa iru awọn eeyan ti iba yii saaba maa n kọlu, ajọ naa sọ pe awọn eeyan ti ọjọ ori wọn wa laaarin ọdun mọkanlelọgbọn (31) si ogoji ọdun (40), takọ-tabo ni wọn ni o si le mu.
Ọna lati dèna Lassa Fever
Aisan iba ọrẹrẹ jẹ aisan ti ko ni ẹrọ, amọ ti o ni itọju ti ẹni to ba ni aisan naa ba tete lọ si ile iwosan lati fi ara rẹ han.
Ọna ti a le gba dina aisan ti o wa lati ara ẹran igbẹ papa eku inu ile:
Ẹ sọra fun jijẹ eku tabi ẹran igbẹ.
Ẹ ma se sa garri sita gbangba.
Ẹ pa awọn eku to ba wa ni inu ile ati agbegbe yin.
Ẹ pa oko tabi koriko ti o ba wa ni agbeegbe, ki ayika naa le wa ni mimo ni gbogbo igba.
Awọn ohun elo ounjẹ gbọdọ wa ni inu ike ti ẹkutele ko lee de bẹ.
Ẹ sọra lati farakan ẹni ti o ma ni aisan iba ti kosi tete lọ.
Awon dokita tabi osisẹ ile iwosan gbọdọ sọra gidigidi, ki wọn si lo ibọwo tabi iboju ti wọn ba n toju ẹni to n se aisan.



