Lassa Fiver gba ẹ̀mí dókítà kan nípìnlẹ́ Ondo

Oríṣun àwòrán, Others
Ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun ni Naijiria, NCDC ti kede iku dokita kan to padanu ẹmi rẹ sọwọ aisan iba Lassa.
Dokita naa, ẹni ti wọn pe ni ẹni ọdun mọkanlelọgbọn lo wa lati ipinlẹ Ondo, to si jade laye ni igba to pada si orilẹede Naijiria lati ilẹ UK.
Ọga agba fun ajọ NCDC, Dokita Jide Idris, ṣalaye pe awọn ami to jẹyọ lara oloogbe naa nigba to wa ni ile iwosan aladani lo jẹ ki wọn lọ se ayẹwo.
Dokita naa pada jade laye lọjọ kinni, oṣu Kẹta saaju ki ayẹwo ilera ti wọn se fun to jade sita ni ọjọ kẹrin, oṣu Kẹta ọdun 2025.
Bi iṣẹlẹ naa se waye ni ọpọ iwadii ti bẹrẹ lori ati dena aisan yii lawujọ ni orilẹede Naijiria ati ni ilẹ UK.
Bakan ni wọn ti n se ayẹwo fun awọn mọlẹbi, awọn oṣiṣẹ eleto ilera, arin irinajo to ṣeese ki ṣalabapade oloogbe ko to jade laye.
Orilẹede Naijiria se akọsilẹ awọn to le ni ẹgbẹrun meji to ṣeeṣe ki wọn ni aisan Lassa ṣugbọn fidi 535 mulẹ ni ọdun 2025, ti eeyan mejidinlọgọrun si jade ni awọn ipinlẹ mẹrinla—Ondo, Bauchi, Edo, Taraba,Ebonyi ati awọn mii.
Saaju ko to se aisan yii, dokita to di oloogbe ṣe abẹwo si ọdọ ọrẹbinrin rẹ nipinlẹ Edo, to ba ọpọ mọlẹbi ati ọrẹ se ere.
Eyi lo ti n ba ọpọ lẹru pe o ṣeeṣe ki awọn eeyan naa ti lugbadi aisan Lassa.
Ọna lati dèna Lassa Fever
Aisan iba ọrẹrẹ jẹ aisan ti ko ni ẹrọ, amọ ti o ni itọju ti ẹni to ba ni aisan naa ba tete lọ si ile iwosan lati fi ara rẹ han.
Ọna ti a le gba dina aisan ti o wa lati ara ẹran igbẹ papa eku inu ile:
- Ẹ sọra fun jijẹ eku tabi ẹran igbẹ.
- Ẹ ma se sa garri sita gbangba.
- Ẹ pa awọn eku to ba wa ni inu ile ati agbegbe yin.
- Ẹ pa oko tabi koriko ti o ba wa ni agbeegbe, ki ayika naa le wa ni mimo ni gbogbo igba.
- Awọn ohun elo ounjẹ gbọdọ wa ni inu ike ti ẹkutele ko lee de bẹ.
- Ẹ sọra lati farakan ẹni ti o ma ni aisan iba ti kosi tete lọ.
- Awon dokita tabi osisẹ ile iwosan gbọdọ sọra gidigidi, ki wọn si lo ibọwo tabi iboju ti wọn ba n toju ẹni to n se aisan.















