Obìnrin kan déèrò ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tó sọ fún Jesu pé kó gé irun orí rẹ̀ lórí Tiktok

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọmọ orilẹede Indonesia kan, to tun jẹ gbajumọ ori Tiktok, ti ri ẹwọn ọdun mẹta he lẹyin to ya aworan Jesu sori foonu rẹ, to si sọ pe Jesu gbọdọ ge iru ori rẹ.
442,000 eeyan lo n tẹle Ratu Thalisa, to jẹ Musulumi ati ọkunrin to pa ara rẹ da di obinrin lori Tiktok.
Asiko to n ṣeto kan loju opo Tiktok rẹ ọhun lo fun ẹnikan to ni ko ge irun rẹ ko le jọ ọkunrin lesi.

Oríṣun àwòrán, Anugrah Rija Nasution/Tribun-Medan.com
Ile ẹjọ kan ni Medan, to wa ni Sumatra sọ pe Thalisa jẹbi ẹsun pinpin ọrọ ikorira lori ayelujara, o si ṣe idajọ ẹwọn ọdun meji ati oṣu mẹwaa fun.
Ile ẹjọ ọhun sọ pe ọrọ to sọ le da wahala silẹ laarin ilu, bẹẹ ni ọrọ naa tun le da irẹpọ ru laarin awọn ẹsin.
Lẹyin na ni wọn fi ẹsun sisọ ọrọ odi si ẹsin kan an.
Igbẹjọ naa lo waye lẹyin ti oniruru ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi kọwe ẹsun ọrọ odi mọ afurasi ọhun.
Wayi o, awọn ajafẹtọ ọmọniyan, to fi mọ ajọ Amnesty International, ti bu ẹnu atẹ lu idajọ naa, eyii ti wọn ni o lodi si ẹtọ rẹ lati sọrọ bo ṣe wu u.
Adari ajọ Amnesty ni Indonesia, Usman Hamid, ni "Awọn alaṣẹ ni Indonesia ko gbọdọ lo ofin Electronic Information and Transactions (EIT) wọn lati fi iya jẹ awọn eeyan fun ohun ti wọn n sọ lori ayelujara."
Hamid sọ pe ijọba gbọdọ yi idajọ to ṣe fun obinrin naa pada ni kankan, ko si fun ni ominira rẹ gẹgẹ bo ṣe tọ si i.
Ọdun 2008 ni ijọba Indonesia ṣagbekalẹ ofin EIT, ti wọn si ṣatunṣe rẹ lọdun 2016 lati gbogun ti iwa ibanilorukójẹ lori ayelujara.
Ọpọ araalu lo bu ẹnu atẹ lu ofin naa lọdun lọhun, ti pupọ ninu awọn ẹgbẹ ajafẹtọ ọmọniyan si sọ pe yoo tẹ ẹtọ araalu lati sọrọ loju mọlẹ.
Wayi o, atẹjade lati ajọ Amnesty sọ pe apapọ eeyan 560 ni wọn ti fẹsun kan labẹ ofin naa laarin ọdun 2019 si 2024, ti awọn 421 si jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn ni Indonesia.















