Bí o ṣe lè dá ayédèrú kọ́ndọ́mù mọ̀ lórí igbá

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nnkan bii ọsẹ meji sẹyin ni ajọ to n bojuto ounjẹ ati oogun lilo ni Naijiia, NAFDAC, ke gbajare sita pe ọpọ ayederu oogun lo ti wa ni igboro.
Lara awọn ayederu ohun ti wọn mẹnuba ni ayederu rọba idaabobo ati eyii ti ọjọ ti lọ lori ré to gba igboro kan.
Ninu fidio kan to gba ori ayelujara, ajọ naa sọ pe ayederu ni gbogbo rọba idaabobo "Kiss" to wa ninu ọja.
Atẹjade ti wọn fi lede sọ pe "Nigba ti a bọ si igboro lọjọ Iṣẹgun, awọn oṣisẹ wa ri awọn kọndọmu ti ajọ USAID fi ranṣẹ ti ọjọ ti lọ lori rẹ ninu ọja, eyii ti awọn kan n ta pẹlu orukọ 'Kiss Condom' lara rẹ."
Lẹyin fidio naa ni ọpọ eeyan bẹrẹ si n mẹnuba bi ọpọ ayederu kọndọmu ṣe gba igboro kan.
Wayi o, bawo ni o ṣe le da ayederu kọndọmu mọ tabi eyii ti ọjọ ti lọ lori rẹ? Alaye ree.
Bi o ṣe le mọ pali kọndọmu ti kii ṣe ojulowo
- Aṣikọ orukọ ileesṣẹ tabi eyii ti ko han daadaa – Wo pali kọndọmu rẹ daadaa lati ri pe ko si aṣiṣe kankan lara orukọ rẹ ati pe orukọ naa ko tii bẹrẹ si n parẹ
- Oniruru awọ lara pali – O le da ayederu kọndọmu mọ nigba ti awọn awọ ara paali naa ko ba ba ara wọn mu. Awọ kan le han daadaa ki omiran ti maa bo
- Paali to ti ja – Ti paali kọndọmu rẹ ba ti ja, to ba ti ṣi tabi eyii ti wọn ko lẹ daadaa, fura si irufẹ kọndọmu bẹẹ
- Alaye ti ko ba ara wọn – Wo ara pali kọndọmu rẹ daadaa lati fidi rẹ mulẹ pe awọn akọle ara rẹ ba ara wọn mu. Fun apẹrẹ, lara awọn akọle to yé ko wa lara rẹ ni ileeṣẹ to ṣe kọndọmu naa, ọjọ ti wọn ṣe e ati ọjọ ti ọjọ yoo lọ lori rẹ
Bi o ṣe le mọ ayederu kọndọmu lara kọndọmu naa funra rẹ
- Bi ara kọndọmu naa funra rẹ ṣe ri.
- Ayederu kọndọmu le nipọn ju bo ṣe yẹ lọ, bẹẹ naa ni ayederu kọndọmu le ma nipọn rara. Nigba mii, ororo ara irufẹ kọndọmu bẹẹ le pọ ju bo ṣe yẹ lọ.
- Nigba mii ẹwẹ, ayederu kọndọmu le ni iho lara, o si le ni oorun ti ko dara.
Ri daju pe o n ra rọba idaabo bo rẹ lawọn ile itaja to gbontẹ ijọba ki o ma ba ra ayederu kọndọmu.
Amọ ṣa, ti o ba ri pe o ti ṣeṣi ra kọndọmu ti kii ṣe ojulowo tabi eyii ti ọjọ ti lọ lori rẹ, ri daju pe o ko lo irufẹ rọba bẹẹ.
Ni ṣe ni ki o sọ irufẹ kọndọmu bẹẹ nu, ki o si fi ohun ti oju rẹ to lọ ileeṣẹ to n ta a tabi awọn alaṣẹ leti.
Ewu pupọ lo wa ninu lilo ayederu kọndọmu; lara ewu naa ni kiko arun ibalopọ tabi ikuna lati dena oyun.















