Bí ilé ẹjọ́ ṣe kọ́kọ́ yọ mi nípò Eleruwa, jẹ́ kí n gbóòrùn ara mi - Eleruwa
Laipẹ yii ni gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, gbe ọpa aṣẹ fun Oba Samuel Adebayo Adegbola, gẹgẹ bi Eleruwa tuntun fun ilu Eruwa.
Igbesẹ naa waye lẹyin ọdun bii mẹfa ti ile ẹjọ yọ Ọba Adegbola (Ajọbọ Olurin Kini) nipo naa, pe kii ṣe oun lo tọ si.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba lẹyin ipadabọsipo rẹ, Oba Adegbola sọ pe awọn mejidinlogun ni awọn dije dupo ọba nigba akọkọ, to si jẹ pe oun nikan ni awọn afọbajẹ dibi fun un.
O ni lẹyin naa ni wọn fi orukọ oun ranṣẹ si ijọba ipinlẹ Oyo, labẹ idari gomina tẹlẹ, oloogbe Abiola Ajimobi, ti ijọba naa si fi ọwọ si iyansipo oun.
Ko pẹ lẹyin iyansipo rẹ ni awọn alatako rẹ kan gbe ọrọ lọ si iwaju ile-ẹjọ pe ko yọ ọ nipo.
Kabiesi sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo pe nitori pe oun jẹ ọmọ obinrin ni wọn ṣe tako oun.
"Lati idile iya a mi ni mo ti kọkọ jẹ ọba lọdun 1998, idi si ree ti awọn eeyan kan fi tako mi pe, ọmọ obinrin ko lẹtọọ lati jẹ ọba."
"Gbogbo nnkan to yẹ ki n ṣe tabi jẹ ti eeyan fi n jẹ ọba ni mo sẹ."

Ọba Adegbola ṣalaye pe idajọ ile-ẹjọ to yọ oun kuro nipo jẹ ki oun gboorun ara oun, lati mọ iru eeyan ti oun jẹ ati bi oun ṣe n ṣe daadaa si nipo ọba.
"Awọn eeyan bẹrẹ si ni ka awọn nnkan rere ti mo ṣe fun ọdun mọkanlelogun ti mo kọkọ fi jọba. Eyi jẹ ki n mọ, paapaa lati ọdun 2029 ti wọn yọ mi nipo, pe mo n ṣe daadaa.
O ni fun ọdun mẹfa ti ile-ẹjọ fi yọ oun kuro nipo ọba, aarin ilu Eruwa naa ni oun n gbe, ti oun si tun n ṣiṣẹ fun idagbasoke ilu naa.
O tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe pupọ ninu awọn ti awọn jọ dije dupo ọba, lo ti n wa ki oun nile bayii ti ijọba da oun pada sipo.
Bawo ni iyọnipo Oba Adebayo Samuel Adegbola ṣe waye
Oba Adegbola ti kọkọ dari ilu Eruwa fun ọdun mọkanlelogun, ki ile ẹjọ to ga julọ too yọ ọ nipo naa lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla ọdun 2019.
Eyi lo mu ori àpèèrè ọba ilu Eruwa ṣofo fun ọdun mẹfa gbako lẹyin ti wọn yọ Ọba Samuel Adebayo Adegbola kuro nipo.
Ki lo de ti ijọba fi da a pada sori itẹ lẹyin ọdun mẹfa?

Gẹgẹ bi Kọmiṣanna eto iroyin ipinlẹ Oyo , Dotun Oyelade ṣe ṣalaye, o ni iwe to wa lati ọdọ Kọmiṣanna ọrọ oye jijé , Ọnarebu Ademola Ojo, fi han pe ori itẹ Eleruwa ti ṣofo latigba ti ẹjọ ti wa ni kootu.
Paapaa julo nigba ti wọn ti da ẹjọ ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Oyo da lori rẹ nu lọjọ kejilelogun, oṣu Kẹwaa ọdun 2024.
" Yoo wu mi lati ran gbogbo wa leti, pe idile ọmọ oye to n jẹ Laribikusi ko ri eeyan kankan fa kalẹ fun ori itẹ naa laaarin asiko ti ofin la kalẹ fun wọn lati ṣe bẹẹ.
''Abala kẹẹẹdogun, ẹka kin-in-ni ofin kejidinlọgbọn ipinlẹ Oyo lo ṣalaye eyi (Section 15(1) of the Chiefs Law Cap 28 of Oyo State."
"Fun idi eyi, lẹyin agbeyewo to yẹ, gomina ninu ọgbọn inu rẹ, fi aaye silẹ fun idile Akalako lati fa ọmọ oye kalẹ"
Bẹẹ ni Ọnarebu Ademola Ojo, Kọmiṣanna ọrọ oye jije nipinlẹ Oyo, ṣalaye.
O ni lẹyin ayẹwo finni-finni, awọn afọbaje Eruwa fẹnuko, wọn si fa Ọmọọba Adebayo Adegbola kalẹ gẹgẹ bii Eleruwa tuntun.

