Ohun mẹ́sàn-án nípa Lesotho, orílẹ̀èdè tí 'ẹnìkan kò gbúròó rẹ̀ rí'

Oríṣun àwòrán, AFP
Orilẹede kekere to wa ni Guusu ilẹ Africa ni Lesotho. O kun fun awọn oke, orilẹede South Africa lo si yi i ka porogodo.
Aarẹ ilẹ America, Donald Trump, lo sọ nipa orilẹede Lesotho to jẹ ọkan lara ilẹ Africa, pe ẹnikẹni ko gburoo ilu naa ri.
Bii pe ilu Lesotho ko si labẹ ọrun lo jọ pẹlu ọrọ Trump.
Wọ̀nyi ni ohun mẹ́sàn-àn tó yẹ láti mọ̀ nípa Lesotho
- Ìlú orí òkè ni
Aaye to ga ni Lesotho wa ninu aato ilu, ori oke tente lo wa.
Lati de awọn abule to wa ninu rẹ, eeyan ni lati gun ẹṣin, fi ẹsẹ rin tabi wọ ọkọ ofurufu ni.
Giga yii ni wọn ṣe n pe ibẹ ni "Kingdom in the Sky", iyẹn ilu to wa loju ọrun.
Lesotho nikan ni ilu naa to ga ni iwọn 1,000m (3,281ft). Gẹgẹ bi iwe itan akọsilẹ Encyclopaedia Britannica ṣe wi, aaye to lọ silẹ ju ni Lesotho ni 1,400m.
- South Africa ló yí i ká pátápátá
Orilẹede South Africa lo yi Lesotho ka patapata, ohun kan to pin wọn niya naa ko ju awọn oke ẹrimọ ti Lesotho ni lọ.
Lesotho ko ni ilẹ pupọ lati fi dako, eyi maa n jẹ ki ounjẹ wọn nibẹ, ọpọ wọn lo si jẹ pe, iṣẹ oṣu ti wọn n ṣe ni South Africa ni wọn fi n gbera.
Fun ọpọ ọdun lo ti di dandan fun ọpọ eeyan ni Lesotho lati lọọ ṣiṣẹ ni South Africa, ki wọn too le gbọ bukaata ara wọn.
Awọn eeyan Lesotho ti wọn to miliọnu meji niye, fi aṣa ati ede jọ South Africa.
Ede wọn ti a mọ si Sesotho, jẹ ọkan lara awọn ede mọkanla ti wọn n sọ ni South Africa.
Koda, awọn to n sọ ede naa pọ gan-an ni South Africa ju ni Lesotho funra rẹ lọ.
- Ohun àmuṣọrọ́ to pọ́ jù ni Lesotho ni Goolu funfun ('white gold')
Ko si nnkan alumọọni to bẹẹ ni Lesotho, eyi ri bẹẹ nitori oju ọjọ wọn ti ko daa latari oke, ti ko si si aaye fun iṣẹ ọgbin lati ṣe daadaa.
Ohun amuṣọrọ ti wọn ni ju naa ni omi, eyi ti wọn maa n pe ni wura funfun lọdọ wọn. (White Gold).
South Africa naa si ni wọn n ta omi ọhun si, wọn si tun maa n ta okuta Diamond naa .
- Lesotho jẹ́ ibùdó ẹ̀ka eré ìdárayá kan
Nitori oke to yi Lesotho po, aaye wa fun ere idaraya ti wọn n pe ni 'skiing and snowboarding.'
Ibi to ba dagun ni wọn ti n ṣe awọn ere yii, eyi si wa fun awọn oke ni Lesotho, lo fi jẹ orilẹede naa ni wọn gbe ade fun ninu ere idaraya meji yii.

Oríṣun àwòrán, AFP
Basotho ni wọn n pe awọn ọmọ Lesotho

Oríṣun àwòrán, AFP
Orukọ ti a mọ awọn eeyan to ba wa lati Lesotho si ni Basotho.
Lara awọn ohun ti wọn si mọ wọn fun ni lilo aṣọ to nipọn, dide fila apẹ, eyi ti wọn n pe no mokorotlo.
Fila bii apẹ ti wọn n de yii jẹ ami ti wọn fi n da awọn eeyan Lesotho mọ, o si wa laarin asia orilẹede wọn.
Owu to nipọn ni wọn fi n ṣe aṣọ wọn, yoo si ni ọlọkan o jọkan awọ to n sọ nipa itan Lesotho lara.
Awọn Basotho maa n wọ aṣọ wọn bii ẹni to lo iborun yipo ara bi wọn ba n lọ ode pataki, wọn si maa n fi ṣe ẹbun fun eeyan pẹlu.
- Ọkan lára àwọn orílẹ̀èdè tí àrùn kò-gbóògùn ti pọ̀ jù lágbàáyé ni Lesotho.
Lesotho jẹ ilu kan ti arun ko gboogun ti a mọ si HIV ti gbalẹ ju lagbaaye, eeyan kan ninu eeyan marun-un ti wọn jẹ agbalagba ni wọn n gbe pẹlu arun naa.
Bakan naa ni wọn tun ni awọn arun mi-in naa to jẹ aifojuri ju awọn orilẹede agbaye mi-in lọ. Koda, ẹyin ni awọn Namibia, Botswana ati Eswatini n tọ wọn.
Ijọba America ti ya owo to to $1bn (biliọnu kan dọla) sọtọ fun wọn lati fi ṣẹgun HIV lati 2006.
Wọn n ba wọn ri si idena ati itọju rẹ, gẹgẹ bi ijọba America ṣe sọ.
- Ọmọọba Harry nifẹẹ si riran Lesotho lọwọ
Gẹgẹ bo ṣe ri ni UK, ofin jijẹ ọba ti wọn n lo ni UK naa ni wọn n lo ni Lesotho.
Eyi ni pe bi ẹbi kan ba tiẹ wa to jẹ awọn ni wọn n jẹ ọba ilu, sibẹ, olootu kan ti wọn ba dibo yan lo n dari ilu.
Ọmọọba Lesotho ti a mọ si Seeiso, to jẹ aburo fun ọba Letsie kẹta to wa lori itẹ, jẹ ọrẹ timọtimọ pẹlu Arẹmọ ilẹ Gẹẹsi, Prince Harry.
Awọn mejeeji ti gbe ajọ alaanu kan kalẹ ni Lesotho, eyi ti wọn pe ni 'Sentebale.' Iitumọ rẹ ni ma gbagbe mi).
Ajọ alaanu yii n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ileewosan alabọọde lẹsẹkuku, wọn n ran awọn to ba ni kokoro HIV lọwọ.
Nigba ti Ọmọọba Harry wa lẹni ọdun mọkandinlogun lo kọkọ ṣabẹwo si Lesotho, o si ti lọ sibẹ lọpọ igba lẹyin igba iyẹn.
- Lesotho n fi aṣọ 'jinnsi' ranṣẹ si US
Bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan Iwọ-Oorun America ni aye mọ fun wiwọ aṣọ lile ti a mọ si jinnsi (Jeans ) ju, ọpọ rẹ lo jẹ pe Lesotho lo ti wa.
Awọn ileeṣẹ to n ṣe aṣọ yii ni Lesotho ti ṣe ọpọ rẹ fun awọn alaṣọ nla nla l'America.
Awọn bii Levi ati Wrangler. Eyi ni wọn fi n pe Lesotho ni "Denim capital of Africa".
Bakan naa ni wọn jẹ ọkan lara awọn ontaja nla to n ta a si ilẹ America.
Awọn ajoji lati China ati Taiwan ni wọn ni pupọ ninu awọn ileeṣẹ aṣọ to w ani Lesotho.
- Lesotho ni àwọn èèyàn ti ń pa ara wọn jù
Ilu ti akọsilẹ wa fun pe awọn eeyan n pa ara wọn ju nibẹ ni Lesotho.
Ninu eeyan 100,000, ida 87.5 lo n pa ara wọn lọdun, gẹgẹ bi ajọ ilera agbaye, UN World Health Organization ṣe sọ.
Guyana ni orilẹede to pawọle Lesotho, ida ogoji ni awọn to n pa ara wọn nibẹ.
Ko si id ikan fun onka rabandẹ awọn Lesotho to n pa ara wọn yii, bi ko ṣe pe awọn awoye sọ pe aṣilo oogun, imukumu ọti, ai si iṣẹ fun wọn to lati ṣe ati ai si ilaniloye nipa ilera ọpọlọ lo n mu wọn gba ẹmi lẹnu ara wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images












