Afurasí yìnbọn pa alákòso WhatsApp nítorí tó yọ ọ́ lórí ìkànnì náà

Àwòrán WhatsApp

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní orílẹ̀èdè Pakistan ti fi ṣìkún òfin mú ọkùnrin kan, fún ẹ̀sùn wí pé ó yìnbọn pa adarí ìkànnì 'Admin WhatsApp Group' kan tí wọ́n jọ wà, nítorí pé ẹni náà yọ ọ́ lórí ìkànnì náà.

Ní ìrọ̀lẹ́ Ọjọ́bọ̀ ni wọ́n ní ìpànìyàn náà wáyé ní agbègbè Regi, Peshawar tó jẹ́ oríkò Khyber Pakhtunkhwa tó pa ààlà pẹ̀lú orílẹ̀ èdè Afghanistan.

Gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ṣe sọ, afurasí náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ashfaq Khan, ni wọ́n ti fẹ̀sùn ṣíṣekúpa Mushtaq Ahmed, kàn.

Iléèṣẹ́ Ìròyìn Times of India jábọ̀ pé, Ashfaq àti Mushtaq ní èdè àìyedè lórí WhatsApp Group kan tí àwọn méjéèjì jọ wà, èyí tó mú kí Mushtaq yọ Ashfaq lórí ìkànnì náà.

Ìgbésẹ̀ Mushtaq yìí bí Ashfaq nínú àmọ́ tí àwọn méjéèjì jọ pinnu láti pàdé níbìkan láti yanjú aáwọ̀ tó wà láàrin wọn.

Àmọ́ níṣe ni Ashfaq fa ìbọn yọ, tó sì ṣíná ìbọn fún Mushtaq nígbà tí wọ́n dé ibi tí wọ́n ti fẹ́ pàdé láti parí aáwọ̀ náà èyí tó mú ẹ̀mí Mushtaq lọ lójú ẹsẹ̀.

Àbúrò olóògbé, Humayun Khan sọ fún àwọn akọ̀ròyìn pé, òun wà níbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé ṣùgbọ́n òun kò lè sọ nǹkan tó fa ìfaǹfà láàrin wọn.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní Humayun Khan ló wá fi ẹjọ́ afurasí náà sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá lẹ́yìn tó sá kúrò níbi ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà.