Agbébọn yìnbọn mọ́ bààlúù UN, èèyàn mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n kú

Aworan ọkọ agberapa UN

Oríṣun àwòrán, UNMISS

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Eeyan mẹtadinlọgbọn lo ti di oloogbe bayii lorilẹede South Sudan.

Lasiko ti baaluu ajọ Iṣọkan agbaye (UN) n gbiyanju lati ko awọn ọmọ ogun wọn kuro nibudo ti wọn wa lọ si Upper Nile ni wọn pade iku.

Iṣẹlẹ yii waye lọjọ Ẹti, ọjọ keje, oṣu Kẹta ọdun 2025.

Ajọ UN funra rẹ lo fidi eyi mulẹ ninu atẹjade wọn.

Atẹjade naa ṣalaye pe awọn agbebọn yinbọn mọ ọkọ baaluu agberapa (helicopter) to jẹ ti UN, awọn ọmọ ogun to wa ninu ọkọ naa si ṣegbe pẹlu ọga wọn agba toun naa jẹ ọmọ orilẹede South Sudan.

Gẹgẹ bi UN ṣe wi, wọn ni ikọlu yii le pada di ogun.

Bakan naa ni Aarẹ South Sudan, Salva Kiir, sọ pe ọkọ agberapa keji to gbiyanju lati gbera lẹyin ikọlu naa, ja lulẹ, gbogbo eeyan to wa ninu rẹ si ku pata.

Minisita eto iroyin South Sudan to ba ẹka iroyin Reuters sọrọ, ṣalaye pe eeyan mẹtadinlọgbọn ti wọn jẹ ọmọ orilẹede naa lo jade laye.

Tẹ o ba gbagbe, ija to n waye ni Upper Nile lati bii ọsẹ meloo kan ti da omi alaafia aarin Aarẹ Kiir ati Igbakeji rẹ, Riek Machar, rú.

Ni 2013, ija emi-o-gba, iwọ-o-gba to wa laaarin awọn mejeeji lo bi ogun ti wọn fi ọdun marun-un ja, nibi ti eeyan 400,000, iyẹn ẹgbẹrun lọna irinwo ti di oloogbe.

Eeyan ti ko din ni miliọnu meji aabọ lo si fi ile wọn silẹ nigba naa, ti wọn sa gba ibo mi-in lọ.

Bo tilẹ jẹ pe wọn kọwọ bọwe adehun alaafia ni 2018, sibẹ, alaafia ko jọba niluu naa titi dasiko yii.

Àwọn wo ni wọ́n ń jà ní South Sudan?

Aworan ajuwe South Sudan ati agbegbe rẹ
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ija ajaku akata to n waye lọwọ ni South Sudan wa laaarin awọn ṣọja ilu naa ati awọn kan ti wọn n pe ni Ṣọja funfun (White Army).

Awọn White Army yii jẹ ti ibilẹ. Marchar, Igbakeji aarẹ ni wọn si n ṣiṣẹ fun.

Nigba to n ṣalaye si i nipa awọn to ba ikọlu lọ, Aarẹ Kiir sọ pe Ọgagun Majur Dak, to ṣaaju ikọ ologun to duro ni Nasir,lo di oloogbe.

Lori ikọlu yii, awọn alaṣẹ ti nawọ gan awọn eeyan kan, eyi ti wọn lo ṣee ṣe ko sọ rogbodiayn naa di ogun mi-in.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, awọn eeyan nla ti wọn jẹ ọmọ ẹyin Igbakeji aarẹ, wa lara awọn ti wọn fi ọwọ ofin mu.

Lara awọn eeyan naa ni minisita to wa fun ọrọ epo ati ọga ologun onipo nla kan.

Aarẹ Kirr sọ lẹyin ikọlu ọjọ Ẹti naa, pe kawọn araalu fọkan balẹ, ko ni i siyọnu.

"Mo ti sọ ọ leralera pe orilẹede wa ko ni i pada sinu ogun mọ.

''Ki ẹnikẹni ma ṣe fi ofin sọwọ ara rẹ, ijọba mi ti mo n dari rẹ yii yoo yanju gbogbo ẹ pata."

Ọdun 2011 ni South Sudan ya kuro lara Sudan, ti wọn da duro. Orilẹede yii ko ti i lọjọ lori rara, oun lo kere ju ninu idasilẹ awọn orilẹede lagbaaye.