Wo bí àwọn obiǹrin yìí ṣe dáhùn ìbéèrè láyàájọ́ àwọn obìnrin lágbàáyé fún 2025

Àkọlé fídíò, Idahun awọn ibeere to rọ mọ awọn akọni obinrin lorilẹede Naijiria
Wo bí àwọn obiǹrin yìí ṣe dáhùn ìbéèrè láyàájọ́ àwọn obìnrin lágbàáyé fún 2025

Gbogbo ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹta ọdun ni ayajọ ti wọn ya sọtọ gẹgẹ bi ọjọ awọn obinrin kaakiri agbaye.

Bo tilẹ jẹ pe ọjọ pọ diẹ ninu ọdun ti wọn fi n mọ riri awọn obinrin ju ọkunrin lọ, sibẹ, ti ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹta yii maa n yatọ gedegbe, nitori gbogbo aye ni wọn ti n sami rẹ.

Lati fi ayẹyẹ naa da ara wa lara ya, ka si tun da ara wa lẹkọọ ni BBC Yoruba fi mu awọn obinrin meji wa lati dahun awọn ibeere to rọ mọ awọn akọni obinrin ni Naijiria, bi a ṣe n ṣajọyọ ọjọ awọn obinrin lagbaaye fun ti ódun 2025.

Ẹ jẹ gbadun bi kinni ọhun ṣe lọ lati ẹnu Abilekọ Abosede Ogunjọbi ati Titilayọ Atiba.

Awọn ibeere to rọ mọ aṣa, ẹkọ lẹka ọtọọtọ ati aṣeyọri awọn obinrin ni wọn dahun si pẹlu alaye kikun.