'Ìfẹ́ tí mo ní sí ọ̀bọ ló jẹ́ kí n bẹ̀rẹ̀ eré ìdárayá lílo ọwọ́ àti ẹsẹ̀ fi sáré'
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1
Ó ti pẹ́ ti mo ti fẹ́ràn ọ̀bọ tó sì máa ń wù mí láti mọ eré sá bíi wọn.
Èyí ni ọ̀rọ̀ tó jáde lẹ́nu Kenichi Ito tó máa ń sáré pẹ̀lú ọwọ́ àti ẹsẹ̀, tó sì ń sáré pẹ̀lú ọwọ́ àti ẹsẹ̀ jùlọ ní àgbáyé.
Ito tó máa ń sáré pẹ̀lú ọwọ́ àti ẹsẹ̀ kílómítà ọgọ́rùn-ún láàárín ìṣẹ̀jú àáyá 15.71.
Ó ní ọdẹ kan rò wí pé ẹranko kan ni òun lásìkò tí òun ń gbáradì fún ìdíje tó sì na ìbọn sì òun.
Ó sọ pé òun sáré fò dìde láti sọ fun pé èèyàn ni òun, òun kàn máa ń sáré bí ọ̀bọ ni.
Báyìí, eré ìdárayà lílo ọwọ́ àti ẹsẹ̀ láti fi sáré, tí wọ́n ń pè ní Quadrobics ti ń tàn káàkiri orí ayélujára àti káàkiri àgbáyé pàápàá jùlọ ní orílẹ̀ èdè Russia.
Kódà àwọn ọmọdé náà ti ń ṣeré ọ̀hún àmọ́ àwọn olóṣèlú kan ti ń sọ pé eré náà kò bójú mú àti pé ó lòdì sí àṣà ilẹ̀ Russia.









