Àkọsílẹ̀ iye èèyàn tó bá ìkọlù agbébọn lọ ni 2024 rèé àti ipò tí Nàíjíríà wà nínú ìgbésùnmọ̀mí

Aworan awọn eeyan to wọ aṣọ ologun, ti wọn bo oju wọn ti wọn si n gun alupupu lóko aṣálẹ̀

Oríṣun àwòrán, OTHERS

    • Author, Busayo James-Olufade
    • Role, BBC News Yoruba
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ẹka to n ṣe odiwọn iwa igbesunmọmi ati aibalẹ ọkan lagbaaye, (Global Terrorism Index) ti pin Naijiria si ipo kẹfa ninu awọn orilẹede ti igbesunmọmi ti gbilẹ ju laye.

Ẹka Global Terrorism Index ṣalaye pe Naijiria ti sun kuro ni ipo kẹjọ to wa ni 2023 ati 2024, pẹlu alekun to ba odiwọn iwa ipá to waye, to ti gunke di 7.658 bayii.

Gẹgẹ bi abajade wọn ti wọn fi sita lọjọ karun-un, oṣu Kẹta 2025 ṣe wi, orilẹede Burkina Faso lo lewaju ninu awọn ilu ti aibalẹ ọkanb pọ si, 8.581 ni onka tiwọn.

Orilẹede Pakistan lo ṣikeji, awọn gba 8.374 ninu awọn orilẹede agbesunmọmi.

Syria lo ṣikẹta pẹlu onka 8.006).

Mali wa nipo kẹrin pẹlu onka 7.907.

Niger wa nipo karun-un, onka tiwọn jẹ 7.776. Naijiria wa nipo kẹfa pẹlu onka 7.658.

Àwọn yòókù ni:

Somalia: (7.614), Israel (7.463), Afghanistan (7.262), Cameroon (6.944), Myanmar (6.929), DR Congo (6.768), Iraq (6.582), India (6.410), Colombia (6.381) ati Russia (6.267) lati ipo keje de ikẹrindinlogun.

Òǹkà àwón èèyan tó di olóògbé láti ọwọ́ agbégbọn ní Naijiria ní 2024

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Abajade ẹka yii fi han pe eeyan 565, iyẹn ẹẹdẹgbẹta-le-marundinlaadọrin ni wọn ku lati ọwọ awọn agbebọn ni 2024.

Wọn kede pe alekun ti ba iye iku naa lati ọdun meji sẹyin.

"Lagbaaye, iku awọn eeyan lati ara igbesunmọmi ti dinku to ida mẹta, yatọ si bo ṣe gbilẹ gan-an ni 2015, orilẹede Iraq ati Nigeria si ni adinku ti de ba iku naa ju.

" Iku oro yii de gongo ori ẹ ni Naijiria ni 2014, nigba ti eeyan 2,101 ku lati ọwọ awọn agbebọn, ko too ja walẹ si 392 ni 2022, ṣugbọn ni 2023, iku tun pọ si i ni ida mẹtalelọgbọn (34%), o pada le kun di 533, o si di 565 ni 2024."

Bẹẹ ni abajade Global Terrorism Index, ṣalaye.

Bakan naa ni wọn kede pe orilẹede ti ikọlu ba lagbaaye ti pọ si i, wọn lo gunke lati 58 si 66 lati 2024.

Ẹka yii ṣalaye pe ọpọ orilẹede ni eto aabo wọn ti dinku, o si to ilu marundinlaaadọta (45) ti iwa ipa awọn eeyan ibi naa ti ba.

Orilẹede mẹtalelọgbọn (34) ni wọn ni iyatọ de ba ni ti daadaa lẹka aabo.

Ẹkun Sahel ni wọn pe ni orita idunkooko ati igbesunmọmi, iku to le ni ida aadọta lo waye latara igbesunmọmi nibẹ ni 2024 bi wọn ṣe sọ

"Marun-un ninu orilẹede mẹwaa ti igbesunmọmi ti n ṣẹlẹ ni wọn wa ni Sahel, bo tilẹ jẹ pe, Burkina Faso ni ikọlu naa ba ju. Ikọlu ati iku awọn eeyan latọwọ awọn agbebọn gunke si i ni ida mọkanlelogun ati mẹtadinlọgọta."

Global Terrorism Index lo sọ bẹẹ.