'Àwọn agbéṣùmọ̀mí lẹ́kùn Sahel Africa ló ń ṣekúpa èèyàn jù lágbàáyé'

Ọmọ ogu Mali tó ń gbógun ti ìgbéṣùmọ̀mí

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọmọ ogu Mali tó ń gbógun ti ìgbéṣùmọ̀mí
    • Author, Busayo James-Olufade
    • Role, Senior Journalist
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ẹkùn Sahel ní ilẹ̀ Afirika ni ó jẹ́ oríkò àwọn agbéṣùmọ̀mí báyìí, tí ìwádìí àjọ Global Terrorism Index (GTI), fún ìgbà àkọ́kọ́ sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ibẹ̀ ni ìdajì ikú àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn sọ́wọ́ ìgbéṣùmọ̀mí tgi ń wáyé.

Ìwádìí GTI tuntun sọ pé ẹkùn Sahel ní Afirika ní ìdá mọ́kànléláàádọ́ta (51%) nínú ìdá ọgọ́rùn-ún ikú látara ìgbéṣùmọ̀mí ti wáyé - èyí tó túmọ̀ sí pé ikú 3,885 ló wáyé níbẹ̀ nínú 7,555 tó wáyé káàkiri àgbáyé.

Ìjábọ̀ náà fi kun pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àdínkù bá bí àwọn agbéṣùmọ̀mí ṣe ń ṣọṣẹ́ ní àgbáyé láti ọdún 2015 àmọ́ níṣe ni wọ́n ń ṣọṣẹ́ síi ní ẹkùn Sahel Africa lati ọdún 2019 báwọn agbéṣùmọ̀mí ṣe ń túnbọ̀ láti máa kojú ìjà sí ẹkùn yìí.

Àjọ Institute for Economics and Peace, àjọ tó wà fún ṣíṣe ìwádìí àlááfíà àti wàhálà káàkiri àgbáyé ló ṣe àgbéjáde ìwádìí náà.

Àwòrán tó ṣàfihàn ẹkùn Sahel

Àwọn orílẹ̀ èdè lábẹ́ ẹkùn Sahel Africa gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde GTI jẹ́ orílẹ̀ èdè mẹ́wàá tó fi mọ́ Burkiina Faso, Mali, Niger, Cameroon, Guinea, The Gambia, Senegal, Nigeria, Chad àti Mauritania.

Àwọn orílẹ̀ èdè tó wà lábẹ́ ẹkùn yìí ni wọ́n ń bímọ jùlọ ní àgbàyé, tó sì jẹ́ pé ìdá méjì níní ìdá mẹ́ta àwọn èèyàn ẹkùn náà ni ọjọ́ orí wọn wà lábẹ́ ọdún márùndínlọ́gbọ̀n.

Yàtọ̀ sí àwọn orílẹ̀ èdè tó ti gòkè àgbà níbi tí àwọn agbéṣùmọ̀mí tó jẹ́ aládàni ti ń dìde, ni ẹkùn Sahel, níṣe ni àwọn ẹgbẹ́ àwọn agbéṣùmọ̀mí ń pọ̀ si, gẹ́gẹ́ bí ìwádìí náà ṣe sọ àti pé ẹgbẹ́ agbéṣùmọ̀mí méjì: Islamic State àti Jama'at Nusrat al-Islam wal Muslimeen (JNIM), ẹ̀ka ìjọ al-Qaeda ló ń ṣe ìkọlù náà.

Alága ìgbìmọ̀ African Security Sector Network, Niagale Bagayoko ní àwọ agbéṣùmọ̀ mí náà ń gbiyànjú láti gbé ìlànà òfin tuntun kalẹ̀ nipa lílo ìlànà òfin Sharia láwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n wà.

Ó ní èyí sì ń fa kí wọ́n máa díje láàárín ara wọn fún ilẹ̀ àti láti ni ipa ní agbègbè kóówá wọn.

Máàpù Sahel
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Wọ́n ní àlékún ti bá àwọn agbéṣùmọ̀mí ti ikọ̀ Islamic State ń ṣe àkóso rẹ̀ ní ìlọ́po méjì ní orílẹ̀ èdè Mali láti ìgbà tí ìdìtẹ̀gbàjọba tí wáyé ní orílẹ̀ èdè náà lọ́dún 2020 sí 2021 – èyí tó wọ́pọ̀ ní ẹnubòdè pẹ̀lú Burkina Faso àti Niger – bí ìjọ JNIM náà ṣe ń gbìyànjú láti lékún ibi tí ọwọ́jà wọn dé gẹ́gẹ́ bí àwọn onímọ̀ UN nipa Mali ṣe sọ.

Ìwádìí GTI náà sọ pé àwọn ẹgbẹ́ méjéèjì ló ń gbá èèyàn kúnra, tí wọ́n sì fẹ̀sùn kàn pé àwọn Islamic State ń gba àwọn ọmọdé kúnra.

Beverly Ochieng tó jẹ́ ọ̀gá àgbà nídìí ṣíṣe àgbéyẹ̀wò ọ̀rọ̀ ní Francophone Africa at Control Risks ní ọ̀pọ̀ èèyàn ni kìí lè padà mọ́ nígbà tí wọ́n bá ti pinnu láti darapọ̀ mọ́ ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí.

Ìwádìí GTI ṣàlàyé bí ètò àìṣedédé lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú àti ìṣèjọba tí kò dúró ire ń jẹ́ kí ìgbéṣùmọ̀mí peléke sib í wọ́n ṣe nàka sí aáwọ̀ tó ń wáyé ní ẹkùn náà wà lára nǹkan tó ń àlékún ìgbéṣùmọ̀mí.

Ẹkùn Sahel ti wọ́n máa ń pè ní ààri gbùngbùn ilẹ̀ Africa. Láti ọdún 2020, ìdìtẹ̀gbàjọba mẹ́fà ló ti wáyé ní ẹkùn náà: méjì ni Mali, méjì ní Burkina Faso, ọ̀kan ní Guinea àti Niger. Àwọn ológun ló ń ṣàkóso àwọn orílẹ̀ èdè náà báyìí.

Dókítà Folahanmi Aina, onímọ̀ nipa SOAS ní ilé ẹ̀kọ́ gíga University of London ní ẹk[-un Sahel ti rí ìjákulẹ̀ tó pọ̀ lórí nǹkan tó ń jẹ́ orílẹ̀ èdè.

"Bí àwọn olórí orílẹ̀ èdè láwọn ẹkùn yìí ṣe ń gbé àwọn ètò tó máa ṣe àwọn èèyàn wọn tì ló ń bí báwọn ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí ṣe ń dìde, tí wọ́n sì ń dàgbàsókè."

Àwọn ológun méjì tó gba ní Niger ọ̀gágun Abdourahamane Tiani àti akẹgbẹ́ rẹ̀ ní Burkina Faso, Captain Ibrahim Traoré

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Capt Ibrahim Traoré ti Burkina Faso àti Abdourahamane Tiani jẹ́jẹ̀ẹ́ láti kojú ìgbéṣùmọ̀mí nígbà tí wọ́n fipá gba ìjọba

Ìgbàgbọ́ wà pé àwọn ìjọba alágbádá kò rí ojútùú sí ìdúnkokò àwọn agbéṣùmọ̀mí lórí ètò ààbò àmọ́ kò ì tíì sí ìyàtọ̀ kan tó fojú hàn láti ìgbà táwọ ológun náà ti gba ìjọba, wọn kò ì tíì mú àyípadà kan gbòógì bá ohun tó wà nílẹ̀ àti pé ètò ààbò tún burú si ni.

Dókítà Aina ní àwọn ológun tó ń gbàjọba náà kò gbáradì fú iṣẹ́ takuntakun tó wà nídìí ìṣèjọba.

GTI sọ pé orílẹ̀ èdè Burkina Faso ni orílẹ̀ èdè tí àwọn agbéṣùmọ̀mí ti ṣọṣẹ́ jùlọ lọ́dún láàárín ọdún méjì síra wọn lọ́dún 2024. Láàárín ọdún mẹ́rìnlá tí ìwádìí náà ti bẹ̀rẹ̀, ohun ni orílẹ̀ èdè tó gba ipò kìíní mọ́ Iraq àti Afghanistan lọ́wọ́.

Àwọn ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí yìí ni wọ́n máa ń hu àwọn ìwà kò tọ́ bíi ìjínigbé láti fi gba owó àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ gẹ́gẹ́ bí ìjábọ̀ GTI ṣe sọ.

Bákan náà ni àwọn tó ń gbé egbògi olóró láti South America sí Europe ń ṣàmúlò ẹkùn náà láti fi ṣe iṣẹ́ láabi wọn, tí wọ́n sì ka gbígbe egbògi olóró gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan táwọn agbéṣùmọ̀mí ń lò láti fi kówó jọ ní ẹkùn náà.

Ó wòye pé àwọn ikọ̀ kan máa ń ggbìyànjú láti ma kópa nínú ìwà ọ̀daràn ṣùgbọ́n tí wọ́n máa ń wá owó nípasẹ̀ gbígba owó orí tàbí pípèsè ààbò fáwọn èèyàn láti gfi gba owó.

Àwọn ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí ń gbèrò láti ṣàkóso àwọn ohun àlùmọ́nì ẹkùn Sahel. Niger ni orílẹ̀ èdè keje tó ń pèsè Uranium ní àgbáyé, táwọn ikọ̀ IS àti JNIM sì ń ṣàmúlò àlùmọ́nì wura ní orílẹ̀ èdè náà.

Ọkùnrin tó ń wakùsà ní Burkina Faso

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ìwàkusà wúrà tí wọn kò mójútó ní Sahel ń fa àlékún ìgbéṣùmọ̀mí

Lẹ́yìn àwọn ìdìtẹ̀gbàjọba tó wáyé, àwọn ìjọba ẹkùn Sahel gbìyànjú láti kẹ̀yìn sí àjọṣepọ̀ tí wọ́n ní pẹ̀lú àwọn orílẹ̀ èdè bíi France àti US, tí wọ́n sì ń tọ China àti Russia fún ìrànlọ́wọ́ láti kojú àwọn agbéṣùmọ̀mí.

"Ní báyìí, à ń ri pé Russia ń ṣe àkóso àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tó wà ní ẹkùn tí wọ́n ń pè ní Africa Corps èyí tí wọ́n ń pè ní Wagner tẹ́lẹ̀," Ochieng sọ. Iṣẹ́ wọn ni láti ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti àtìlẹyìn fáwọn ọmọ ogun láti lè kojú àwọn agbéṣùmọ̀mí àmọ́ èyí kò ì tíì kẹ́sẹ járí.

Fún ìdí èyí, ìwádìí GTI ṣèkìlọ̀ pé ó ṣeéṣe kí ewu rẹ̀ kọjá ọ̀rọ̀ àwọn agbéṣùmọ̀mí àti pé o ṣeéṣe kó tàn dé àwọn orílẹ̀ èdè tó súnmọ́ wọn. Kódà, ó ṣeéṣe kí èyí ti máa wáyé bí Togo ṣe ní àkọ́ọ́lẹ̀ ìkọlù mẹ́wàá àti ìpànìyàn méjìléláàádọ́ta lọ́dún 2024.

Ochieng fara mọ́ ìjábọ̀ yìí bí ó ṣe ní ó ṣeéṣe kí ìgbéṣùmọ̀mọ̀mí tàn dé àwọn orílẹ̀ èdè bíi Benin, Togo àtàwọn orílẹ̀ èdè míì ní ìwọ̀ oòrùn Africa.