Kí ló dé tí ìjọba US ṣe fẹ́ dènà físà àwọn ọmọ Naijiria kan, òṣìṣẹ́ ìjọba àti ẹbí wọn?

US President Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Pete Marovich/Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba orilẹede Amẹrika ti kede igbesẹ tuntun lori fifun awọn eeyan kan ti wọn fẹsun kan pe wọn lọwọ ninu rogbodiyan nipa iṣekupani awọn Kristẹni lorilẹede Naijiria ati lagbaye.

Igbesẹ yii ni ko ni fi aye agba awọn ọmọ Naijiria kan, awọn oṣiṣẹ ijọba ati awọn mọlẹbi wọn.

Akọwe ijọba, Marco Rubio ni pe ile ijọba Washington n gbe igbesẹ yii lori aṣẹ Aarẹ Trump lati gbe ogun ti awọn eeyan kan ti wọn lọwọ ninu kiko ogun ja ati iṣekupani awọn Kristẹni ni Naijiria ati kaakiri agbaye."

Ninu atẹjade to fi lede, o ni ijọba ko ni fi aye gba awọn eeyan yii ti wọn lọwọ ninu iwa yii, fi owo dasi tabi gbe eyikeyi igbesẹ tako ominira ẹsin ni anfani lati wọ orilẹede Amẹrika.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ọ kilọ pe ofin fisa gbigba lo kan awọn eeyan Naijiria ati awọn oṣiṣẹ ijọba ti o ba kọlu awọn eeyan nitori igbagbọ wọn.

Igbesẹ, labẹ ofin irinajo lorilẹede Amẹrika faye gba ijọba lati fun awọn eeyan yii ni anfani lati wọ orilẹede Amẹrika to fi mọ awọn mọlẹbi wọn.

Ikede yii waye lẹyin ti awọ bẹ silẹ laarin orilẹede Amẹrika ati Naijiria lori ẹsun pe awọn Kristẹni n koju iṣekupani.

Bẹẹ ba gbagbe, Aarẹ Amẹrika, Donald Trump leri lati ko ogun wọ Nàìjíríà lati fina mọ awọn agbesunmọni to ni wọn on doju kọ awọn Kristẹni, gẹgẹ bii atẹjade kan to fi sita loju opo ayelujara ṣe ṣalaye.

Trump tun fẹsun kan ijọba Naijiria pe wọn faye gba iṣekupani awọn Kristẹni.

Ninu ọrọ to gbe sita soju opo ikanni Truth rẹ lọjọ Satide, Trump ni ileeṣẹ ologun Amẹrika le wọle si Naijiria pẹlu awọn ọmọ ologun lati kọlu awọn to pe ni alakakiti agbesunmọmi alakatakiti ẹsin islam to ni wọn n ṣekupa awọn Kristẹni ni Naijiria.

Bakan naa lo tun leri oun yoo dawọ gbogbo iranwọ ti Amẹrika nnfi ṣọwọ si Naijiria duro..

Ijọba Naijiria fesi si ẹsun ti Trump fi kan an naa, to sì tọka ẹsun naa gẹgẹ bii iroyin ẹlẹjẹ ati ahesọ ọrọ ti ko l'ẹsẹ nlẹ rara.

Trump tẹsiwaju ninu atẹjade naa pe oun ti paṣẹ fun awọn ẹka ologun ilẹ Amẹrika lati bẹrẹ igbesẹ tako orilẹede Naijiria- "bi ijọba Naijiiia ba tun daba to ba faye gba iṣekupani awọn Kristẹni,".