Kí ló fà á tí ọ̀nà Circular Road n'Ibadan tó yẹ kó mú inú aráàlú dùn ṣe ń gba omijé lójú wọn?
Irinajo Circular Road bẹrẹ lati igba iṣejọba Gomina Rasheed Adewolu Ladoja, titi to fi kan Gomina Seyi Makinde.
Lọdun yii, Gomina Makinde gbe aba isuna ₦891,985,074,480.27 kalẹ niwaju awọn asofin ipinlẹ naa fun ijiroro ati fifi ontẹ lu fun ọdun luu fun ti ọdun 2026.
Bẹẹni ọna Circular Road yii jẹ ọkan lara ohun ti ijọba ipinnu lati ṣe fun ọdun to n bọ.
Ṣugbọn igbesẹ yii n pa ọpọ araalu Ibadan lẹkun.
Ọpọ awọn olugbe ijọba ibilẹ mẹfa ni ilu Ibadan, olu ilu Ipinlẹ Oyo fi ehonu han lọjọ Aje ọjọ kẹwaa oṣu kọkonla ọdun 2025 lori bi ijọba Ipinlẹ Oyo se n wo dukia won lulẹ.
Awon olugbe ijọba ibilẹ, Egbeda, Ido, Akinyele, Ona Ara, Lagelu ati Oluyole ni wọn ko ara wọn jọọ lori bíi ijọba Ipinlẹ oyo ti fe yoo meter 500 si apa ọtun ati osi opopona obiripo (Circular Road) ti ijọba Ipinlẹ oyo nṣe lọwọ.
Awọn olugbe awọn agbegbe ọhun lọ ni bi ijọba ipinlẹ Oyo ba tesiwaju pẹlu igbesẹ yìí, o le ni eeyan ẹgbẹrun lọna ọọdunrun 300,00, ti yoo di alainilelori ni ijọba ibilẹ mẹfefa ti opopona naa yoo gba kọja.
BBC ṣe akojọpọ alaye lori irinajo Circular Road ati ibi ti ọrọ de lasiko yii.






