Ijó, ayọ̀ báwọn èèyàn 38 tí wọ́n jí gbé ní Eruku ṣe padà sílé

Awọn janduku agbebọn faṣọ boju ati awọn eeyan ilu Eruku niwaju ile ijọsin CAC nipinlẹ Kwara.

Oríṣun àwòrán, Getty Images/BBC

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 10

Olujọsin mejidinlogoji ti wọn ji gbe ni ile ijọsin CAC ni ilu Eruku, ijọba ibilẹ Ekiti, ipinlẹ Kwara lọjọ Kejidinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2025 ti pada sile ile wọn.

Atẹjade kan ti agbẹnusọ ijọba ibilẹ Ekiti fi lede lọjọ Keji, oṣu Kejila sọ pe awọn eeyan naa ti pada si ile wọn bayii.

O ni gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrasaq ko awọn eeyan naa le alaga ijọba ibilẹ Ekiti, Awelewa Olawale Gabriel lọwọ.

Nigba to n gba awọn eeyan naa, Awelewa dupẹ lọwọ Aarẹ Bola Tinubu, Gomina AbdulRasaq atawọn ẹṣọ aabo latari bi wọn ṣe tete gba itusilẹ awọn eeyan naa kuro ni akata awọn ajinigbe.

O ni ajọṣepọ awọn ẹṣọ aabo ati ijọba lo jẹ ki wọn tete gba itusilẹ awọn eeyan naa ati pe nnkan bii aago mẹfa abọ irọlẹ ọjọ Iṣẹgun ni awọn eeyan naa pada sile tawọn araalu si fi ijo ati ọyaya gba wọn pada.

Alaga ijọba ibilẹ naa fi kun pe ijọba yoo tunbọ maa tẹsiwaju lati maa da aabo bo gbogbo awọn eeyan ati dukia ni gbogbo ẹkun mẹwaa to wa nibẹ.

Ẹ o ranti pe Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu, ti kede pe awọn eeyan mejidinlogoji (38) ti awọn ajinigbe ji gbe ni ṣọọṣi CAC Oke-Iṣẹgun, nipinlẹ Kwara, ti gba ominira bayii.

Irọlẹ ọjọ Aiku, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kọkanla ọdun 2025 ni Aarẹ Tinubu kede bẹẹ loju opo X rẹ.

Lati igba naa ni awọn eeyan ọhun si ti wa pẹlu ijọba Kwara nibi ti wọn ti n gba itọju lori ikọlu naa.

Èèyàn 38 tí wọ́n jí gbé l'Eruku ti gba ìtúsílẹ̀- Ààrẹ Bola Tinubu

Aare Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Aare Bola Tinubu

Nigba to n ṣalaye itusilẹ naa, Aarẹ Tinubu sọ pe :

"Ẹ o ranti pe mo fagile irinajo mi lọ sibi ipade G20 to yẹ ko waye lorilẹede South Africa, lati le mojuto aabo nile.

"Ọpẹ fun awọn ẹṣọ alaabo wa lati bii ọjọ meloo sẹyin, gbogbo awọn olujọsin 38 ti wọn ji gbe ni Eruku, ipinlẹ Kwara ni wọn ti ri idande bayii."

Bakan naa ni Aarẹ fi kun un pe mọkanlelaaadọta (51) ninu awọn akẹkọọ ti wọn ji gbe nile ẹkọ awọn Katoliiki nipinlẹ Niger ni wọn ti pada sile .

"Mo n tọpinpin bi eto aabo ṣe n lọ kaakiri orilẹede Naijiria , mo si n gba iroyin nipa bo ṣe n lọ"

Gẹgẹ bo ṣe wi, Tinubu ni oun ko ni i sinmi lori eto aabo, o ni gbogbo ọmọ Naijiria lo ni ẹtọ si aabo to peye.

Labẹ iṣakoso oun si ree, oun yoo ri i pe oun da aabo bo awọn ọmọ Naijiria bo ṣe yẹ

Pasito to waasu lọjọ isinmi oni, ni ṣọọṣi CAC Oke-Isegun, Eruku, ipinle Kwara

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Lẹ́yìn ìkọlù agbébọn, ìsìn ọjọ́ ìsinmi wáyé ní ṣọ́ọ̀ṣì CAC, Eruku, pásítọ̀ ní káwọn ọmọ ìjọ má ṣe bẹ̀rù ikú

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lẹyin ọjọ marun-un ti awọn agbebọn kọlu ṣọọṣi CAC ilu Eruku, nipinlẹ Kwara, isin ọjọ isinmi waye ni ṣọọṣi naa lonii, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kọkanla ọdun 2025.

Ninu ọrọ iwaasu alufa ijọ naa, o rọ awọn ọmọ ijọ lati ma ṣe bẹru iku, ki wọn si ma ṣe sẹ́ Jesu Oluwa ninu ohun gbogbo.

Gẹgẹ bo ṣe wi ninu fidio ijọsin naa ti wọn fi sori ayelujara, pasitọ to waasu naa ni:

"Gẹgẹ bii onigbagbọ, ẹ ko gbọdọ bẹru wọn. Jesu ti ṣeleri iye ayeraye fun wa. Ẹ ma jẹ ka bẹru iku, ibikibi ti iku ba ti de, ma sẹ́ Jesu.

" To o ba ti sẹ́ Jesu, ileri yii wa fun ọ, wi pe Ọmọ Alade Alaafia n mu ọ lọ si ijọba alaafia.

"Aye yii lopin o, ṣugbọn ijọba ti Jesu n bọ waa ṣe ko lopin, ijọba ayeraye ni, oun lo fi sọ pe ki a ma ṣe jẹ ki ọkan wa daru."

Bẹẹ ni Alufa naa wi.

Ẹ o ranti pe ikọlu awọn agbebọn si sọọṣi CAC Oke Isegun, niluu Eruku, ijọba ibilẹ Ekiti nipinlẹ Kwara, waye lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla

Odun 2025.

Eeyan mẹta ni iroyin sọ pe o ku ninu ikọlu naa, ọpọ eeyan lo si w ani igbekun awọn ajinigbe naa titi di asiko ti a n kọ iroyin yii, ti ajinigbe n beere owo gọbọi lati tu wọn silẹ.

Ẹgbẹ́ CAN ìpínlẹ̀ Kwara fagilé ìsìn orin ọdún Kérésìmesì, látàri ìkọlù àwọn agbébọn

Aworan awọn ẹgbẹ akọrin ti wọn wọ aṣọ pupa, wọn de fila wọn si mu iwe orin dani

Oríṣun àwòrán, @CAN Kwara

Ẹgbẹ ọmọ lẹyin Kristi (CAN), ẹka ti ipinlẹ Kwara, ti fagile ayẹyẹ isin orin ọdun Keresimesi tọdun yii to yẹ ko waye ni ọjọ Aje, ọjọ kin-in-ni oṣu Kejila, ọdun 2025 .

Wiwọgile ayẹyẹ orin ọdun Keresimesi naa waye latari ikọlu awọn agbebọn to ṣẹlẹ ninu ijọ CAC Eruku, nijọba ibilẹ Ekiti, ipinlẹ Kwara, nibi ti wọn ti ṣekupa awọn olujọsin ti wọn si tun ji awọn mi-in gbe lọ.

Ẹgbẹ CAN ipinlẹ Kwara ni inu ọfọ lawọn ọmọlẹyìn Kristi wa bayii latari iṣẹlẹ naa, eyi ti ki i ṣe akọkọ iru ẹ.

Ẹgbẹ naa ni awọn kẹdun pẹlu gbogbo awọn mọlẹbi tọrọ naa kan, ijọ Ọlọrun ati apapọ awọn eeyan ilu Eruku.

Gẹgẹ bi ẹgbẹ ọmọ lẹyin Kristi, wọn ni awọn ko le tẹsiwaju ninu ayẹyẹ naa niru akoko yii ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa wa ninu ọfọ.

Ẹgbẹ CAN ni ifagile ayẹyẹ isin orin ọdun Keresimesi tọdun yii jẹ ibanikẹdun ati ibọwọ fun awọn to padanu ẹmi wọn, pẹlu awọn to f'arapa nibi ikọlu naa.

CAN Kwara dupẹ lọwọ Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazak, fun atilẹyin rẹ ati ilakaka rẹ.

'A rọ gómìnà kó fi kún ìgbìyànjú rẹ̀ lórí àwọn tí wọ́n jí gbé lọ'

Gomina ipinle Kwara, Abdulrahman Abdulrazak ati awọn ikọ rẹ

Oríṣun àwòrán, @CAN Kwara

Atẹjade kan lati ọwọ Alaga ẹgbẹ (CAN) ipinlẹ Kwara, Bishop Adewole, sọ pe awọn ba Gomina ipinlẹ naa kẹdun, awọn si rọ ọ lati fi kun igbiyanju rẹ lori bi wọn yoo ṣe sawari awọn ti wọn ji gbe, ki idajọ ododo waye, ki àláfíà si pada si ilu naa.

Ẹgbẹ naa ke si gbogbo ọmọlẹyìn Kristi nipinlẹ Kwara lati darapọ mọ adura ọlọjọ mẹta kan ti wọn lo da lorii títu awọn mọlẹbi awọn eeyan tọrọ yii kan ninu.

Ikeji ni dida awọn ti wọn ji gbe pada layọ ati imularada awọn to farapa.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ iṣẹgun, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla ọdun 2025 ni awọn agbebọn yawọ inu ijọ CAC niluu Eruku, lasiko ti wọn n ṣe isin lọwọ, ti wọn si ṣekupa eeyan mẹta, ji eeyan mejidinlọgbọn gbe.

Àwọn agbébọn tó jí àwọn olùjọsìn gbé ní Kwara mú àdínkù bá owó ìtúsílẹ̀ di ogún mílíọ̀nù náírà fún ẹnìkọ̀ọ̀kan

Awọn ajinigbe to ji awọn olujọsin mẹtadinlogoji ni ile ijọsin CAC gbe ni ilu Eruku, ipinlẹ Kwara ti mu adinku ba iye ti wọn n beere fun gẹgẹ bi owo itusilẹ.

Awọn ajinigbe naa ti n beere fun ogun miliọnu naira gẹgẹ bi owo itusilẹ fun ẹnikọọkan lodi si ọgọrun-un miliọnu naira ti wọn ti ṣaaju beere.

Ọba ilu Eruku, Ọba Busari Olarewaju lo fidi ọrọ naa mulẹ fun BBC News Yoruba ni owurọ ọjọ Ẹti, ọjọ Kọkanlelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2025.

Ọba Olanrewaju ni awọn ko i tii mọ ohun to maa jẹ ṣiṣe lori lati wa owo naa fun eeyan mẹtalelogoji.

Àwọn agbébọn tó jí olùjọsìn 37 ìjọ C.A.C. gbé ní Kwara ń bèèrè fún N300m láti tú wọn sílẹ̀

Ṣaaju ni awọn janduku agbebọn to ya bo ile ijọsin CAC ni ilu Eruku nijọba ibilẹ Ekiti ni ipinlẹ Kwara ti beere fun ọdunrun un miliọnu naira (N300m) lati tu awọn eeyan mẹtadinlogoji ti wọn ji gbe silẹ

Ohun ti a gbọ ni pe awọn ajinigbe ọhun ti pin awọn eeyan ti wọn ji gbe si isọri mẹta.

Kabiyesi ilu Eruku, Ọba Busari Olarewaju, salaye pe awọn ajinigbe naa ti kan si ẹbi awọn ti wọn ji gbe lati wa sanwo itusilẹ fun wọn.

Ọba Ọlarewaju ṣalaye siwaju si pe wọn ni ki isọri kọọkan san ọgọrun kan mílíọ̀nù naira ti apapọ owo naa si jẹ ọdunrun un milionu naira.

Ọkan lara awọn ọdọ ilu naa, Ọgbẹni Ṣogo fidi rẹ mulẹ pe ẹrọ ibanisọrọ awọn ti wọn ji gbe ni awọn ajinigbe fi ba mọlebi wọn sọrọ.

O salaye pe awọn ajinigbe naa ni kawọn ti wọn ji gbe pe mọlẹbi wọn lati fi beere fun owo itusilẹ.

Sogo fikun ọrọ rẹ pe ọkan lara awọn oloye ilu, Olusẹgun Olukọtun, to ni mọlẹbi mẹrin ninu awọn ti wọn ji gbe sọ pe awọn ajinigbe ti pe oun.

Bakan naa, ilu Eruku ti ṣagbejade orukọ awọn mẹtadinlogoji ti wọn ji gbe.

Ninu ọrọ tiẹ, alaga ijọba ibilẹ Ekiti nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Gabriel Awẹlẹwa naa jẹrii pe awọn ajinigbe ti pe awọn mọlebi awọn ti wọn ji gbe.

O ni awọn o si mọ idi ti wọn fi pin wọn si isọri mẹta, nitori awọn ti wọn ji gbe lo sọ lori ẹrọ ibanisọrọ pe, wọn ti pin awọn si isọri mẹta.

Lasiko to n sọrọ, ọkan lara ọdọ ilu naa, Lekan ni awọn o mọ ọna ti awọn fẹ gbe ọrọ yii gba.

Lekan ni owo ti wọn n beere fun ti pọju, o ni awọn obinrin ti sa kuro ni ilu tan wi pe awọn ọkunrin nikan lo ku.

Ìjọba Kwara gbé àwọn ilé ẹ̀kọ́ tì pa níjọba ìbílẹ̀ márùn-ún lẹyìn ijínigbé àtí ìpánìyàn tó wáyé ní ìjọ CAC ìlú Eruku

Gomina Abdulrahman Addulrasaq ipinlẹ Kwara, awọn ọlọpaa ati ile ijosin CAC ilu Eruku

Ṣaaju ni ijọba ipinlẹ Kwara ti gbe gbogbo awọn ile ẹkọ alakọbẹrẹ ati girama to wa ni ijọba ibilẹ marun-un ti pa lẹkun gusu ipinlẹ naa tori bi ọrọ eto abo se ri bayii nibẹ.

Awọn ijọba ibilẹ tọrọ naa kan ni, ìjọba ibilẹ Ekiti, Isin, Oke ẹrọ, Ifẹlodun ati Irẹpọdun ti gbogbo wọn wa ni lẹkun Gusu ipinlẹ Kwara.

Titi pa awọn ile ẹkọ naa ko sẹyin bọrọ eto abo ṣe n buru si i lẹkun naa.

Alaga ẹgbẹ awọn olukọ ipinlẹ Kwara (NUT), Kọmureedi Yusuf Agboọla, sọ ninu atẹjade kan to fi sita pe ijọba ti awọn ile ẹkọ naa pa latari ipenija ọrọ eto abo.

O salaye pe ki awọn olukọ kiyesi atẹjade yii, ati pe bi nnkan ba se ri awọn yóò pada fi to wọn leti.

Ninu ọrọ rẹ, alakoso awọn olukọ nijọba ibilẹ Isin, Oloye Lere Balogun, naa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ.

Kọmisọna feto ẹkọ ni ipinlẹ Kwara, Dr Lawal Ọlọrungbẹbẹ naa sọ pe ijoba ipinlẹ gbe igbesẹ yii lati daabobo awọn akẹkọọ ni.

O fi kun un pe ijọba fẹ ki aabo to peye wa fun awọn akẹẹkọ to fi mọ awọn akẹẹkọ to n gbe lọgba ile ẹkọ.

Gbogbo ile ẹkọ ijọba ati aladani lọrọ naa kan bayii lawọn ijọba ibilẹ marun-un ọhun.

Ni irọlẹ ana ni ibẹrubojo gbalẹ pe, awọn ajinigbe fẹ kọlu ile ẹkọ Anglican Girls College Iludun Oro, ṣugbọn ti ijọba tete ko awọn ẹṣọ alabo sọwọ si ile ẹkọ naa.

Titi awọn ile ẹkọ pa yii waye lẹyin wakati merinlelogun tawọn agbebọn kọlu ile ìjọsìn CAC niluu Eruku nijọba ibilẹ Ekiti nibi ti wọn pawọn olujọsin, ti wọn si ji awọn ọmọ ijọ marundinlogoji gbe lọ.

Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazak naa sabẹwo si ilu Eruku l'Ọjọru lati bawọn kẹdun, to si bẹnu atẹ lu iṣẹlẹ ikọlu naa.