Ọmọ kan ṣoṣo tí Idayat bí kú sí kànga ní Kwara

Awọn abanikẹdun ati kanga ti Abdullateef bẹ si
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Isẹlẹ buruku kan sẹlẹ niluu Ilorin, ipinle Kwara, lọjọ Aiku oni ti i ṣe Sannde, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kọkanla ọdun 2025.

Ọkunrin ẹni ọdun mokanlelogbon (34) ti orukọ rẹ n jẹ Abdullateef lo ṣadeede bẹ sinu kanga, to si ku sinu rẹ.

BBC News Yoruba ri i gbọ pe iṣẹlẹ laabi yii sẹlẹ lagboole Bolarinwa, ni agbegbe Centre Igboro, ni deede aago mẹrin owurọ ọjọ Sannde oni.

Nigba ti BBC sabẹwo si ile naa, awọn abanikẹdun pọ nibẹ ti wọn n tu iya oloogbe naa, Idayat Ahmed, ti ko bi ju Lateef nikan lọ, ninu.

Idayat ninu alaye rẹ sọ pe:

"Ọmọ mi kì í bá èèyàn jà, lẹ́yìn kó kírun nikan"

Iya Abdullateef ni:

"Ni ana ni wọn deede ransẹ si mi lati ile awọn obi mi pe Abdullateef sọ pe oun ṣẹ mi, pe ki n foriji oun.

"Mo da wọn lohun pe ọmọ mi ko ṣe nnkan kan fun mi, ṣugbọn to ba ni ẹsẹ to ṣẹ ti mi o mọ, mo dariji i.

"Lẹyin naa ni a jọ pada sile, mo ṣe irẹsi sugbọn ko jẹ ẹ, nitori o n gba aawẹ lọwọ. O ni ki n jẹ koun kọkọ kirun.

Nigba to n tẹsiwaju ninu alaye rẹ, Iya Abdullateef sọ bo ṣe di pe ọmọ rẹ di ero inu kanga.

"Igba to pẹ, mo lọ yọju wo o, mo si tun ba a lori irun kiki naa. Igba to ṣetan, mo fun un loogun ko lo, ki o le sun, ṣugbọn ko sun, ohun to n sọ ni, 'Allahu, Allahu.''

"Koda, mo ba igo to jabọ lọwọ rẹ, to ti fọ silẹ, bi mo ṣe mu un wa sile awọn ẹbi mi niyẹn ni oru ana Satide mojumọ oni Sannde.

"Lẹyin naa ni emi pada sile ọkọ mi, sugbọn mi o le sun. Igba to ya ni mo gba ipe, pe ọmọ mi ti ko sinu kanga."

Nipa iru eeyan ti Abdullateef jẹ, iya rẹ ṣalaye pe ọmọ to bẹru ija jija ni, o ni ki i ba eeyan ja, lẹyin ko kirun nikan.

Nigba to n dahun ibeere boya ọmọ rẹ ni akọsilẹ aarun ọpọlọ, Idayat dahun pe ọmọ oun ko ni aisan ọpọlọ rara.

Abdullateef jẹ́ ọmọ líle - Ọkọ ìyá Olóògbé

Oku Abdullateef

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Oku Abdullateef

Ninu ọrọ tirẹ, ọkọ Iya Abdullateef, Ahmed, sọ pe ọmọ lile ni Oloogbe.

Ahmed sọ pe oun ti ba Abdullateef ja lori lilo awọn oogun to le sakoba fun ara.

O ni awọn oogun oloro bi Colorado jẹ awọn oogun to yẹ ki awọn ọdọ jina sii.

Ọkọ Iya Oloogbe naa sọ pe kurukẹrẹ ti oun ati iya rẹ n gbọ ninu yara rẹ lo mu awọn lọ bẹ ẹ wo.

"Sugbọn igba ta a debẹ, o ti fọ awọn igo silẹ.

"Ko ma ba se iya rẹ leṣe la ṣe gbe e wa si ile ẹbi awọn iya rẹ, ti awọn ọkunrin wa lati boju to o.

"Ohun ti a gbọ ni pe o fọ ilẹkun yara ti wọn fi si jade, o si tun ja kọkọrọ kanga, ko to wa bẹ sinu rẹ.

"Ṣe ẹ mọ pe kanga to ba wa lagboole, titipa lo maa n wa ni gbogbo igba, amọ Abdullateef fi ipa ja, o si bẹ sinu rẹ kawọn eeyan too de.

"O jẹ iṣẹlẹ to ṣe ni laanu pupọ, amọ a gba fun Olorun, nitori ko si ohun kan ti a le se."

Bẹẹ ni ọkọ Iya Abdullateef ṣalaye.

Iléeṣẹ́ panápaná Kwara sọ̀rọ̀

Ṣaaju ni agbẹnusọ ajọ panapana ipinlẹ Kwara, PFO Hassan Hakeem Adekunle, ti fi atẹjade lede pe, awọn gba ipe pajawiri lati agboole Bolarinwa, ni Centre Igboro, Ilorin.

Atẹjade naa sọ pe ọkunrin ẹni ọdun mọkanlelọgbọn kan, Abdullateef lo bẹ sinu kanga.

O sọ pe iwadii fi han pe o ti fẹ bẹ sinu rẹ tipẹ ti wọn o gba a laaye, sugbọn o ri i ṣe nigba ti awọn eeyan ti sun.

O ni igba ti awọn fi maa yọ ọ jade, oku rẹ ni awọn yọ.

Lẹyin naa ni wọn gbe oku naa fun olori ile wọn, Alhaji Bolarinwa.