Orílẹ́èdè Afirika mẹ́wàá tí ìjọba ti náwó jùlọ lórí ètò ààbò lọ́dún 2025

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orilẹede Egypt lo ṣe ipo kinni ninu awọn orilẹede Afirika mẹwaa to nawo julọ lori eto aabo lọdun 2025.
Ikanni kan ti wọn n pe orukọ rẹ ni global military information lo fidi ọrọ yii mulẹ.
Lara awọn nnkan ti wọn lo lati mọ awọn orilẹede to nawo sori eto abo julọ ni iye awọn ọmogun ti orilẹede kọọkan lo, irinṣẹ ijagun ati bi ileeṣẹ ọmogun oju ofurufu ati oju omi wọn ṣe lagbara to.
Wọnyi lawọn orilẹede Afirika mẹwaa to nawo julọ lori eto aabo lọdun 2025 yii:
Egypt
Orilẹede Egypt ni akọkọ ninu awọn orilẹede ilẹ Afirika to lo awọn ọmogun oriilẹ julọ lọdun yii.
Egypt lo oniruuru ọkọ ijagun, irinṣẹ ologun ati baalu ijagun julọ ni Afirika lọdun 2025.
Iroyin lati ori ikanni global military information fidi rẹ mulẹ pe $5.88bn ni Egypt ti na lori eto aabo lọdun yii.
Algeria
Ọmogun igbalode ati eyi to ti wa tipẹ ni wọn wa ninu ọmogun orilẹede Algeria.
Awọn ọmogun oju omi ati ti ofurufu wa, bakan naa lawọn ọmogun mii tun wa lọtọ fun awọn iṣẹ mii.
Ileeṣẹ ologun ofurufu orilẹede Algeria lagbara gan an.
Ileeṣẹ ọmogun oriilẹ Algeria gbajugbaja nipa dida aabo bo ibode orilẹede naa pẹlu awọn orilẹede apa ariwa Afirika yooku.
Iroyin fidi rẹ mulẹ pe awọn ọmogun Algeria wa kaakiri ibode orilẹede naa to fi mọ eti okun Mediterranean Sea.
$25bn ni ikanni global military information sọ pe Algeria ti na lori eto aabo lọdun yii.
Nigeria
Agbara ileeṣẹ ologun Naijiria wa ninu iye ọmogun ti Naijiria ni.
Ikanni Global military information sọ pe Naijiria lo ni ọmogun oju ofurufu to pọ julọ l'Afirika.
Gẹgẹ bi ikanni naa ṣe ṣalaye, Naijiria ni ọmogun to to 230,000, bakan naa ni Naijiria tun ni ọmogun to pọ lati koju awọn agbesunmọmi.
$3.16bn ni owo ti ijọba Naijiria ti na lọdun yii sori eto aabo nikan.
South Africa
South Africa ni orilẹede Afirika to ṣe ipo kẹrin ninu awọn orilẹede to nawo lori eto abo julọ.
Ileeṣẹ ologun South Africa gbaju gbaja fun agbara ọmogun oriilẹ, oju omi ati ọmogun ofurufu wọn.
Ileeṣẹ ologun South Africa ni baalu ijagun eyi ti wọn maa n lo lati koju awọn ọta loorekoore.
South Africa ni awọn akọṣẹmọṣẹ to mọ nnkan ijagun igbalode lo daadaa.
Ikanni Global military information sọ pe ko din ni $3.1bn ti South Africa na lori eto aabo lọdun 2025 yii.
Ethiopia
Ọmogun oriilẹ lo pọju ninu awọn ọmogun orilẹede Ethiopia.
Ileeṣẹ ologun Ethiopia lagbara gan an lori ilẹ, lori omi ati loju ofurufu.
Ileeṣẹ ologun Ethiopia tun maa n ṣọ awọn ibode orilẹede naa daadaa.
Ikanni Global military information fidi rẹ mulẹ pe ko din ni $2.10bn ti Ethiopia na lori eto aabo lọdun 2025 yii.
Angola
Orilẹede Angola naa wa lara awọn orilẹede Afirika to ti nawo gọbọi lori eto aabo lọdun 2025 yii.
Ileeṣẹ ologun oju omi ati ti ofurufu Angola naa lagbara gidi.
Awọn ọmogun Angola maa n ṣọ awọn ibode orilẹede naa daadaa.
$1.1bn ni owo ti orilẹede Angola ti na lori eto aabo lọdun 2025 yii.
Morocco
Orilẹede Morocco ni ọmogun oriilẹ to pọ gan an, bakan naa ni wọn tun ni oniruuru ọkọ ijagun.
Ọmogun oju omi ati ofurufu orilẹede Morocco naa lagbara gan an.
Owo gọbọi ni ikanni Global military information sọ pe Morocco ti na lori ẹka eto aabo lọdun yii.
DR Congo
Orilẹede DR Congo ni orilẹede Afirika to wa ni ipo kẹjọ ninu awọn orilẹede to nawo gọbọi lori eto abo.
DR Congo ni ọmogun to pọ ni toootọ amọ wọn o ni awọn irinṣẹ ijagun igbalode.
Owo ti ko din ni $800m ni iroyin sọ pe orilẹede naa na lori eto aabo ni ọdun 2025 yii.
Sudan
Orilẹede Sudan to n koju ogun abẹle lọwọ yii ti lo oriṣiiriṣii ọmogun lati pese aabo fun araalu.
Awọn ọmogun Sudan gbaju gbaja fun bi wọn ti jẹ akinkanju lori ilẹ, loju ofurufu ati lori omi.
Owo to to $342m ni ikanni Global military information sọ pe Sudan ti na lori eto aabo lọdun yii.
Libya
Orilẹede Libya lo wa ni ipo kẹwaa ninu awọn orilẹede ilẹ Afirika to nawo gọbọi lori eto aabo ni Afirika.
Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọmogun Libya n koju oniruuru ipenija lọwọ yii, Libya maa n saba ni ọmogun to n dantọ.















