Ààrẹ Tinubu bá ẹbí Ọgagun Uba táwọn agbébọn pa kẹ́dùn

Aarẹ Bola Tinubu ati Oloogbe Ọgagun Musa Uba

Oríṣun àwòrán, Presidency/ Amaq

Àkọlé àwòrán, Aarẹ Bola Tinubu ati Oloogbe Ọgagun Musa Uba
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Tinubu, ti ba ẹbi Ọgagun Musa Uba, tawọn agbebọn pa nipinlẹ Borno, kẹdun iṣẹlẹ naa.

Ẹ o ranti pe ṣaaju ni Aarẹ ti kọkọ fi idi iku ọga ṣọja to sun loju ija naa mulẹ ninu ikede kan.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ Aarẹ Tinubu, Bayo Onanuga, fi sita lọjọ Iṣẹgun lo ti kede pe Aarẹ ni iku Ọgagun Uba jọ oun loju gan-an, o si ka oun laya .

"Gẹgẹ bii Olori aabo orilẹede Naijiria, inu mi bajẹ pupọ pẹlu iku awọn ṣọja wa ti wọn ku soju ija.

"K'Ọlọrun rọ́ awọn ẹbi Ọgagun Musa Uba ati awọn ikọ̀ yoku naa loju."

Bẹẹ ni apa kan atẹjade naa wi.

Ninu atẹjade to wa lati ileeṣẹ ologun Naijiria ni wọn ti ṣalaye pe awọn agbebọn to pa Ọgagun Uba, dena de ikọ ologun ti ọga ṣoja naa lewaju rẹ ni.

Awọn aworan ati fọnran to fi diẹ lara iṣẹlẹ naa si gba ori ayelujara kan, ṣugbọn ikọ ologun ko ti i sọ nnkan kan nipa rẹ.

Taa ni Brigadier General Musa Uba, ọ̀gágun tí orúkọ rẹ̀ ń milẹ̀ tìtì lórí ayélujára?

Brigadier General Musa Uba

Oríṣun àwòrán, Amaq/X

Ọrọ nipa ọgagun kan, M Uba, to wa ni nipo Brigadier General ti bẹrẹ si n fa ori ayelujara ya bayii.

Eyii ko ṣẹyin iroyin kan to ni awọn ọmọ ẹgbẹ agbesunmọmi ISWAP ti ji gbe lasiko ikọlu kan.

Ṣaaju ni iroyin ti kọkọ ni o dari ẹka 25 Task Force Brigade lọ ibikan niluu Wajiroko, Azir Multe, to wa ni ijọba ibilẹ Damboa.

Lẹyin eyii ni awọn fidio kan bẹrẹ si n milẹ titi lori ayelujara lati ọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ ISWAP.

Bo tilẹ jẹ pe ISWAP n sọ pe akata awọn ni ọgagun naa, ko si ẹni to tii le sọ ibi to wa ni pato.

Taa ni Brigadier General M Uba

M Uba ni adari ẹka 25 Brigade ninu ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria.

Ipo ti ọgagun naa wa fi han pe o wọ ileeṣẹ ologun lẹyin to kawe gboye nile ẹkọ Nigerian Defense Academy (NDA) tabi nipasẹ eto igbanisiṣẹ Direct Short Service Commission (DSSC).

Iroyin kan sọ lọjọ karundinlogun, oṣu kọkanla ọdun yii pe ọwọ awọn agbesunmọmi ISWAP tẹ ọgagun ọhun ni Damboa, ipinlẹ Borno.

A gbọ pe abule Wajiroko ni iṣẹlẹ naa ti waye lasiko ti oun atawọn ologun n bọ lati ibi iṣẹ kan ti wọn lọ ṣe.

Ileeṣẹ ọmọ ogun fidi rẹ mulẹ pe ologun meji ati araalu meji ti wọn n ran ologun lọwọ lo padanu wọn ninu ikọlu naa amọ wọn ko darukọ awọn ti ọrọ kan.

Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, ko si ẹni to tii le sọ ibi ti Brigadier General Uba wa.

Amọ ti iroyin to n lọ ni igboro ba jẹ ootọ, o n tumọ si pe Uba ni ologun ti ipo rẹ ga julọ ni Naijiria to yoo ko sọwọ awọn agbesunmọmi.

Ki ni alaye ileeṣẹ ologun nipa ibi ti Brigadier General Uba wa?

Ọgagun Appolonia Anele to gbẹnusọ fun ileeṣẹ ologun Naijiria sọ ninu atẹjade kan pe loootọ ni ọgagun to di awati naa ko awọn ọmọ ogun kan jade ti awọn agbesunmọmi si kọlu wọn.

Wọn ni asiko ti awọn ologun naa lọ ṣiṣẹ kan ninu igbo Sambisa ni ikọlu ọhun waye.

Amọ wọn ni irọ ni pe awọn ọmọ ogun ISWAP ti ji ọgagun naa gbe to si wa ni akata wọn.

Wayi o, lẹyin ọjọ diẹ ti ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria sọrọ yii ni ISWAP gbe fidio kan jade ninu eyii ti wọn ti ṣafihan ọgagun Uba.