Níṣe ló dàbí kí n la gbohùngbohùn mọ́ Obasanjo lórí nígbà tó sọ̀rọ̀ níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí mi - Fayose

Oríṣun àwòrán, GettyImages/ Ayodele Fayose/Facebook
Ó jọ bí ẹni pé ohun tí Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí Nàìjíríà, Olusegun Obasanjo sọ níbi ètò ayẹyẹ ọjọ́ ìbí gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Ekiti, Ayodele Fayose kò ì tíì tán nínú rẹ̀.
Èyí kò ṣẹ̀yìn bí Fayose ṣe tún sọ níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe láìpẹ́ yìí pé níṣe ló dàbí kí òun gba gbohùngbohùn lọ́wọ́ Obasanjo níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí òun, kí òun sì là á mọ́ Obasanjo lórí bó ṣe ń sọ̀rọ̀ náà.
Fayose ní òun ti gbìyànjú láti parí aáwọ̀ pẹ̀lú Obasanjo ṣáájú ọjọ́ ayẹyẹ ọjọ́ ìbí karùndínláàádọ́rin tí òun ṣe náà.
Ó ní òun lo èèyàn kan gẹ́gẹ́ bí alárinnà láàárín àwọn méjéèjì ṣáájú ayẹyẹ náà.
"Obasanjo ló ṣẹ mí torí òun ló yọ mí nípò gẹ́gẹ́ bí gómìnà, tí ẹnikẹ́ni yóò bá tọrọ àforíjì, Obasanjo ló yẹ kó ṣe bẹ́ẹ̀ fún mi"
"Gbogbo àwọn ìfaǹfà tí a bá ti ní sẹ́yìn, kí a fi sẹ́yìn. Tí mo bá ṣẹ̀ ẹ́ tàbí tí o bá ṣẹ̀ mí, ẹ jẹ́ ka fi sẹ́yìn," Fayose sọ.
Ó ṣàlàyé pé òun kò pe Obasanjo síbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí òun láti fi tọrọ ìdáríjì lọ́wọ́ rẹ̀ nítorí òun kò ṣẹ Obasanjo.
Ó fi kun pé Obasanjo ló ṣẹ òun nítorí òun ló yọ òun nípò gẹ́gẹ́ bí gómìnà àti pé tí ẹnikẹ́ni yóò bá tọrọ àforíjì, Obasanjo ló yẹ kó tọrọ àforíjì lọ́wọ́ òun.
Fayose ní Obasanjo gba òun ní àlejò dáadáa nígbà tí òun ṣe àbẹ̀wò sí ilé rẹ̀, tó sì ṣèlérí pé òun máa wá síbi ayẹyẹ náà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ní ayẹyẹ míì ní orílẹ̀ èdè Rwanda.
Ó fi kun pé òun ṣe ètò owó $20,000 fún ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí náà láti wá síbi ayẹyẹ náà.
"Báwo ni èèyàn ṣe máa gba owó ẹni tí yóò sì tún máa wá sọ ìṣokúsọ nípa ẹni náà?" Fayose bèèrè.
Báwo ni èèyàn ṣe máa sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ sí ẹni tó ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún márùndínláàádọ́rin? - Fayose kọminú
Ó tẹ̀síwájú pé ìkùnsínú bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Obasanjo sọ pé òun ni òun fẹ́ sọ̀rọ̀ kẹ́yìn níbi ayẹyẹ náà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igbákejì ààrẹ ni àwọn ti ṣètò tẹ́lẹ̀ láti parí ayẹyẹ ọ̀hún.
Ó júwe àwọn ọ̀rọ̀ tí Obasanjo sọ níbi ayẹyẹ náà bíi pé ó mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ìkọlù sí òun ni.
"Báwo ni èèyàn ṣe máa sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ sí ẹni tó ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún márùndínláàádọ́rin?
"Inú bí mi gan ní àsìkò yẹn, ó dàbí ẹni pé kí n gba gbohùngbohùn lọ́wọ́ rẹ̀, kí n là á mọ lórí ṣùgbọ́n mo gbà á mọ́ra nítorí igbákejì ààrẹ wà lórí ìjókòó."
Fayose fi kun pé òun fẹ́ kí ìbáṣepọ̀ tòótọ́ wáyé láàárín òun àti Obasanjo ṣùgbọ́n ìwà Obasanjo túmọ̀ sí pé kò fẹ́ kí àlááfíà wáyé.
"Tí mo bá mọ̀ pé bí ó ṣe máa parí nìyẹn, kí ni mo nílò Obasanjo fún? Ṣé mo fẹ́ gbégbá ìbò ni?"
Kí ló fa gbas-gbos láàárín Fayose àti Obasanjo tí Fayose fi júwe Baba Iyabo bíi ọ̀sínwín?

Oríṣun àwòrán, people's Gazzet
O jọ bii pe ija tuntun ti bẹrẹ laarin Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Olusẹgun Obasanjo, ati gomina ipinlẹ Ekiti nigba kan ri, Ayodele Fayose.
Ija naa ko ṣẹyin awọn oko ọrọ kan to jabọ lati ẹnu Obasanjo si Fayose nibi ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ to waye niluu Eko lopin ọsẹ.
Ko pẹ ti ọrọ Obasanjo bẹrẹ si n fa ori ayelujra ya ti Fayose naa da esi pada fun Obasanjo eyii to fi han pe oun kii ṣe ọmọ lọ ile lọ gba esi wa.
Bi Gbas-gbos naa ṣe bẹrẹ
Gbas-gbos Aarẹ tẹlẹ ati gomina tẹlẹ naa bẹrẹ lopin ọsẹ nibi ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun marunlelọgọta Fayose.
Nibi ayẹyẹ naa to waye niluu Eko ni wọn ti fun Obasanjo lanfani lati sọrọ to si jade lati ṣe bẹẹ.
Lara awọn ọrọ ti Obasanjo sọ si Fayose loju awọn mọlẹbi, ọrẹ, iyawo atawọn alejo to wa nibi ayẹyẹ naa ni ko dun mọ Fayose ninu.
Gẹgẹ bii ohun ti Obsan sọ nibẹ, Fayose funra rẹ lo fi iwe pe Aarẹ tẹlẹ sibi ayẹyẹ ọhun, koda, oun naa lo tun fi owo baalu rẹ lati ilu Kigali, lorilẹede Rwanda ranṣẹ.
Ki ni Obasanjo sọ ni pato to bi Fayose ninu?

Oríṣun àwòrán, Fayose/Obasanjo
Nigba to n sọrọ nibi eto naa ni Obasanjo ti kọkọ ni Fayose ti rin oun fi ni aimoye igba lai yipada.
O ni bo tilẹ jẹ pe o maa n tọrọ aforijin lọwọ nigba mii ko dẹkun ati maa sọrọ abuku si oun.
Obasanjo tẹsiwaju pe Fayose ko to ẹni to n pe oun sibi ayẹyẹ naa amọ o ran minisita nigba kan ri, Osita Chidoka, lati ṣe alarena laarin wọn ti oun si sọ fun pe oun ko ni fi owo ifẹyinti oun gbe baalu lati Kigali wa si Naijiria fun ayẹyẹ naa ki Fayose to fi owo ranṣẹ.
Obasanjo ni "Awọn kan pe mi pe 'agbọ pe ẹ fẹ lọ sibi ayẹyẹ ọjọ ibi Fayose, ṣe ẹ ti gbagbe pe o maa n tabuku yin nigba kan ri ni?' Ṣugbọn mo ni ki wọn ma ṣeyọnu pe ọkan lara awọn ọmọ mi naa ni.
"Ṣugbọn mi o fẹ ki a gbagbe ẹkọ ohun to ti waye laarin emi ati iwọ latẹyinwa, o gbọdọ kọ ẹkọ nla lati ara awọn iṣẹlẹ naa.
Baba Iyabo tun mẹnuba bo ṣe gba Fayose nimọran lodi si didokoowo adiyẹ sinsin lasiko rẹ bii gomina amọ Fayose kọ jalẹ ti okoowo naa si lulẹ lẹyinorẹyin. Obasano juwe okoowo ọhun bii iwa jibiti.
Bo tilẹ jẹ pe ọpọ awọn to wa nibẹ lo n rẹrin ti Fayhose ati iyawo rẹ si duro niwaju Obasanjo tọwọtọwọ, pupọ ninu ọrọ ti Obasanjo sọ ku dun mọ Fayose ninu.
Ki ni esi Fayose?
Lẹyin ayẹyẹ naa ti ọrọ Obasanjo bẹrẹ si n fa ori ayelujra ya ni Fayose da esi pada fun Obasanjo pẹlu ọrọ abuku mii.
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Abeokuta, agbẹnusọ Obasanjo, Kehinde Akinyemi ni Fayose ti fesi pada lori ọrọ ti Obsanjo sọ nibi ayẹyẹ re, eebu lo si fi ranṣẹ.
Gẹgẹ bii ọrọ Akinyemi, o ni Fayose dupẹ lọwọ Obasanjo fun bo ṣe yẹ oun si lati lati yọju sibi ayẹyẹ naa amọ o sọ awọn "ọrọ ti ko mu ọgbọn dani" nibẹ.
O ni Fayoṣe sọ pe oun yan lati ma fesi ni gbagede ayẹyẹ ọhun "ki gbogbo aye le mọ iyatọ laarin ọkunrin ti ori rẹ pe ati ọkunrin to n sinwin."
O ni Fayose tun ti rọ Obasanjo ko da owo ti oun fi ranṣẹ si pada, o tun fidi rẹ mulẹ pe Obasanjo ti da owo ọhun pada lai fọwọ kan an.















