Àlàyé rèé lórí bí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ tó fa aáwọ láàárín Wike àti ọmọ ológun ṣe jẹ́

Oríṣun àwòrán, Collage
Láti ìgbà tí ìfaǹfà ti wáyé láàárín mínísítà fọ́rọ̀ ìlú Abuja, Nyesom Wike àtàwọn ọmọ ogun kan ní ìlú Abuja.
Ilẹ̀ kan tí wọ́n ní ọ̀gá àgbà tẹ́lẹ̀ rí fún iléeṣẹ́ ológun orí omi, Vice Admiral Awwal ló ni í ló ṣokùnfà ìfaǹfà náà.
Agbẹnusọ fún Nyesom Wike, Lere Olayinka ti wá ṣàlàyé ohun tó ṣokùnfà ìfaǹfà náà.
Olayinka nígbà tó ń kópa lórí ètò iléeṣẹ́ Channels Television, Sunrise Daily sọ pé àwọn èèyàn kan ló lu ọ̀gá ológun tẹ́lẹ̀ rí náà ní jìbìtì lórí ilẹ̀ náà ṣùgbọ́n kàkà kó bèèrè ìrànlọ́wọ́, níṣe ló gbìyànjú láti lo àwọn ológun.
"Iléeṣẹ́ tó ta ilẹ̀ fún ọ̀gá ológun lù ú ní jìbìtì ni, tí òun náà sì mọ̀ pé wọ́n lu òun ní jìbìtì ni"
Ó ṣàlàyé pé iléeṣẹ́ kan ni wọ́n ta ilẹ̀ náà fún tẹ́lẹ̀, kí iléeṣẹ́ náà tó gbìyànjú láti máa ṣòwò lódì sí nǹkan tó rà á fún.
"Ní ọdún 2007 ni wọ́n wọn ilẹ̀ náà fún iléeṣẹ́ Santos Estate Limited láti fi kọ́ ibùdó ìgbafẹ́. Iléeṣẹ́ náà kò kọ́ nǹkankan sórí ilẹ̀ náà nítorí ojú ọ̀nà ni, ẹ ò lè kọ́lé síbẹ̀.
"Lọ́dún 2022 ni iléeṣẹ́ náà kọ̀wé sí iléeṣẹ́ tó ń rí sí ìdàgbàsókè ìlú Abuja FCTDA pé àwọn fẹ́ yí ìlò ilẹ̀ náà padà fún ohun tó le pawó wọlé ṣùgbọ́n tí wọn dúró de ìbuwọ́lù mínísítà kí wan tó máa tà á fáwọn èèyàn.
"Lára àwọn tí wọ́n ta ilẹ̀ náà fún ni ọ̀gá àgbà tẹ́lẹ̀ rí fún iléeṣẹ́ ológun orí omi."
Olayinka ní àwọn iléeṣẹ́ náà lu ọ̀gágun náà ní jìbìtì ni, tí òun náà sì mọ̀ pé wọ́n lu òun ní jìbìtì ni.
ṣṢùgbọ́n kàkà kó bèèrè fún ìrànlọ́wọ́ níṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí ní lo àwọn ọmọ ogun láti fi dúnkokò mọ́ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ wọn.
Bí Wike ṣe wọ́ ọmogun nílẹ̀ tàbùkù àṣẹ́ iṣẹ́ ológun, à gbé òṣùbá fún Yerima bó ṣe hùwà akin pẹ̀lú Mínísítà - Àwọn ọ̀gá ológun fọ́nmú

Oríṣun àwòrán, Screenshot/Facebook Screengrab
Awọn ajagunfẹyinti onipo agba ti a mọ si Jẹnẹra, ti fi aidunnu wọn han si aawọ to waye laaarin minisita ilẹ Abuja, Nyesom Wike ati ọmọ ogun, A. M Yerima, lori ọrọ ilẹ kan niluu Abuja, lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii.
Ninu ifọrọwerọ ọtọọtọ ti iwe iroyin 'The Punch' ṣe fun awọn ọga ologun naa l'Ọjọru ana ni wọn ti ni bi Wike ṣe ko oju ọmọ ogun naa tabuku aṣẹ iṣẹ ologun.
Koda, Minisita fun idaboobo lorilẹede yii, Mohammed Badaru, sọ pe ileeṣẹ ologun yoo maa da aabo bo awọn ologun to ba n tẹle aṣẹ iṣẹ to ba ofin mu.
O ni ẹka to n ri si idaboobo ti bẹrẹ iwadii lori ohun to ṣẹlẹ naa.
Minisita fun idaboobo gboriyin fun ṣọja Yerima, nipa bo ṣe huwa lasiko ti aigbọra ẹni ye ọhun bẹ silẹ laaarin rẹ ati Nyesom Wike.
Nigba to n sọrọ l'Abuja nibi eto iranti awọn ologun to ti sun loju ija, eyi ti wọn n palẹ rẹ mọ fun ti ọdun 2026 (Armed Forces Remembrance Day 2026), minisita naa sọ pe :
"Gẹgẹ bi ẹka ileeṣẹ, ati bii ileeṣẹ ologun, ni gbogbo igba ni a o maa da aabo bo awọn ologun wa lẹnu iṣẹ to ba ofin mu ti wọn ba n ṣe.''
"A ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa, a si fi n da yin loju pe ologun yowu to ba n ṣiṣẹ ti wọn gbe le e lọwọ lọna to ba ofin mu yoo maa ri aabo to lagbara gba.
"A ko ni i jẹ ki nnkan kan ṣe e , niwọn igba to ba ti jẹ pe iṣẹ rẹ lo n ṣe, o si n ṣe e daadaa."
Aawọ to waye laaarin Minisita Wike ati ṣọja ọmọ ogun oju omi kekere yẹn kọja iru eeyan ti wọn jẹ -Ajagunfẹyinti Peter Aro
Ninu ọrọ tirẹ, Ajagunfẹyinti( Brig Gen) Peter Aro, sọ pe yẹpẹrẹ kọ ni eku asin to ba di ti ka fi ọ̀wọ̀ to tọ fun iṣẹ ologun.
O ni aawọ to waye naa fi bo ṣe yẹ ki ibọwọ wa fun ẹka to yẹ, ninu ijọba Dẹmokresi han.
" Aawọ to waye laaarin Minisita Wike ati ṣọja ọmọ ogun oju omi kekere yẹn kọja iru eeyan ti wọn jẹ. O fi bo ṣe yẹ ka lo agbara ati bi ko ṣe yẹ ka lo o ninu ijọba Demokresi han ni.
"Ologun yẹn, ni gbogbo ọna, n ṣiṣẹ ti ọga rẹ pa a laṣẹ lati ṣe ni; ojuṣe rẹ ni lati tẹle aṣẹ iṣẹ rẹ bo ṣe wa, ki i ṣe ko maa da ọgbọn kan nitori girigiri oloṣelu.''
Ajagunfẹyinti Aro sọ pe loootọ ni Wike ni ẹtọ lati beere ohun ti ko ba ye e lori ilẹ naa, ṣugbọn ọna to gbe e gba ko daa.
O ni bi Wike ba kọwe si minisita eto idaboobo, tabi olori awọn ọmọ ogun alaabo, tabi ko tiẹ lọ sile ẹjọ, o daa ju bo ṣe sọ ẹka ijọba apapọ di nnkan yẹpẹrẹ loju aye lọ.
Bẹẹ ni Ajagunfẹyinti Peter Aro wi.
Tẹ o ba gbagbe, ṣaaju ni olori ologun tẹlẹ, Lt. Gen. Tukur Buratai, naa ti ni afi ki Wike tọrọ aforiji nita gbangba lọwọ Aarẹ Bola Tinubu, ileeṣẹ ologun ati ṣọja ti wọn ja tahun sira wọn naa.
Buratai sọ pe iwa ti Wike hu ko tọ, o si tumọ si aibọwọ fun ileeṣẹ ologun.
Mi o tiẹ lero pe minisita kan le huwa bẹẹ yẹn si ṣọja to n ṣiṣẹ rẹ-Ajagunfẹyinti Bashir Adewinbi
Bakan naa ni Ajagunfẹyinti Bashir Adewinbi, ṣalaye pe oun ko tilẹ lero pe minisita kan le wu iru iwa ti Wike wu.
" Mi o tiẹ lero pe minisita kan le huwa bẹẹ yẹn si ṣọja to n ṣiṣẹ rẹ. ileeṣẹ ologun ki i ṣe ileeṣẹ lasan, labẹ aṣẹ olori orilẹede lo wa.
"Gbogbo idojukọ ologun kan, tumọ si didojukọ aarẹ ni, ko si yẹ ki iru rẹ jẹ itẹwọgba."
Bẹẹ ni Ajagunfẹyinti Bashir Adewinbi pẹlu ṣalaye.
Latigba ti ọrọ yii ti ṣẹlẹ ni ero awọn eeyan ti n ṣe ọtọọtọ lori rẹ, bawọn kan ṣe n sọ pe ṣọja lo jẹbi ni awọn kan n sọ pe Wike lo ya alaṣeju.
Ohun ti iwadii ileeṣẹ ologun yoo bi lori rẹ, ati awọn igbesẹ miran to n lọ ni ọpọ eeyan n reti.
Wo kókó ohun tó yẹ kó o mọ nípa Yerima, ológun tó gbéná wojú Wike àti ọ̀gá rẹ̀ tó ní ilẹ̀ tó fa aáwọ, Awwal Zubairu Gambo

Oríṣun àwòrán, Collage
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ Isegun ni ariwo ta nípa iporogan to wáyé láàárín Mínísítà fún olú ìlú ilẹ̀ wa, Nyesom Wike àti ọmọ ológun ojú omi kan, A.M Yerima.
Aáwọ̀ náà ló dá lórí ọ̀rọ̀ ilẹ̀, ilé àti bó ṣe tako òfin idagbasoke ìlú Abuja.
Bí àwọn méjèèjì ṣe tahun síra wọn lo tí ń fa awuyewuye yika Naijiria, tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì fẹ́ mọ̀ irú èèyàn tó ní ilẹ̀ náà àti ọ̀gá ológun tó rán an nisẹ.
BBC News Yorùbá wa ṣe àkójọpọ̀ àwọn kókó to yẹ kí ẹ mọ̀ nípa Yerima àti ọ̀gá rẹ̀ lẹ́nu isẹ ológun to ni ilẹ to fa aáwọ náà, Awwal Subairu Gambo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ta ni Awwal Zubairu Gambo?
Ní oṣù Kìíní, ọdún 2021 ni wọ́n yan ọ̀gágun Awwal Zubairu Gambo gẹ́gẹ́ bí olórí iléeṣẹ́ ológun orí kọkànlélógún Nàìjíríà lẹ́yìn tó ti ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ológun fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún.
Ní ọjọ́ Kejìlélógún, oṣù Kẹrin, ọdún 1966 ni wọ́n bi ní ìjọba ìbílẹ̀ Nasarawa ìpínlẹ̀ Kano.
Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Gwagwarwa Special Primary School ní ìpínlẹ̀ Kano, tó sì tún lọ sí ilé ẹ̀kọ́ girama Rumfa College níbi tó ti jáde ìwé mẹ́wàá.
Ní ọjọ́ Kẹrìnlélógún, oṣù Kẹsàn-án, ọdún 1984 ni Gambo wọ ilé ẹ̀kọ́ Nigeraian Defence Academy fún ìkẹ́kọ̀ọ́ 36 Regular Course.
Ọjọ́ Kẹrìnlélógún, oṣù Kẹwàá, ọdún 1989 ló di Sub-Lieutenant.
Onírúurú ipò tó ṣe kókó ni Gambo dì mú ní iléeṣẹ́ ọmọ ogun orí omi àti oríko iléeṣẹ́ ààbò Nàìjíríà.
Lábẹ́ ìṣèjọba ààrẹ àná, Muhammadu Buhari ló ṣe ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ológun orí omi láàárín oṣù Kìíní ọdún 2021 sí oṣù Kẹfà, ọdún 2023.
Láàárín ọdún 2018 sí oṣù Kìíní ọdún 2021ló ṣe adarí ẹ̀ka Procurement ní Defence Space Administration.
Láàárín ọdún 2017 sí 2018 ló ṣe olórí òṣìṣẹ́ ní ilé ẹ̀kọ́ olùkọ́ni Naval Training Command tó wà ní ìpínlẹ̀ Eko.
Ọdún 2017, ó dipò alákòso ètò ààbò fún ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ohun ìbojú àánú woni ti iléeṣẹ́ ààrẹ fún ìlà oòrùn Nàìjíríà àti adarí ẹ̀ka tó ń rí sí ìwádìí ní iléeṣẹ́ ètò ààbò ti ìlú Abuja.
Láàárín ọdún 2015 sí 2017 ló ṣe adarí ẹ̀ka Simulation ní Naval Doctrine àti Assessment Centre, Bonny Camp ìpínlẹ̀ Eko.
Ọdún 2009 ló kẹ́kọ̀ọ́ gboyè onípò kejì lẹ́ka ìmọ̀ ètò ìrìnnà ní ilé ẹ̀kọ́ Ladoke Akintola University of Technology, LAUTECH.
Ta ni AM Yerima, ológun ojú omi tó gbéná woju Nyesom Wike?
Láti ìgbà tí fídíò tó ṣàfihàn bí ọmọ ogun AM Yerima àti Wike ti gba orí ayélujára ni àwọn èèyàn ti ń kan sáárá síi fún bí ó ṣe dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú bí ìfaǹfà ṣe lágbára tó.
Ogúnjọ́, oṣù Keje, ọdún 1992 ni wọ́n bí Yerima ní ìpínlẹ̀ Kaduna gẹ́gẹ́ bí bó ṣe wà lójú òpó Profile Legacy àti Scovuesta.
Ipò Lieutenant ló dì mú nínú iṣẹ́ ológun orí omi.
Ní ilé ẹ̀kọ́ Ahmadu Bello University ló ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ kó tó darapọ̀ mọ́ iléeṣẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ ológun, Nigerian Defence Academy, NDA, Kaduna.

Oríṣun àwòrán, Lere Olayinka/Facebook
Kí ló ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?
Ẹ ó rántí pé ní ọ̀sán ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni fídíò kan gba orí ayélujára èyí tó fa awuyewuye láàárín àwọn ọmọ Nàìjíríà.
Nínú fídíò náà ni mínísítà fun olú ìlú orílẹ̀ èdè yìí, Nyesom Wike àti ọmọ ogun ojú omi kan ti ń tahùn síra wọn.
Ohun tó jọ ni pé ọ̀rọ̀ ilẹ̀ kan ló ṣokùnfà àìgbọ́ra ẹni yé tó wáyé láàárín mínísítà àti ọmọ ogun náà.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló wáyé nígbà tí Wike àtàwọn òṣìṣẹ́ ìjọba fẹ́ wọ orí ilẹ̀ kan ṣùgbọ́n tí ọmọ ogun náà dáwọn dúró wí pé wọn kò lè wọ ibẹ̀.
Wike, ẹni tó ń bínú nínú fídíò náà ń bèèrè lọ́wọ́ ọmọ ogun náà pé ìwé àṣẹ wo ló ní tí wọ́n fi wà lórí ilẹ̀ náà tàbí láti fẹ́ ṣiṣẹ́ le lórí?
Amọ tí ọmọ ogun náà kò kúrò níwájú rẹ̀, tó sì ń da lóhùn àwọn ìbéèrè rẹ̀.
Mínísítà náà bèèrè pé kí ọmọ ogun náà ṣàfihàn ìwé ilẹ̀ tó wà lọ́wọ́ wọn, tí wọ́n fi ń dá ààbò bo ilẹ̀ náà.
Ìwé tí wọ́n fún-un yín láti fi ṣiṣẹ́ lórí ilẹ̀ yìí dà, báwo ni ọkùnrin náà pẹ̀lú ipò tó wà, tí kò ní ìṣòro kankan, kí ó kọ̀wé láti rí àwọn nǹkan tí mo ní, àmọ́ àwọn ọmọ ogun ló kó wá láti fi halẹ̀ mọ́ ta a ni?"
Ṣùgbọ́n ọmọ ogun náà fún Wike lésì pé níṣe ni òun ń tẹ̀lé àṣẹ tí wọ́n fún òun.















