Ilé ẹ̀jọ́ gíga kò lágbára láti dá ẹjọ́ mi lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀, yóò dáa kò jáwọ̀ nínú rẹ̀ - Nnamdi Kanu

Adari ẹgbẹ awọn ajijagbara Biafra, Nnamdi Kanu ti ke si ile ẹjọ giga to n gbọ ẹjọ rẹ niluu Abuja pe ko wọgile idajọ to n mura lati ṣe fun oun logunjọ oṣu yii.
Kanu lo sọ bẹẹ ninu iwe kan to fi ṣọwọ si adajọ James Omotosho ninu eyii to ti sọ pe ko si ofin to kin ẹjọ ti ijọba n ba oun ṣe lẹyin.
Aipẹ yii ni Kanu le gbogbo awọn agbẹjọro rẹ, ti adajọ agba Naijiria tẹlẹ, Kanu Agabi (SAN), jẹ adari wọn, to si sọ pe oun funra oun ni yoo maa ṣoju ara oun niwaju adajọ.
Ninu ariyanjiyan Kanu, o ni ofin ti wọn fi pe oun lẹjọ to jẹ ofin didena iwa igbesunmọmi ti ọdun 2013 tako abala ofin 1(3), 36(1)–(12) ati 42 ti ọdun 1999 ati ofin to sọrọ nipa ẹtọ araalu ni Afrika, African Charter on Human and Peoples' Rights.
O ni ile ẹjọ naa gbọdọ gba pe ẹsun karundinlogun ti wọn fi kan oun (to ti di ẹsun keje bayii) ko si ninu iwe ofin Naijiria mọ.
Kanu tẹsiwaju pe ti wọn ba tẹle abala 76(1)(a)(iii) ofin to n dena iwa igbesunmọmi ti ọdun 2022, o n tumọ si pe ile ẹjọ giga naa ko lagbara lati ṣe ẹjọ oun lai ni ẹri nitori oun ti wọn pe oun lẹjọ le lori jẹ ẹṣẹ labẹ ofin orilẹede Kenya ti wọn ti gbe oun lọna ti ko tọ.
Lẹyin to jawe ẹ lọ gbele yin fun awọn agbẹọro rẹ, olori ẹgbẹ Biafra naa sọ pe wọn tan oun lati bẹbẹ labẹ ofin ti ko ni akọsilẹ kankan eyii to tako abala 220 ofin ACJA ti ọdun 2015.
Ẹsun meje ọtọtọ ni ijọba apapọ fi kan Kanu, ẹsun naa lo rọ mọ igbesunmọmi to ni nọmba FHC/ABJ/CR/383/2015 niwaju adajọ James Omotoso.
Ijọba fẹsun kan Kanu pe oun lo n lewaju ẹgbẹ to fẹ ko awọn ipinlẹ kan ni ila oorun ati lara ipinlẹ Kogi ati Benue kuro lara Naijiria.
Awọn ọmọ Igbo kilọ lori idajọ Kanu to n bọ lọna
Ẹgbẹ awọn ọmọ Igbo kan niluu Abuja, Igbo Community Association, ti kilọ pe idajọ Nnamdi Kanu ti yoo waye logunjọ oṣu yii le da rugudu silẹ ni Naijiria.
Aarẹ ẹgbẹ naa, Ikenna Ezenekwe, sọ ninu atẹjade kan pe ki ile ẹjọ to fẹ ṣedajọ naa ṣọra nitori Kanu ko tii sọrọ gbe ara rẹ lẹyin nile ẹjọ ọhum ko si yẹ ki idajọ waye lai jẹ pe o ṣe bẹẹ.
Ezenekwe sọ pe ko tọ ki idajọ afurasi naa waye lai jẹ ki oun funra rẹ lanfani lati sọ tẹnu rẹ nile ẹjo naa.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, ọna ti ko ba ofin mu ni ijoba Naijiria fi ji Kanu gbe kuro lorilẹede Kenya wa si Naijiria lati bẹrẹ ẹjọ naa.
O ni wọn fi Kanu si atimọle fun odidi ọdun mẹrin gbako nigba ti ile ẹjọ kankan ko tii sọ pe o jẹbi ẹsun kankan.
Lẹyin naa lo rọ Aarẹ Bola Tinubu ko wo ọna mii ti yoo fi tu Kanu silẹ, o tun rọ adajọ Omotoso lati fi ọgbọn wo igbẹjọ naa latari orukọ tuntun ti Aarẹ Donald Trump ti Amẹrika ṣẹṣẹ sọ Naijiria.
O pari ọrọ rẹ pe ki wọn tu kanu silẹ ki gudugbeẹ nla ma baa ja ni Naijiria lẹyin idajọ Kanu.















