Àlàyé lórí bí ọ̀kan nínú Naijiria, Cameroon, DR Congo àti Gabon láti Afirika yóò ṣe yege fún play-off ẹlẹ́kùn-jẹkùn àgbáyé ti 2026 World Cup

Agbabọọlu iwaju DR Congo, Chancel Mbemba, aṣọle Cameroon, Andre Onana, Ẹlẹsẹ ayo Naijiria, Victor Osimhen ati ẹlẹsẹ ayo Gabon, Pierre-Emerick Aubameyang

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ẹgbẹ agbabọọlu kan ninu DR Congo, Cameroon, Nigeria ati Gabon ni yoo lanfaani ifẹsẹwọnsẹ ẹlẹkun-jẹkun lagbaaye lati pegede fun idije 2026 Fifa World Cup
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ẹgbẹ agbabọọlu kan ninu awọn mẹrin ti yoo koju ara wọn lọsẹ yii ni yoo lanfaani lati pegede fun ipele to kẹyin lati pegede fun idije ife ẹyẹ agbaye 2026 World Cup.

Lẹyin ti wọn kuna lati pedege fun idije 2026 World Cup lati ilẹ Afririka, Cameroon, DR Congo, Gabon ati Naijiria yoo maa waako lorilẹede Mococco lati Ọjọbọ ọsẹ yii lati mọ ikọ agbabọọlu kan ti yoo lọ ṣoju Afirika ninu idije ati pegede fun idije ife ẹyẹ agbaye ọdun to n bọ.

Ikọ agbabọọlu to ba pegede laarin awọn mẹrẹẹrin yoo tun koju ikọ agbabọọlu kan tabi meji si i lati pegede fun idije 2026 World Cup.

BBC ṣalaye bi ikọ agbabọọlu ti yoo lọ ṣoju Afirika ninu ifẹsẹwọnsẹ ẹlẹkun jẹkun kaakiri agbaye nibi ti ẹgbẹ agbabọọlu ti yoo pegede fun 2026 World Cup yoo ti jade sita.

Bi Cameroon, DR Congo, Gabon ati Naijiria ṣe de ipele play-offs Afirika

Awọn ẹgbẹ agbabọọlu mẹrẹẹrin yii, Cameroon, DR Congo, Gabon ati Naijiria, pegede fun idije play-off lẹyin ti gbogbo wọn ṣe ipo keji ni isọri onikalaku wọn.

Ajọ FIFA ati CAF ko abajade ifẹsẹwọnsẹ pẹlu awọn ikọ agbabọọlu to ṣe ipo kẹfa ni isọri mẹjọ ti wọn pin awọn ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ Afirika si, nitori Eritrea yọwọ kuro ninu ninu idije ati pegede fun idije ere bọọlu agbaye ọdun 2026 nigba to ku ọjọ kan ki idije naa bẹrẹ.

Gabon lo ṣe daadaa julọ, lẹyin naa ni DR Congo ati Cameroon.

Ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles Naijiria gan an rapala wọ ipele play-off ni lẹyin ti wọn lu Benin pẹlu ami ayo mẹrim sodo.

Bawo ni wọn ti pin isọri play-off Afirika?

Ipo awọn ẹgbẹ agbabọọlu mẹrin lori atẹ iwọn FIFA ni wọn lo lati ṣe agbekalẹ ifẹsẹwọnsẹ play-off Afirika yii.

Awọn ikọ agbabọọlu meji ti wọn gbewọn daadaa yoo koju meji ti ko gbewọn to wọn lori atẹ iwọn FIFA.

Ipo 41 ni Naijiria wa lori atẹ iwọn FIFA nigba ti Gabon ti wọn yoo koju lỌjọbọ wa nipo 77.

Cameroon wa nipo 54 nigba ti DR Congo ti wọn yoo jọ waako wa nipo 60.

Awọn meji to ba bori ninu ifẹsẹwọnsẹ mejeeji yii yoo koju ara wọn lọjọ Aiku ọsẹ to n bọ.

Niluu Rabat lorilẹede Morocco ni ifẹsẹwọnsẹ mẹtẹẹta naa yoo ti waye.

Ki ni yoo ṣẹlẹ sawọn to ba bori?

Agbabọọlu New Caledonia, Joris Kenon ati agbabọọlu Bolivia's Enzo Monteiro

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, New Caledonia ati Bolivia wa lara awọn agbabọọlu ti ẹgbẹ agbabọọlu to ba bori idije play-offs Afirika le koju

Ikọ agbabọọlu to ba gba ipo kinni ninu idije play-off Afirika ni yoo lọ kopa ninu idije ati pegede fun idije 2026 World Cup ẹlẹni mẹfa eyi ti yoo waye loṣu Kẹta ọdun to n bọ.

Meji ninu ikọ agbabọọlu mẹfa yii ni yoo pegede fun idije ife ẹyẹ agbaye 2026 World Cup.

Ẹgbẹ agbabọọlu meji ni yoo wa lati ajọ Concacaf, ọkan ni yoo wa lati ẹkun Aṣia, ọkan lati Oceania ati ọkan lati South America.

Isọri meji ni wọn yoo pin awọn ikọ agbabọọlu mẹfa si i.

Ẹgbẹ agbabọọlu wo lawọn to ba pegede nibi idije play-off yoo koju ninu idije ife ẹyẹ agbaye?

Ọjọ karun un ọjọ Ẹti oṣu Kejila ọdun yii ni FIFA yoo pin ikọ agbabọọlu 48 si isọri mejila.

Ikọ agbabọọlu 42 ni FIFA yoo le pin lọjọ karun un oṣu Kejila naa,

Ẹgbẹ agbabọọlu meji lati idije play-off ẹlẹkun-jẹkun kaakiri agbaye ati ikọ agbabọọlu mẹrin ti yoo pegede lati idije play-off ilẹ Yuroopu ni FIFA ko ni tii le pin loṣu Kejila to n bọ yii.

Nitori naa, ikọ agbabọọlu to ba bori ninu idije play-off Afirika le mọ awọn ẹgbẹ agbabọọlu ti wọn yoo koju ninu idije ife ẹyẹ agbaye 2026 World Cup.

Ẹgbẹ agbabọọlu wo lo le bori ninu idije play-off Afirika?


Akọnimọọgba Naijiria, Eric Chelle, wọ aṣọ dudu alapa gigun to ni ami idanimọ ajọ NFF ti n ṣakoso ere bọọlu ni Naijiria lara.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Oju wa lara akọnimọọgba Naijiria, Eric Chelle lati ri pe Super Eagles pegede fun 2026 World Cup

Ikọ agbabọọlu Super Eagles Naijiria lo gbewọn julọ lori atẹ iwọn FIFA laarin ẹgbẹ agbẹgbọọlu mẹrin ti yoo kopa ninu idije play-off Afirika.

Amọ, ami ayo mẹrin pere ni Super Eagles rigba ninu mẹẹdogun ninu ifẹsẹwọnsẹ marun un to ti yẹ ki wọn ri ami ayo mẹẹdogun gba.

Cameroon ni ẹgbẹ ẹgbẹ agbabọọlu mii to gbọrọgẹjigẹ ṣugbọn awọn naa ko fakọyọ ninu awọn idije ati pegede fun idije 2026 World Cup ti wọn gba.

Ami ayo mẹri ọtọọtọ ni Cape Verde fi ṣaaju wọn gba ipo kinni ni isọri D.

Nitori naa, o ṣoro lati sọ ikọ agbabọọlu ti yoo bori idije play-off Afirika ọsẹ yii ni Morocco.

Ẹlẹsẹ ayo DR Congo Yoane Wissa wọ jẹsi olomi aro to tun ni awọ pupa ati olomi ọsan lara

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ẹlẹsẹ ayo DR Congo Yoane Wissa ko ni le kopa ninu idije play-offs Afirika

Ọdun 1974 ni DR Congo ti kopa ninu idije World Cup kẹyin.

Zaire ni orukọ ti orilẹede ọhun n jẹ nigba naa.

DR Congo lo ṣe ipo keji ni isọri B lẹyin Senegal to ṣe ipo kinni ni isọri naa.

Ẹwẹ, ẹlẹsẹ ayo DR Congo, Yoane Wissa, ko ni kopa ninu idije play-off yii tori o fi ẹsẹ ṣeṣe.

Gabon ni wọn fẹ kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye fun igba akọkọ.

Ami ayo kan ṣoṣo ni Ivory Coast to ṣe ipo kinni ni isọri F fi ṣiwaju wọn.

Denis Bouanga ati Pierre-Emerick Aubameyang ni awọn ẹlẹsẹ ayo meji to le fakọyọ fun Gabon ninu idije play-off yii.