Ìjọba UK kìlọ̀ fáwọn èèyàn rẹ̀ nípa ìpínlẹ̀ ogún tí ààbò ti mẹ́hẹ ni Nàìjíríà

Àsíá ilẹ̀ UK

Oríṣun àwòrán, Gov . UK

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti ṣèkìlọ̀ lórí ṣíṣe ìrìnàjò lọ sáwọn ìpínlẹ̀ kan ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Àjọ Foreign, Commonwealth, and Development Office ti United Kingdom lo kede bẹẹ.

Ninu àtẹ̀jáde kan tí wọ́n fi sójú òpó ayélujára wọn lọ́jọ́ Àìkú, wọn gbé ìkìlọ̀ tuntun síta pé àìsí ààbò tún ti ń peléke ní àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Wọ́n ní àwọn ìpínlẹ̀ náà ni àwọn ìwà ìjínigbé, ìgbéṣùmọ̀mí, àtàwọn ìwà ọ̀daràn míì tún ti ń peléke si, tí wọ́n sì ní gbogbo ẹkùn káàkiri Nàìjíríà ni àwọn ìwà ọ̀daràn náà ti ń wáyé.

Àtẹ̀jáde náà rọ àwọn ọmọ ilẹ̀ Britain tó wà ní Nàìjíríà láti ṣe jẹ́jẹ́, kí wọ́n mọ gbogbo ibi tí wọ́n ń rí sì, kí wọ́n sì ri dájú pé wọn gbọ́dọ̀ mọ àwọn ibi tí wọ́n bá ń lọ dáadáa.

"Gbogbo àwọn ìpínlẹ̀ tó wà lẹ́kùn Àríwá Nàìjíríà ni kò ní ààbò tó péye"

FCDO ní kí wọ́n yàgò ṣíṣe ìrìnàjò lọ sí àwọn ìpínlẹ̀ Borno, Yobe, Adamawa, Gombe, Katsina àti Zamfara nítorí ìkọlù àwọn agbéṣùmọ̀mí Boko Haram àti ISWAP.

Wọ́n ní káwọn èèyàn máa yẹra fún ibi tí àwọn èrò bá pọ̀ sí, ibùdókọ̀, àwọn ilé ìjọsìn àti ibi tí àwọn ayẹyẹ ńlá bá ti ń wáyé.

Wọ́n ṣàkìlọ̀ pé àwọn agbéṣùmọ̀mí náà le ṣèkọlù sáwọn àjọ tó ń ṣiṣẹ́ ìbojú àánú woni, tó fi mọ́ àwọn ọkọ̀ tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́.

Ìjọba UK náà sọ pé gbogbo àwọn ìpínlẹ̀ tó wà ní àríwá Nàìjíríà ni ó ṣòro fáwọn èèyàn láti máa ṣe ìrìnàjò lọ pàápàá àwọn ìpínlẹ̀ Kaduna, Kano, Kebbi, Jigawa, Sokoto, Niger, Kogi, Plataeu, Taraba, tó fi mọ́ àwọn agbègbè kan ní olú ìlú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Abuja.

Wọ́n fi kun pé ìwà ọ̀daràn, tó fi mọ́ gbígbe ohun ìjà olóró ló ń wáyé láwọn ìpínlẹ̀ náà àti pé ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn máa ń sábà wáyé ní Abuja.

"Lóòrè kóòrè ni wọ́n máa ń ṣe ìwọ́de ní Abuja èyí tó lè di wàhálà. Ẹ máa tẹ̀lé àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn abẹ́lé, ẹ yàgò fún àwọn ibi tí èrò bá pọ̀ sí, kí ẹ sì máa tẹ̀lé àṣẹ àwọn iléesẹ́ ààbò àti ọlọ́pàá.

Wọ́n fi kun pé ní ẹkùn ìlà oòrùn àríwá Nàìjíríà níbi tí iléeṣẹ́ ológun ti ń kojú àwọn agbéṣùmọ̀mí ní Adamawa, Borno àti Yobe tí àwọn agbéṣùmọ̀mí náà sì le kojú oro padà.

Awọn eeyan UK gbọ́dọ̀ ṣọ́ra láti ṣe àbẹ̀wò sáwọn agbegbe tó wà ní bèbè omi bíi Delta, Bayelsa, Rivers, Akwa Ibom àti Cross Rivers

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Wọ́n ní ó máa ṣòro fún àwọn tó wà ní ìlú Maiduguri láti kúrò níbẹ̀ tí ètò ààbò bá filè burú jù báyìí lọ níbẹ̀.

Ní ẹkùn ẹkùn ilà oòrùn gúúsù àti ààrin gbùngbùn gúúsù, FCDO ṣèkìlọ̀ pé kí àwọn èèyàn wọn má ṣe ìrìnàjò lọ sí àwọn ìpínlẹ̀ tó wà ní bèbè omi bíi Delta, Bayelsa, Rivers, Akwa Ibom àti Cross Rivers.

Wọ́n ní ìwà ìdigunjalè, ìwà ọ̀daràn àtàwọn ìjínigbé tó ń wáyé láwọn ẹkùn náà lágbára púpọ̀.

Bákan náà ni wọ́n tún ṣèkìlọ̀ lórí àwọn tó ń jà fún yíya kúrò lára Nàìjíríà tí wọ́n ń fa wàhálà ní ìlà oòrùn gúúsù Nàìjíríà, bí wọ́n ṣe máa ń kọlu àwọn ológun tó fi mọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò míì.

Wọ́n tún kọminú lórí bí ìjínigbé, jíja ọkọ̀ gbà ṣe wọ́pọ̀ ní ìpínlẹ̀ Eko bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà ìgbéṣùmọ̀mí kìí sábà wáyé níbẹ̀.

Wọ́n ṣèkìlọ̀ fáwọn èèyàn wọn àtàwọn arìnrìnàjò míì láti máa wà ní ojú lálakàn fi nígbà tí wọ́n bá wà ní ìpínlẹ̀ Eko.

FCDO rọ gbogbo àwọn èèyàn tó wà ní agbègbè tó léwu láti ṣe jẹ́jẹ́, kí wọ́n sì máa tẹ̀lé àwọn ìmọ̀ràn lórí ètò ààbò táwọn iléeṣẹ́ àti ilé ìtura tí wọ́n bá wà bá fún wọn.