Mọ̀ nípa abẹ́rẹ́ tó ń dá ebi dúró, mú àdínkù bá ara sísan, tó sì ń dènà àìsàn ọkàn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Abẹrẹ ajẹsara kan ti wa ti wón ṣe lati dena de ara sisan, to si tun dena aisan ọkan ati aisan rọpa rọsẹ lagọ ara gẹgẹ bii iwadii kan to ṣẹsẹ jade ṣe salaye.
Awọn oniwadii wo anfani to wa lara Semaglutide - oogun kan to da ebi duro, ti wọn fun ni lorukọ tuntun bi Wegovy, Ozempic ati Rybelsus.
Wọn ni abẹrẹ to n dena de ara sisan naa tun le ṣe ọpọlọpọ anfani fun awọn agbalagba.
Ọjọgbọn John Deanfield lo lewaju awọn oniwadii to se abẹrẹ naa sọ pe abẹrẹ yii le tun ni ipa nla lati mu ki ifunpa ati itọ suga eeyan wa silẹ, ti yoo si tun ṣe anfani nla fun ọkan.
Iwadii oni ọdun marun un ti ilẹ ẹkọ fasiti ti ilu London lo awọn ẹri ti wọn ri nigba ti wọp ṣe ayẹwo fun o le ni ẹgbẹrun mẹtadinlogun eeyan ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun marundinlaadọta ni orilẹede mọkanlelogoji.
“A ti pada ri pe oogun kan wa to le mu ayipada nla ba agọ ara, to si n dena ọpọlọpọ aisan ti yoo jẹ anfani fun ọpọlọpọ eeyan"
O sọ eyi saaju ifilọlẹ iwadii naa fun ajọ ilẹ Yooropu to n risi ara sisan ni Venice, Ọjọgbọn Deanfield ni iwadii ikọ rẹ ni ọpọlọpọ ojutu to ṣe pataki.
O ni o jẹ iwadii to ṣe pataki, to di bi asiko ti wọn gbe satins sita lọdun1990s
“A ti pada ri pe oogun kan wa to le mu ayipada nla ba agọ ara, to si dena ọpọlọpọ aisan ti yoo jẹ anfani fun ọpọlọpọ eeyan.
“A ti ni oogun to n yi ọpọlọpọ nnkan pada, paapa nipa ki eeyan maa dagba.”
Iwadii Ọjọgbọn Deanfield ti ṣayẹwo iye akoko ṣaaju ki awọn alaisan to ni awọn aisan cardiovascular to waye - bi aisan ọkan tabi aisan rọpa rọsẹ - tabi wọn di ijakulẹ ọkan.
Lẹyin ọsẹ ogun ti wọn ti lori oogun semaglutide, ida mejilelọgọta awọn alaisan yoo padanu ida marun un ara wọn dipo ida mẹwaa ti ẹgbẹ placebo.
Sibẹsibẹ, eewu adinku nipa aisan ọkan, kudiẹkuidẹ ọkan tabi aisan rọpa rọsẹ da bi eyi ti eeyan ti padanu ida marun un ara sisan.
Ọjọgbọn Deanfield sọ pe: “O fẹ to idaji awọn alaisan ti mo rii fun iwadii aisan ọkan ni ipele ara sisan.
Awọn oniwadi ti n ṣiṣẹ lori iwadii pe semaglutide n mu adinku ba eewu aisan ọkan tabi rọparọsẹ ninu awọn eeyan to ba ti sanra ju
Nigba to ba BBC Radio lonii, Ọjọgbọn Deanfield sọ pe oogun naa ni ipa nla “to pataki” ninu itọju sisan ara ju.
“Ọpọlọpọ awọn eniyan ti wọn n gbe pẹlu sisan ara ju, ni wọn nipa bi wọn ṣe san ara, ati pe oogun oogun, fun idi yii nikan, pese aye pataki to le mu adikun ba eyi,” o sọ.
“Ṣugbọn awọn oogun ti yoo tun ṣe anfani nla nipasẹ titako awọn iṣoro tabi ilera to ti wa tẹlẹ. Eyi mu ori wu pupọ.”
Ni oṣu kẹjọ, awọn oniwadi ti n ṣiṣẹ lori iwadii pe semaglutide n mu adinku ba eewu aisan ọkan tabi rọparọsẹ ninu awọn eeyan to ba ti sanra ju pẹlu arun ọkan.
Iwadii Ọjọgbọn Deanfield jẹ ọkan lara awọn iwadii meji ti wọn fẹ ṣe ifilọlẹ fun ajọ ECO ni Ilu Italy.
Iwadii keji ti Ọjọgbọn Donna Ryan lewaju , ti Ileeṣẹ Iwadi Biomedical Pennington ni Ilu New Orleans, wo ipa igba pipẹ semaglutide lori ara sisan.
Wegovy ni eroja kanna bi Ozempic - oogun itọ-ọgbẹ kan ti o sọ pe Hollywood “abẹrẹ ajẹsara”.
Ẹwẹ, awọn amoye ṣe kilọ tẹlẹ pe ko ṣe atunṣe kiakia tabi rọpo fun jijẹ ounjẹ daradara ati sise ere idaraya, ati pe wọn gbọdọ lo ni labẹ abojuto awọn onimọ nipa rẹ.















