Ìjọba Nàìjíríà wọ́gilé owó orí ìdá 0.5% tó kéde fún àbò lọ́wọ́ jìbìtì orí ayélujára

Oríṣun àwòrán, officialasiwajubat/instagram
Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti so amulo eto owo ori lori owo ti awọn ọmọ Naijiria ba gba lori ayelujara rọ bayii naa.
Laipẹ yii ni banki apapọ Naijiria kede pe gbogbo owo ti awọn ọmọ Naijiria ba n gba lori ayelujara yoo maa la owo ori ti wọn yoo maa yọ fun abo lọwọ jibiti ori ayelujara lọ.
Minisita feto iroyin, Mohammed Idris lo ṣalaye eyi lẹyin ipade igbimọ iṣakoso ijọba apapọ Naijiria to waye nilu Abuja lọjọ Iṣẹgun.
Minisita feto iroyin ni aarẹ orilẹede Naijiria, Bọla Tinubu paṣẹ ki wọn wọgile gbigba owo naa lẹyin ijiroro awọn ọmọ igbimọ iṣakoso ijọba apapọ Naijiria.
O ni aarẹ tun paṣẹ fun atungbeyẹwo eto naa ati ọna ti wọn yoo gba ṣe amulo rẹ.











