Iye àwọn tó ti kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ mọ́ṣáláṣí tí ọmọkùnrin kan dáná sun ní Kano ti di márùndínlógún

Awọn alaṣẹ ni ipinlẹ Kano lẹkun ariwa orilẹede Naijiria sọ wi pe iye awọn to ti jade laye lẹyin ti ọmọdekunrin kan dana sun Mọṣalaṣi nibẹ ti di marundinlogun.
Eeyan mẹrin miran jtun jade laye lọjọ Ẹti lẹyin ti won ti kọkọ kede oku eeyan mọkanla nibi iṣẹlẹ naa lọjọbọ.
Awọn miran to fara sese l’asiko ìṣẹlẹ buruku naa ṣi wa ni ile iwosan bayii.
Ọmọdekunrin naa da ina sun mọṣalaṣi naa lọjọru lẹyin to wọn epo bẹntiro yi gbogbo ara mọṣalaṣi naa to si sọ ina sii lẹyin to ti ilẹkun rẹ pa.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni iwadii ṣi n lọ lori iṣẹlẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Kano Police
Eeyan mọkanla lo ti ba iṣẹlẹ ina to waye nipinlẹ Kano lọ nibi ti ọkunrin kan ti dana sun Mọṣalaṣi nipinlẹ Kano,
Lowurọ Ọjọ kẹdogun oṣu karun un ni ileeṣẹ ọlọpaa kede sita pe ọwọ tẹ ọkunrin kan, Shafiu Abubakar, ẹni to mọmọ dana sun Mọṣalaṣi ti Ogoji eeyan wa ninu rẹ ti wọn si n kirun lọwọ.
Iṣẹlẹ naa waye ni ilu Gadan ni ijọba ibilẹ Gezawa.
Olugbe agbegbe naa ti orukọ rẹ n jẹ, Hamisu Abdullahi sọ fun BBC pe eeyan mẹjọ lara awọn to gbẹmi mi nitori iṣẹlẹ naa ni wọn ti ṣe eto isinku fun wọn.
"Ikọlu yii kọ ni akọkọ ti Shafiu yoo ṣe nitori o ti kọ́kọ́ pa awọn ẹgbọn rẹ meji, o si fara rẹ kalẹ fun ọlọpaa pe oun loun pa wọn"
Abdullahi tẹsiwaju pe “Ni bayii, wọn ti gbe oku awọn eeyan meje de, ti a si ti sin wọn, ti a yoo si sin ẹnikan yooku ni owurọ ọla.”
O jẹ ko di mimọ pe ọkan lara awọn oloogbe jẹ ẹgbọn rẹ lọkunrin.
O fikun pe o eeyan mejilelogun to wa ni ile iwosan bayii ti wọn gba itọju lọwọ.
Olugbe mii, Rabiu Gaden ṣalaye pe ikọlu yii kọ ni ikọlu akọkọ ti Shafiu yoo ṣe nitori o ti ki kọlu awọn ẹgbọn rẹ meji, to si tun fara rẹ kalẹ fun ileeṣẹ ọlọpaa pe o ṣe ṣekupa wọn.
Malam Garba to oun naa jẹ olugbe mii lagbegbe naa ni “Ni gbogbo igba ni ọkunrin yii ma wo bi pe nnkan n da lamu.
“Ọpọ igba ni wọn ti gbe lọ si ile iwosan lati ṣe ayẹwo ọpọlọ sugbọn wọn ni nnkan ko ṣe rara.
“Fun idi eyi o mọmọ lọ dana sun Mọṣalaṣi, ẹgbọn rẹ meji lo ba iṣẹlẹ naa lọ, ti a si ti sin wọn lanaa.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni afurasi naa da epo bẹntiroolu mọ ado oloro, to si sọ si Mọṣalaṣi nibi eeyan mẹrinlelogun to jẹ ọkunrin ti farapa, ti mẹrin ninu wọn si jẹ ọmọde.
"Àlàyé rèé lórí ìdí tí mo ṣe dáná sun Mọ́ṣáláṣí, tí èmi àti èèyàn 24 míì sì fara pa"

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kano ti mu ọkunrin afurasi kan ti wọn lo dana sun mọṣalaaṣi nipinlẹ Kano.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Kano, SP Abdullahi Haruna Kiyawa, sọ pe abule Arababar Abasawa, nijọba ibilẹ Gezewa, ni iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.
O ni lasiko ti awọn eeyan n kirun aarọ ninu mọṣalaaṣi naa ni afurasi sọ ina sibẹ.
Awọn eeyan ti wọn si wa ninu ile ijọsin lasiko naa ju ọgbọn (30), lọ gẹgẹ bo ṣe sọ.
SP Kiyawa sọ pe eeyan mẹrinlelogun ni wọn fara kaaṣa ina ọhun.
Ati pe ọkunrin kan, Shafi'u Abubakar, ẹni ọdun mejidinlogoji, naa f’ara ko ina ọhun.
O ni gbogbo wọn ni wọn ti lọ sileewosan lati gba itọju.

"Mo fẹ gbẹsan lara awọn ẹbi mi to n ba mi ṣe ajọpin ibusun ni mo se dana sun Mọsalasi lasiko ti wọn n kirun lọwọ"
Lori idi to fi dana sun mọṣalaaṣi, Alukoro ọlọpaa salaye pe:
‘’Ọmọkunrin naa sọ pe oun fẹẹ gbẹsan lara awọn ẹbi oun to n ba oun ṣe ajọpin ibusun ni.
‘’O ni oun ti kọ jalẹ lati maṣe sun lori ibusun kan naa pẹlu wọn mọ, ṣugbọn wọn ko gba.
‘’Awọn ẹbi rẹ naa wa ninu mọṣalaaṣi lọwọ idaji ti wọn n kirun lọjọ naa, ẹsan to fẹẹ gba lara wọn lo ṣe sọ ina sile Oluwa’’
SP Kiwaya sọ pe epo bẹntiroolu ni wọn fi pilẹ ina to jo mọṣalaaṣi naa, gẹgẹ bi iwadii awọn.
Ṣaa, afurasi naa ti wa lahaamọ ọlọpaa, nibi ti iwadii ti n tẹsiwaju.
Àwọn jàndùkú agbébọn lé àwọn èèyàn kúrò ní abúlé àádọ́ta ní Zamfara

Oríṣun àwòrán, Tsefe
O kere tan awọn olugbe aadọta abule l'awọn janduku agbebọn ti le kuro ni abule wọn ni ipinlẹ Zamfara.
Iṣẹlẹ yii lo ti jẹ k'awọn eeyan ti wọn le kuro ni abule wọn fan kaakiri bayii.
Ọmọ ile aṣoju-ṣofin to n ṣoju ẹkun Zurmi ati Shinkafi ti iṣẹlẹ naa ti waye, Họnọrebu Bello Shinkafi sọ fun BBC pe o le ni ẹẹdẹgbẹta eayan tawọn ajinigbe ti gbe lọ ni agbegbe naa.
Aṣofin Shinkafi sọ pe ni gbogbo igba l'awọn janduku agbebọn maa n ṣọṣẹ ni ẹkun ti oun n ṣoju.
O ni b'awọn agbebọn ti n ṣeku pa awọn eeyan oun ni wọn tun n ji ọpọ gbe lọ.
Họnọrebu Shinkafi ni gbogbo abule to wa ni ijọba ibilẹ Zurmi nipinlẹ Zamfara ni ko ṣee gbe mọ tori b'awọn janduku agbebọn ṣe n pa awọn eeyan ti wọn ṣi tun n ji wọn gbe lọ.
Awọn janduku agbebọn n ji awọn eeyan gbe lọsan gangan
Ni ọjọ Aje to kọja yii ni a gbọ pe awọn janduku agbebọn sẹku pa ọlọpaa meji ni ọsan gangan niluu Gidan Shaho, nigba ti awọn mii farapa.
Họnọrebu Shinkafi ni lootọọ ni pe ijọba n gbiyanju lati doola awọn olugbe awọn abule to wa ni Zurmi nipa kiko awọn ẹṣọ eleto abo lọ si agbegbe ọhun, amọ, aṣofin naa ni o yẹ ki awọn ẹṣọ eleto aabo ṣe ayipada ọna ti wọn n gba koju awọn ọdaran agbebọn yii.
Shinkafi ni "awọn ẹṣọ eleto abo to wa ni Zamfara gan an ko to.
Bakan naa, awọn sọja kan ti wa ni Zamfara fun bi ọdun mẹsan an, o yẹ ki wọn paarọ wọn pẹlu awọn mii.
Ijọba ipinlẹ Zamfara naa n gbiyanju lati doola awọn eeyan tawọn janduku agbebọn yii jigbe.
Eeyan bii igba ni ijọba ti ri doola pada lọwọ awọn ajinigbe laipẹ yii.
Aṣofin Bello Shinkafi daba kiko awọn ẹṣọ eleto abo mii lọ sí Zamfara
Họnọrebu Shinkafi da aba nile aṣoju ṣofin l'Abuja wi pe ki ijọba apapọ ṣe afikun awọn ẹṣọ eleto abo ni ipinlẹ Zamfara.
Họnọrebu Shinkafi sọ niwaju ile wi pe ẹkun ti oun n ṣoju ni ipinlẹ naa nilo ki awọn sọja ati ọlọpaa pọ si ki wọn le koju awọn janduku to n ṣọṣẹ níbẹ.
O ni ọpọ araalu lo si wa lakata awọn ajinigbe níbẹ eyi t'awọn ẹṣọ eleto abo ṣi le doola wọn.
Ipinlẹ Zamfara jẹ ọkan lara awọn ipinlẹ t'awọn janduku agbebọn ti n ṣọṣẹ ni apa iwọ oorun ariwa orilẹede Naijiria.
Bi awọn agbebọn yii ṣe n ṣe ikọlu s'awọn abule ni wọn n ji awọn eeyan gbe lọ, koda, wọn n tun ṣekupa awọn mii.
Ijọba apapọ ati ti ipinlẹ Zamfara l'awọn n gbiyanju agbara awọn lati daabo bo araalu, amọ, ikọlu awọn janduku agbebọn ṣi n tẹsiwaju ni ipinlẹ Zamfara.
















