Mọ̀ si nípa ọkọ̀ tó ń lo afẹ́fẹ́ gáàsì tí ìjọba kó wọlé láti rọ́pò ọkọ̀ tó ń lo epo bẹntiró

Aworan lilo CNG ninu ọkọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aarẹ Bola Tinubu ti paṣẹ fun gbogbo ẹka ileeṣẹ ijọba lati ra awọn ọkọ to n lọ afẹfẹ gaasi, lati fi rópo awọn ọk to n lo epo bntiroolu.

Agbẹnusọ fun Aarẹ, Ajuri Ngelale lo kede igbesẹ Aarẹ naa ninu atẹjade kan to fi lede fun awọn akọroyin.

Ngulale ni ilana naa wa lati ri pe ijọba ṣe ohun to tọ si ẹka afẹfẹ gaasi ati lati ṣe adikun si owo epo to wọn lasiko yii.

O fikun pe Aarẹ Bola Tinubu ti paṣẹ fun gbogbo awọn ẹka ijọba lati lọ ra awọn ọkọ to n lo afẹfẹ gaasi.

Gẹgẹ bii o ṣe sọ, igbesẹ yii lo da lori igbiyanju ijọba lati maa lo afẹfẹ gaasi, eyi ti yoo mu adikun ba bi eefin ṣe n gba oju ọjọ.

Sugbọn ọpọ eeyan ni ko mọ nipa awọn ọkọ to n lo awọn afẹfẹ gaasi yii ati bo ṣe ń sisẹ si.

Idi ree ti BBC Yoruba fi ṣe ẹkunrẹrẹ iwadii nipa awọn ọkọ to n lo afẹfẹ gaasi naa pẹlu iyatrọ to wa laarin rẹ ati awọn ọkọ to n lo epo bẹntiroolu.

Bakan naa, a tun se awari awọn anfani to wa ninu lilo ọkọ afẹfẹ gaasi fun awọn olugbe Naijiria.

Lita gaasi mẹfa tabi meje le e rin ọgọrun kilomita amọ lita epo bẹtirolu mẹwa ni a lo lati rin kilomita yii

Gaasi taa n pe ni CNG yii wa latara gaasi ta n ri gẹgẹ bi alumọni ni.

Ni eyi to jẹ apeejuwe ti yoo ye wa, gaasi yi jẹ eleyi ti wọn ṣakojọpọ rẹ lọna ti yoo ṣe lo lati fi pese ina, ṣe iranwọ fun ọkọ taa n lo tabi ki a si fi mu ile tutu tabi gbona nipa ẹrọ amuletutu wa ''air conditioner.''

Jakejado agbaye, o sunmọ miliọnu mẹtalelogun ọkọ ti wọn lo gaasi CNG yii nikan fun tabi ki wọn lo gaasi yi papọ pẹlu bẹntiroo ninu ọkọ wọn.

Bi eeyan ba ni to jala lita gaasi mẹfa tabi meje, o le fi ọkọ naa rin irinajo ọgọrun kilomita.

Irin yii, bi eeyan ba lo bẹntiroo, yoo lo jala epo lita mẹwaa.

Lagbaye awọn ilu kan n ṣe amulo ọkọ yi ju ara wọn lọ.

Ni Latin America ati India, wọn gba ti ọkọ yii daada ju awọn to wa ni Yuroopu lọ.

Nilẹ adulawọ wa nibi yi, imọ nipa awọn ọkọ yii ko ti pọ daada.

Ni Naijiria, nkan ajoji lo jẹ ṣugbọn o ṣeeṣe ki o di atẹwọgba pẹlu bi bẹntiroo ti ṣe gbowo lori yi.

Aworan ọkọ bọọsi afẹfẹ gaasi

Oríṣun àwòrán, INNOSONVEHICLES

Gaasi ki yara jo tan, kii si ko ipalara ba ayika wa bi ti bẹntiroo

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Cornel Osigwe, to jẹ agbẹnusọ fun ileeṣẹ IVM sọ pe, anfaani kan ti lilo ọkọ gaasi CNG ni lori awọn eyi to n lo bẹntiroo tabi disuu ni pe gaasi yi kii yara jo tan.

O ni ''gaasi kii ko ipalara ba ayika wa bi ti bẹntiroo.

Ọkọ bẹntiroo mọ awọn ọmọ Naijiria lara lootọ ṣugbọn pẹlu bi a ṣe ni gaasi lọpọ yanturu, iru ọkọ CNG yii yoo ṣe anfaani faraalu''

Gẹgẹ bi iwadii kan ti Price Water Cooper, PWC, gbe jade, Naijiria ni orileede ikẹsan to ni alumọni gaasi julọ lagbaye.

O ni Naijiria ni to 209.5 trillion cubic feet gaasi ti wọn ko si ribi ṣamulo ọpọ rẹ.

Lati le mọ bi gaasi Naijiria ṣe pọ to, Orileede Morocco lọdun 2022 buwọlu adehun kan lati ṣafikun ipese oju opo kun eleyi to wa nilẹ ti yoo gbe gaasi lati Naijiria lọ si orileede wọn.

Oju opo yi yoo ni ikapa lati gbe gaasi 30 billion cubic m/lọdun kan ti yoo si bẹrẹ lati Eko gba Cotonou Lome, Togo,Takoradi ni Ghana Abidjan ni Cote d''voire gba awọn orileede mii titi ti yoo fi kangun si Morocco.

Igbagbọ ni pe yoo ti ati ibẹ lọ si Yuroopu lati Spain.

US$25 billion ni wọn yoo fi pese oju opo yi ti wọn si lero pe yoo bẹrẹ lọdun 2046.

O le yi ọkọ rẹ to n lo bẹntiroolu pada si ti gaasi

A ti yi ọkọ pada lati eleyi to n lo epo bẹntiroo si gaasi CNG tabi LNG kii ṣe nkan to le.

Imọ nipa rẹ kan le ma ti kari bi ti yiyi ọkọ to n lo ọwọ ọtun si apa osi ni Naijiria, amọ awọn to n ṣe wa ni Naijiria.

Ileeṣẹ Innoson taa darukọ ṣaaju wa lara awọn to le ba eeyan yi ọkọ pada si ko maa lo gaasi dipo bẹntiroo.

Ileeṣẹ naa loju opo wọn ni awọnm si tun le ba araalu ṣe aaye ninu ọkọ rẹ ti yoo maa lo gaasi ati bẹntiroo papọ.

Eleyi yoo da bi awọn ọkọ ti wọn n pe ni Hybrid to n ṣe amulo oriṣi ọna lati jẹ ki ọkọ le rin lati ibi kan si omiran.

Pataki julọ awọn onimọ sọ pe bi eeyan ba fẹ ṣe ayipada tabi afikun yi, ko rii wi pe ọkọ rẹ jẹ eleyi ti yoo le gba iru ayipada yi.

Bakan naa ni wọn mu amọran wa wi pe ki eeyan ro daada boya yoo maa ri gaasi deede to ba yi ọkọ naa kuro lati bẹntiroo si gaasi ko ma di pe ati ri gaasi ra yoo di iṣoro.

Ni ti tiẹ, ijọba orileede Naijiria ti ṣe ipinu lati mu alekun ba iye ọkọ ti yoo ma lo gaasi gẹgẹ bi ọkan lara eto mimu ayedẹrun lẹyin ti wọn ba yọ subsidy epo.

Nigba to n ṣe alaye ọrọ yi nigba naa lọhun, Minisita keji fọrọ alumọni epo Timipre Sylvia ṣalaye pe ijọba gbero lati yi nkan bi miliọnu marun ọkọ si eyi to n lo gaasi nigba ti wọn yoo fi pari eto naa.

Oṣu mẹrindinlogoji,36, ni wọn la kalẹ pe ijọba yoo fi ba awọn to n pese irinṣẹ,Original Equipment Manufacturers (OEM) ati awọn oniṣowo epo ati gaasi,ṣiṣẹ ti wọn yoo fi sọ ọkọ miliọnu kan di eyi to n lo gaasi.

Bẹẹ lo ni awọn yoo pese aaye ti wọn yoo ti maa ta gaasi si ọkọ ẹgbẹrun kan.

Ọkọ gaasi CNG, n jẹ ṣe o ni ewu?

Aworan ọkọ afẹfẹ gaasi to n gba gaasi sara

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọkọ lilo yala eyi to n lo gaasi tabi epo bẹntiroo lo lewu.

Lọpọ igba, ewu yi gẹgẹ bi awọn onimọ ti ṣe sọ, ko ṣẹ lẹyin pe awọn eeyan to n lo ọkọ kii fẹ tẹle imọran ti awọn to ṣe ọkọ naa la kalẹ.

Ọkọ oni gaasi CNG yi le jẹ eleyi ti wọn ṣe wa lati ileeṣẹ ọlọkọ tabi ko si jẹ pe wọn yi pada si lilo gaasi tabi ko ṣi ṣe pe o n lo gaasi ati epo bẹntiroo pọ.

Bo ba jẹ elleyi ti wọn ṣe wa pẹlu ile epo gaasi ati irinṣẹ rẹ, ọrọ buṣe.

Ẹnu ki awakọ maa tẹle gbogbo imọran ko si ri pe oun n ra gaasi nibi ti wọn ti n ta eleyi ti ọkọ rẹ n lo.

Gboogbo atunṣe to ku o ku si ọwọ ẹni to n lo irufẹ ọkọ naa.

Amọ bo ba ṣe pe onitọhun yi ọkọ elepo pada si gaasi ni, o ni lati ri wi pe ọkọ naa jẹ eleyi ti yoo gba iyipada bẹẹ loun lo.

Awọn eeyan a maa ra nkan eelo iyipada ọkọ taa mọ si Conversion Kit.

Bi o ba fẹ ra nkan eelo yi, ri wi pe eleyi ti yoo ṣiṣẹ pẹlu ọkọ rẹ lo ra.

Ti ko ba ri bẹẹ, wahala bẹrẹ ni yẹn