Akẹ́kọ̀ọ́ táwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ fìyà jẹ l'Abuja gbé ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀ relé ẹjọ́, bèèrè fún N500m owó gbà má bìnú

Awọn akẹkọọ

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Akẹkọọ kan, Namitra Bwala to han ninu fidio kan laipẹ yii nibi tawọn akẹgbẹ rẹ ti n fiya jẹ, ti gbe ile ẹkọ Lead British International School ni agbegbe Gwarimpa niluu Abuja, lọ ile ẹjọ.

Ọkan lara awọn fidio to lu ori ayelujara pa ṣafihan ṣafihan bi akẹkọọbinrin mii ṣe gba Bwala leti.

Ninu ẹjọ ti o pe, Bwala n beere fun N500,000,000 owo gba mabinu lọwọ ile ẹkọ rẹ lẹyin to sọ pe ilẹ ẹkọ naa kuna lati pese abo to peye fun oun nile ẹkọ.

"Ẹjọ ti akẹkọọbinrin naa pe yoo jẹ ki opin de ba iwa ifiyajẹni lọgba ile ẹkọ"

Bwala tun sọ pe oun n pe ile ẹkọ rẹ ni ẹjọ ni tori pe ile ẹkọ naa ko ka ọrọ ọhun kun lati igba ti ọrọ naa ti waye.

Bakan naa tun ni Bwala sọ fun ile ẹkọ rẹ lati tọrọ aforijin ninu iwe iroyin meji ni Naijiria.

Ileeṣẹ amofin to n ṣoju Bwala salaye pe ẹjọ ti akẹkọọbinrin naa pe yoo jẹ ki opin de ba iru iwa ifiyajeni yii lọgba ile ẹkọ.

"Onibara wa ni ireti pe ẹjọ ti o pe yoo dena irufẹ iṣẹlẹ to ṣẹlẹ si i lati tun ṣẹlẹ si ẹlomiran ninu ọgba ile ẹkọ Lead British International School," ileeṣẹ amofin to n ṣoju Bwala lo sọ bẹẹ.

Ọpọ ọmọ Naijiria lo kọminu lori eto abo awọn akẹkọọ nile ẹkọ Lead British International School, nigba ti fidio to ṣafihan bi awọn akẹgbẹ rẹ ṣe n fiya je akẹkọọbinrin naa.