Adeleke, máṣe dáwọ́ ijó jíjó dúró àmọ́ mú ìṣèjọba rere ní pàtàkì l‘Osun - Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Aarẹ tẹlẹri lorileede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti parọwa si Gomina Ademọla Adeleke ti ipinlẹ Ọṣun, lati maṣe dawọ ijo jijo rẹ duro, ati pe ko tubọ gbajumọ iṣejọba rere.
Ọbasanjọ lo parọwa yii nibi ifilọlẹ ibugbe awọn ọlọlajulọ to kọ sinu ọgba ile gbigbe awọn gomina to wa niluu Oṣogbo, ipinlẹ naa.
Aarẹ tẹlẹri naa to tun jẹ Balogun ilu Owu sọ pe ki Adeleke rii daju pe o sa gbogbo ipa ati agbara rẹ lati mu igbesi aye irọrun ba awọn ọmọ bibi ati olugbe ipinlẹ Ọṣun.
Nigba to n sọrọ, Ọbasanjọ rọ Adeleke lati mu iṣọkan pada sinu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP nipinlẹ naa, ati pe ko bẹrẹ awọn igbesẹ ti yoo ṣe anfaani rere fun araalu
Siwaju sii ni Ọbasanjọ sọ pe ki Adeleke rii daju pe akọsilẹ to tọ n wa fun awọn iṣẹ to n ṣe gẹgẹ bii gomina nitori ọjọ iwaju.
Ki ẹni to ba fẹ bu wa tẹsiwaju - Ọbasanjọ
Olusegun Obasanjo sọ siwaju si pe “Awọn kan ti bu ẹnu atẹ lu ẹ tẹlẹ, wọn n pe ẹ ni onijo lasan.
Ni idahun mi, mo sọ fun wọn pe ẹni ti inu rẹ ba dun nikan lo le jo.
“Lati asiko yii, o ti di akẹgbẹ mi ninu ijo jijo.
“Ohun ti mo ti gbọ ati eyi ti mo ti ri lati bii ọjọ mẹta ti mo ti wa nibi, bi ẹnikẹni ba ṣi tun n ṣiyemeji lori rẹ, mu ẹni naa wa si ipinlẹ rẹ lati fi oju ara rẹ ri funra rẹ.
“Bi o ba ranti pe nigba kan ri, mo pe ẹ lori ẹrọ ibanisọrọ, mo si sọ pe ki o ma ṣe dawọ ijo jijo duro, ṣugbọn mo tun fi kun un pe bi o ṣe n jo, gbiyanju lati rii daju pe o tun n ṣiṣẹ pẹlu ẹ.
“Bi mo ba sọ fun ẹ pe mi o mọ ohun to ṣẹlẹ ki o to de ipo ijọba, irọ ni mo pa. Ṣugbọn ni ọjọ Aiku to kọja lọ, o ṣe ohun to jọ mi loju, to si wu mi lori.
“O ranṣẹ pe gbogbo awọn oloye ati alẹnulọrọ ẹgbẹ papọ. Inu mi dun wi pe o pe wọn papọ. Sẹnetọ Olu Alabi wa nibi, Gomina tẹlẹri, Ọlagunsoye Oyinlọla wa nibi ati Fatai Akinbade naa.
“O ni lati ko gbogbo wọn mọra lati jọ maa ṣiṣẹ. Ohun to dara julọ lati ṣe niyẹn. Mo ti ba meji ninu wọn sọrọ. Igbesẹ to dara ni, eyi ti kii ṣe pe ẹgbẹ oṣelu yin nikan lo dara fun, bi ko ṣe ipinlẹ yii ati orileede Naijiria.
“O sọ pe ijọba n tẹsiwaju ni, o si tun sọ pe gbogbo iṣẹ aṣepati lo ti n ṣiṣẹ le lori; ki Ọlọrun bukun fun iṣẹ ati ilakaka rẹ.
“Gbogbo ibikibi ti a ba ti pade, a maa jo, a si maa yọ. Bi ẹnikẹni ba fẹ bu wa, ki wọn tẹsiwaju. Ni abojuto iṣẹ, ko si opin sii, a ni lati maa gbajumọ ọ siwaju sii ni. Inu mi dun wi pe ṣisẹ n tẹle lo n ṣe awọn iṣẹ naa.
“O ni lati ṣe otitọ pẹlu ẹri ọkan rẹ, si awọn eeyan ati si Ọlọrun rẹ. O si nilo lati jẹ ẹniyan to ni iwa rere.”
Ki ni esi ti Ademola Adeleke fọ pada fun Obasanjo?
Nigba toun naa n sọrọ saaju asiko yii, Adeleke ni pupọ awọn akanṣe iṣẹ to ga julọ ni iṣakoso oun ti pari.
Bakan naa, o ni iṣẹ tun ṣi n lọ lori awọn akanṣe iṣẹ yooku ninu agbekalẹ oun fun itẹsiwaju ipinlẹ Ọṣun.
Adeleke ni ibugbe awọn ọlọlajulọ naa yoo mu adinku ba owo nina nipa gbigba alejo awọn eeyan jankanjankan nipinlẹ naa, to si ni bi wọn ṣe pari rẹ jẹ aṣeyọri nla.















