Aráàlú ṣèwọ́de ìfẹ̀hónúhàn torí ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ ní Benin Republic

Awọn araalu ati awọn oṣiṣẹ ijọba lorilẹede Benin Republic ti koro oju si bi owongogo ounjẹ ṣe n peleke si bayii lorilẹede naa.
Eyi lo si mu ki awọn araalu paapaa awọn oṣiṣẹ ijọba ṣe ṣewọde lati fi ẹhonu wọn han lori bi gbogbo nnkan paapaa ounjẹ ṣe n fi ojoojumọ gbowo lori.
BBC kọwọrin pẹlu awọn araalu ati osisẹ ijọba lasiko ti wọn ṣe iwọde tako ọwọngogo ounjẹ lorilẹede naa.
Saaju ni iwọde kan ti kọkọ waye ni ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2024, bi o tilẹ jẹ pe ijọba ni awọn ko faaye gab ẹnikẹni lati ṣe iwọde lasiko naa.
Bakan naa ni iwọde mii tun waye lọjọ Kiini, oṣu Karun un, ti ijọba si da awọn ẹsọ alaabo sita pe ki wọn ko awọn eeyan to kopa ninu iwọde naa.
Eeyan mejilelaadọrin lo dero atimọle ninu awọn to kopa ninu iwọde ọhun.


Laipẹ yii ni wọn fi eeyan mọkanlelaadọta silẹ laarin wọn, ti ile ẹjọ si palasẹ pe ki wọn lo ṣe ayẹwo fun wọn sugbọn ti ayẹwo jẹ ko di mimọ pe wọn n lo egbogi oloro.
Eyi lo fa ti ile ẹjọ fi da eeyan mọkanlelogun pada si ọgba ẹwọn.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Aliou Yanhoue ni inu awọn araalu ko dun rara si ohun ti ijọba n ṣe fun wọn lori ọrọ ounjẹ.
O ni o ṣeni laanu pe owo ti awọn gba loṣu ko to nnkankan rara ati pe o kere lati fi ra ounjẹ lati fi bọ idile kan pẹlu bi ounjẹ ṣe ti di goolu fun awọn.
“Awọn ounjẹ ti a n jẹ bayii bi Garri, Agbado ati awọn ounjẹ mii ti gbe owo lori, to si n fa inira fun araalu.
“Ni bo ni a n lọ pẹlu eyi, awọn nnkan yii ko dara.
“Awọn ọlọpaa wa na awọn aburo bi pe wọn jale niluu wa sugbọn nitori bi nnkan ṣe wọn gan ni ale se iwọde yii.”
Aladji Sabirou Madjidi naa ba wa sọrọ pe o nira lati jẹ ounjẹ ni igba mẹta bayii lorilẹede Benin Republic.
O tun fẹsun kan ijọba pe wọn ko fi aye silẹ fun awọn araalu ati osisẹ ijọba lati ṣe iwọde lori ohun to n dun wọn lọkan.
“A ni lati sọrọ sita pe ebi n pa awa araalu. Ati osisẹ ijọba ati araalu ni ebi n pa“.















