Ààrẹ Tinubu fi oyè GCON dá Awùjalẹ̀ lọ́lá

Oríṣun àwòrán, Dapo Abiodun/Facebook
Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu ti fi oye ipo keji to ga julọ lorileede Naijiria, Grand Commander of the Order of Niger, GCON da Awujalẹ tilẹ Ijẹbu, Ọba Sikirulai Kayọde Adetọna, Ọgbagba keji lọla.
Nibi eto ayẹyẹ ọjọ ibi aadọrin ọdun ti Ọba Adetọna ṣe niluu Ijẹbu-Ode ni Aarẹ Tinubu ti sọ pe Kabiyesi ọhun tọ si ipo ọkan lara awọn ọlọla to ga julọ, ti wọn si gbọdọ maa bọwọ fun.
Ọjọ Ẹti, ọsẹ yii ni Aarẹ Tinubu fi aami ẹyẹ ti oye ọhun da Awujalẹ lọla, nibi ti awọn bii Fẹmi Gbajabiamila to jẹ olori oṣiṣẹ aarẹ, Gomina Dapọ Abiọdun tipinlẹ Ogun, Gomina Ademọla Adeleke tipinlẹ Ọṣun ati awọn miran ti peju.
Nibẹ ni Aarẹ Tinubu tun ti jẹ ko di mimọ pe ijọba apapọ yoo gba iṣakoso ile-ẹkọ Awujalẹ ti wọn ti n kẹkọọ nipa ilana ati eto oṣelu, Policy and Governance Studies.
Igbakeji Aarẹ, Kashim Shettima to ṣoju Aarẹ Tinubu sọ pe ipa ti Awujalẹ n ko lori ọrọ eto ẹkọ lati ọdun kẹrinlelọgọta to ti wa lori ipo ṣe pataki pupọ, awọn si nilo lati da a lọla.
“Ijọba apapọ yoo gba iṣakoso ile-ẹkọ Awujalẹ lati le fi mọ iriri ipa rere ti kabiyesi n ko lori eto ẹkọ.
“A n ṣajọyọ igboya, iyi, ọwọ ati igbe aye to fi ara jin fun iṣẹ isin
“Awujalẹ duro digbi lati koju iwa irẹjẹ ati idunkooko lasiko ijangbara fun ominira eto oṣelu awa-ara-wa laarin ọdun 1993 si ọdun 1999.
“Ti ijọba awa-ara-wa ba n dun lonii, ko si nnkan meji to fa a, bi ko ṣe pe awọn agba wa bii Ọba Adetọna ti duro digbi lati ja fun awọn eeyan.”
Ṣaaju ninu ọrọ rẹ, Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun gbe oṣuba kare fun Ọba Adetọna lori ifarajin rẹ fun iṣakoso rere nipa ṣiṣe agbatẹru idasilẹ ẹkọ iṣejọba rere ni fasiti Ọlabisi Ọnabanjọ to wa niluu Ago-Iwoye.
“Aṣiwaju, olukọle, ati aṣẹgun ni baba jẹ. O si maa n wu mi lori pupọ gbogbo igba nipa awọn iṣẹ ti wọn ti ṣe silẹ, ati awọn eyi ti wọn n ṣe lọwọ.”
Bakan naa lo tun fi kun ọrọ rẹ pe iwuri nla lo jẹ wi pe igba akọkọ ree ti gbogbo awọn akọwe ijọba to wa nipinlẹ naa lasiko yii ni wọn jẹ akẹkọọjade nile ẹkọ Awujalẹ, iyẹn Oba Sikiru Adetuna School of Governance Studies.
Lara awọn to wa nibẹ ni awọn gomina ana nipinlẹ Ogun, Oluṣẹgun Ọṣọba; Gbenga Daniel ati Ibikunle Amosun; Gomina tẹlẹ nipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai ati awọn miran.















