‘Akẹ́kọ̀ọ́ fásitì kan tí wá fi owó ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀ ta tẹ́tẹ́ níbí rí, a ta fóònù rẹ̀ fi ta tẹ́tẹ́, Ó tún yá'wó ọkọ̀ lọ sílé’
‘Akẹ́kọ̀ọ́ fásitì kan tí wá fi owó ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀ ta tẹ́tẹ́ níbí rí, a ta fóònù rẹ̀ fi ta tẹ́tẹ́, Ó tún yá'wó ọkọ̀ lọ sílé’

Tẹtẹ jẹ ohun to gbajumọ pupọ lorilẹede Naijiria ati jakejado agbaye.
Aisi amojuto ati ifidimulẹ awọn ofin to de tẹtẹ tita ti mu ki iye awọn to n ta tẹtẹ otubọ pọ si ti awọn ewu tawọn to n ta a n faragba si tun tipa bẹẹ pọ sii pẹlu.
“Mo ti ta odindi ọkada mi lati fi ta tẹtẹ” ni ẹri kan ti ọkan lara awọn to ba BBC News Yoruba sọrọ ṣe lalaye.
Irufẹ awọn ewu ti awọn to n ta tẹtẹ tabi ti tẹtẹ ti di baraku fun n foju wina rẹ loorekoore niyi.
Ko din ni ogoji ileeṣẹ tẹtẹ lo wa lorilẹede Naijiria bayii, ti ko si din ni ọgọta miliọnu ọmọ Naijiria to n ta a.
Ọpọ awọn to n ta tẹtẹ lorilẹede Naijiria lo jẹ wi pe bi ọrọ aje ilu ṣe ri lo sun wọn de ibẹ lọna ati lee gbọ ipenija iṣuna wọn.






