Ọmọọba Harry, Meghan gúnlẹ̀ sí Nàìjíríà

Ọmọọba Harry ati iyawo rẹ, Meghan

Oríṣun àwòrán, PA Media

Ọmọọba ilẹ Gẹẹsi, Harry, ati iyawo rẹ Meghan ti gunlẹ si orilẹede Naijiria lẹnu abẹwo tiwantiwa kan.

Ileeṣẹ eto abo lorilẹede Naijiria lo n gbalejo wọn.

Igba akọkọ niyi ti tọkọtaya yii yoo maa ṣe abẹwo si Naijiria, Ọgagun agba ileeṣẹ ọmọogun Naijiria, Ọgagun Christopher Musa lo si pe wọn fun abẹwo naa.

Lara awọn eto ti ireti wa pe o wa nikalẹ fun awọn mejeeji ni abẹwo si ibudo itọju kan ati ipade pẹlu awọn ileeṣẹ ati lajọlajọ to n ṣugba awọn abọde ologun lorilẹede Naijiria.

Ọjọ mẹta ni Ọmọ ọba Harry ati iyawo rẹ, Meghan yoo lo ni Naijiria, wọn yoo de ilu Kaduna lẹkun iwọ oorun ariwa orilẹede Naijiria lati fọrọ jomitoro ọrọ pẹlu awọn ọmọogun to fara ṣeṣe loju ija atawọn ẹbi wọn.

Bakan naa ni wọn yoo tun de ibudo karakata kan ni ilu Eko.

Ileeṣẹ ọmọogun Naijiria sọ peabẹwo Ọmọọba Harry to jẹ oludasile ere idaraya Invictus ganes to wa fun awọn ọmọogun to fi ara pa loju ija, yoo tubọ mu ki eto itọju awọn ọmọogun naa o tubọ jafafa sii ni.

Ere Idaraya Invictus games jẹ ere idaraya ti wọn gbe kalẹ fun awọn ọmọogun lọkunrin ati lobinrin ti wọn fara gbọgbẹ loju ija, Ọmọọba Harry ni oludasilẹ, to si n tun n ṣe agbodegba ati onigbọwọ fun ere idaraya naa.

“Gẹgẹbi ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ igbimọ ere idaraya Invictus, abẹwo yii yoo tubọ kan tan imọlẹ si pataki ati itẹwọgba ileeṣẹ ọmọogun orilẹede Naijiria.”

Orilẹede Naijiria naa n sa ipa lati gbalejo ere idaraya Invictus ni ọdun 2029.

Lasiko abẹwo yii, Meghan, iyawo Ọmọọba Harry pẹlu yoo lewaju apero kan fun awọn obinrin lori didi ipo aṣiwaju mu.

Ileeṣẹ aṣoju ijọba ilẹ Gẹẹsi ni ilu Abuja ni awọn ko mọ si abẹwo naa nitori pe, abẹwo ara ẹni ni wọn fi ṣe.