Mọ̀ si nípa ojúṣe Ọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lẹ́yìn ayẹyẹ ìfinijoyè rẹ̀

Bi ayẹyẹ ifinijọba Charles III ti ṣe waye bayii, to si ti di Ọba ogoji ilẹ Geesi ti wọn bura fun ni Westminister Abbey, o di Ọba lẹyin iku iya rẹ Ọbabinrin, Elizabeth II to papoda ninu osu kẹsan an ọdun to kọja.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ojuse Oba nilẹ Gẹẹsi.

Awọn Ọba ilẹ Gẹẹsi ni olori orilẹede wọn, ṣugbọn ninu oṣelu wọn kan jẹ fidi hẹ ni.

Ojojumo ni wọn n gba iwe to ṣalaye awọn igbese ijọba ti wọn si tun ma n buwọlu lẹta to ṣe pataki.

Adari orilẹede maa n ṣe ipade pọ pẹlu Ọba ilṣ Gẹẹsi lọjọru ni aafin to wa ni Buckingham ti wọn a si jiroro nipa igbeẹ ijọba .

Ipade yii ni o jẹ ipade bonkẹlẹ ti ko si ṣi akọsilẹ rẹ.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Yiyan adari ẹgbẹ oṣelu

Adari ẹgbẹ oṣelu ni ilẹ Gẹẹsi yoo ṣaaju ṣe abẹwo si aafin Ọba ilẹ Gẹẹsi lẹyin to ba ti jawe olubori gẹgẹ bi adari orilẹede ọhun.

Iṣide ijọkọ ile iṣẹ Ọba ile Gẹẹsi ni lati ṣide ijoko ile igbimọ aṣofin akọkọ lọdọdun.

Fifi ọwọ si abadofin

Iṣẹ Ọba ilẹ Gẹẹsi ni lati buwọlu gbogbo abadofin ile igbimo aṣofin ilẹ Gẹẹsi.

Ọba ilẹ Gẹẹsi ni Ọba gbogbo orilẹede to wa labẹ ajọ CommonWealth, oun si ni yoo ma sẹ kokari alejo gbigba nilẹ Gẹẹsi.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Bi wọn ti jọba nilẹ Gẹẹsi.

Akọbi ninu ile ni o lẹtọ lati di ọba ile Gẹẹsi, gẹgẹ bi ofin oye jijẹ ti wọn buwọlu ni ọdun 2013, ofin naa faaye silẹ fun ẹni ti o jẹ akọbi ninu ile lati di Ọba ko ni ṣe boya ọmọbinrin ni.

Arole Ọba Charles ni ọmọ ọba Wales, Ọmọ Williams to dagba julọ, George ni o tẹlẹ baba rẹ ti ọmọbinrin rẹ Charlotte, ọmọbakunrin Loius ati Harry tẹlẹ bi oyẹ Ọba ilẹ Gẹẹsi yoo ṣe lo.

Aworan