Ìjọba Kaduna yóò kó ilé ẹ̀kọ́ 359 pọ̀ sójú kan náà látàrí ìjínigbé lemọ́lemọ́

Oríṣun àwòrán, getty images
Ijọba ipinlẹ Kaduna ti kede pe oun yoo ko awọn akẹkọọ ile ẹkọ ti iye rẹ jẹ 359 soju kan naa latari ikọlu lemọlemọ awọn ajinigbe sawọn ile ẹkọ wọn.
Gomina Uba Sani, ti olori awọn oṣiṣẹ rẹ, Sani Kila ṣoju fun lo sọ ọrọ naa nibi idanilẹkọ kan lori abo awọn ile ẹkọ nipinlẹ ọhun.
O ni ijọba ti ṣẹtan lati ko awọn akẹkọọ kuro lawọn ile ẹkọ lawọn agbegbe ti awọn ajinigbe maa n kọlu lọ sawọn agbegbe ti abo wa.
Ninu alaye rẹ, Kila sọ pe awọn ṣagbekalẹ eto kan lati daabo awọn akẹkọọ naa labẹ eto ‘Safe School Initiative’ ti ijọba apapọ gbe kalẹ ṣaaju.
O fi kun pe ipinlẹ Kaduna jẹ ọkan gbogi lara awọn ipinlẹ tawọn agbebọn, ajinigbe ati agbesumọ n kọlu julọ ni Naijiria, awọn akọlu lemọlemọ naa si ti ṣakoba fun ọrọ aje ipinlẹ ọhun.
Aṣoju gomina ọhun sọ siwaju si pe “ipinlẹ Kaduna n koju iṣoro nla ni ẹka eto ẹkọ, ati akẹkọọ 200,000 lo sa kuro nile ẹkọ, ti wọn si kọ lati fi orukọ silẹ ni saa 2022/2023.
“Eyii n tumọ si pe akẹkọọ 2,111,969 lo forukọsilẹ ni saa 2021/2022 ti akẹkọọ 1,734,704 si forukọsilẹ ni saa 2022/2023.
“Lọpọ ijọba ibilẹ, paapaa ni Chikun, Birnin gwari, Kajuru, Giwa, ati Igabi eto abo to mẹhẹ nibẹ ko jẹ ki ọpọlọpọ awọn akẹkọọ wa sile ẹkọ mọ.
“Apẹrẹ ni ijinigbe akẹkọọ 135 nile ẹkọ alakọbẹrẹ Lea ati ile ẹkọ girama ile ẹkọ kan naa ni Kuriga, nijọba ibilẹ Chikun.”
Ẹwẹ, o ti le lọdun mẹwaa ti ipinlẹ Kaduna ti n koju iṣoro ijinigbe ati igbesumọmi.
Kila ni ko si orilẹede to le ni ilọsiwaju ti ọjọ ọla rẹ sile dara lagbaye ti awọn agbebọn ba n da awọn ile ẹkọ rẹ laamu.
O pari ọrọ rẹ pe awọn ẹṣọ alaabo gbọdọ mura siṣẹ wọn lọna ati yanju eto abo to mẹhẹ nipinlẹ naa.















