Ọ̀rọ̀mpọ̀tọ̀níyùn, obìnrin àkọ́kọ́ tó jẹ́ Aláàfin Ọ̀yọ́

Àkọlé fídíò, Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀níyùn, obìnrin àkọ́kọ́ tó jẹ́ Aláàfin Ọ̀yọ́
Ọ̀rọ̀mpọ̀tọ̀níyùn, obìnrin àkọ́kọ́ tó jẹ́ Aláàfin Ọ̀yọ́
Aworan Alaafina kan pẹlu awọn ikọ rẹ

Oríṣun àwòrán, others

Yoruba maa n sọ pe a ko ri iru eyi ri, a fi n dẹru ba ọlọrọ ni, nitori ko si ohun ti ko sẹlẹ ri nitori ko si ohun tuntun kankan labẹ ọrun.

Fun ọpọ eeyan, awọn obinrin kii jọba nilẹ Yoruba, yatọ si awọn ti wọn fi jẹa dle, ti yoo wa nipo oriade naa fun igba diẹ.

Koda, ọpọ lo gba pe obinrin ko le de ipo awọn ọba kan bii ti Alaafin tilu Oyo ati Ooni tilu Ile Ife.

Amọ gẹgẹ ba a ti ka ninu itan nipa awọn nkan to ti sẹlẹ siwaju laye atijọ, awọn obinrin kan ti jẹ Alaafin ati Ooni ri, ti ko si gbọdọ jẹ ajeji si wa mọ lode oni.

Gẹgẹ ba ti ka itan rẹ lori itakun agbaye ati oju opo Wikipedia, Alaafin akọkọ to jẹ obinrin nilu Oyo ni Aláàfin Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn.

Itan naa ni bi ko ba si ẹsẹ, ẹsẹ kii deede sẹ, bẹẹ si ni bi ko ba ni idi, obinrin kii jẹ Kumolu.

Aisi ọkunrin mọ to wa lati idile to n jẹ Alaafin lo fa sababi bi Aláàfin Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn se di ọba lode Ọyọ.

Ta ni Orompotoniyun, obinrin akọkọ to jẹ Alaafin Oyo?

Ibi ti wọn sin Alaafin Ọrọnpọtọniyun si ni ilu Igboho

Apeja orukọ Alaafin obinrin akọkọ nilu Oyo ni Aláàfin Àjíún Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn, to si maa n ki ara rẹ ni 'Ajiun, a rí òbò sẹgun ọ̀tẹ̀'.

Aláàfin Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn jẹ Alaafin ilu Oyo laarin ọdun 1554 si 1562, nigba ti ko si ọkunrin mọ ni idile ọba to lee jẹ Alaafin.

Orukọ baba Aláàfin Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn ni Alaafin Onigbogi, to n gbe ni ilẹ Ibariba, o tẹri gbasọ, ti arole rẹ, Alaafin Ofinran si jọba lẹyin rẹ.

Nigba ti Alaafin ofinran wa lori itẹ, ni wọn pinnu lati kuro ni ilẹ Ibariba lọ si Ọyọ, to si ko awọn eeyan rẹ ati awọn aburo rẹ lọwọ.

Orukọ awọn aburo rẹ naa ni Ọmọọba Eguguoju, Ọmọọbabinrin Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn ati Ọmọọba Ajiboyede.

Ki lo de ti Aláàfin obinrin, Ọ̀rọ̀mpọ̀tọ̀niyùn, se di Alaafin nilu Oyo?

Ilu Igboho

Loju ọna ni Alaafin Ofinran ti waja, ti Alaafin Oguguoju si gori itẹ lẹyin rẹ, oun lo si lewaju awọn eeyan rẹ de ilu Ọyọ Igboho.

Oyo Igboho yii si ni wọn tẹdo si lẹyin irinajo ọlọjọ gbọọrọ, ibẹ naa si Alaafin Oguguoju naa ku si pẹlu.

Ọkunrin to kan to yẹ ko jọba ni Ọmọọba Ajiboyede, amọ ọmọde patapata ni, ti ọkunrin miran to tun wa nilẹ, Ọmọọba Tella Abiipa, si wa lọmọ irakoro.

Ko wa tun si agbalagba ọkunrin miran ni idile Alaafin to lee gun ori itẹ mọ́ afi obinrin nikan soso.

Idi ree ti awọn Ọyọmesi, to jẹ Afọbajẹ, fi pinnu lati mase mu ọmọ oye laarin ara wọn.