Ilé ẹjọ́ gba béèlì mínísítà Buhari, Hadi Sirika pẹ̀lú mílíọ́nù Náírà lórí ẹ̀sùn ṣíṣe ₦2.5bn báṣubàṣu

Sirika ni ile ẹjọ

Ile ẹjọ ti gba beeli minisita tẹlẹ fun igbokegbodo ọkọ labẹ iṣejọba Aarẹ Muhammadu Buaharim Ọgbẹni Hadi Sirika.

Hadi Sirika sọ fun ile ẹjọ ti ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ lorilẹede Naijiria, EFCC gbe e lọ lori ẹsun ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu pe oun ko jẹbi ẹsun mẹfa ti wọn fi kan oun.

Ni Ọjọbọ ni wọn gbe Sirika, Fatima Hadi Sirika to jẹ mọ rẹ, Jalal Hamma to jẹ ọkọ ọmọ rẹ ati ile iẹ kan ti orukọ rẹ n jẹAl-Duraq Investment lọ siwaju Onidajọ Sylvanus Oriji ti ile ẹjọ giga ilu Abuja kan to fi ikalẹ si agbegbe Maitama nilu Abuja.

EFCC ni Hadi Sirika lo ipo rẹ gẹgẹ bi minisita lati fun ọmọ rẹ ati ọkọ ọmọ rẹ nipa gbigbe iṣẹ agbaṣe idasilẹ ileeṣẹ ofurufu Nigeria Air , pẹlu kikọ afikun oju opo igbera ati ibalẹ awọn baluu ni papakọ ofurufu ilu Katsina.

Bi Hadi Sirika ṣe ni oun ko jẹbi ẹsun naa, ni agbẹjọro rẹ, Kanu Agabi rọ ileẹjọ ọhun lati wo ti ipo rẹ lawujọ ki o si gba oniduro rẹ.

Agbẹjọro fun EFCC, Rotimi Jacobs ko tako ẹbẹ fun beeli yii, amọ o ni gbedeke ti ko rọrun ni ki ile ẹjọ gbe kalẹ fun gbigba oniduro rẹ.

Lẹyin awijare awọn mejeeji, ile ẹjọ naa gba lati gba oniduro Hadi Sirika fun ọgọrun miliọnu Naira ati oniduro meji.

Wọn wa sun ẹjọ naa si ọjọ kẹwaa, ikọkanla ati ogunjọ oṣu kẹfa.

Mínísítà Buhari, Hadi Sirika, ọmọ rẹ̀, àtàwọn méjì fojú balé ẹjọ́ fún ẹ̀sùn lílu ₦2.7bn, owó ìlú ní póńpó
Hadi Sirika
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Àjọ tó ń gbógunti ìwà àjẹbánu ní Nàìjíríà ìyẹn Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, ń wọ́ Mínísítà fétò ìrìnnà òfurufú àná ní Nàìjíríà, Hadi Sirika lọ sílé ẹjọ́.

Ní ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹsàn-án, oṣù Kẹrin ọdún 2024 ni ìgbẹ́jọ́ lórí ẹ̀sùn ṣíṣe ₦2.7bn tó wà fún ṣíṣe ètò ìrìnnà òfurufú Nàìjíríà tó fìdí rẹmi yóò wáyé.

Ẹ̀sùn mẹ́fà ni EFCC ń wọ́ Hadi Sirika, ọmọ rẹ̀, Fatimah àtàwọn méjì míì lọ síwájú Adájọ́ Sylvanus Oriji ti ilé ẹjọ́ gíga ìlú Abuja fún.

Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìpéjọ tó tẹ àwọn akọ̀ròyìn lọ́wọ́ ṣe ṣàfihàn, àwọn méjì míì tó ń kojú ìgbẹ́jọ́ pẹ̀lú Hadi Sirika àti ọmọ rẹ̀ ni Jalal Hamma àti ilé iṣẹ́ Al-Buraq Investment Ltd.

EFCC nínú ẹ̀sùn náà fẹ̀sùn kan Sirika pé ó lo ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Mínísítà láti fi ọ̀nà èrú gbé iṣẹ́ àkànṣe fún ọmọ rẹ̀ láàárín oṣù Kẹrin ọdún 2022 sí oṣù Kẹta ọdún 2023.

Wọ́n fẹ̀sùn kan Sirika pé ó fi ọ̀nà èrú gbé àkànṣe iṣẹ́ láti ṣètò ìrìnnà òfurufú Nàìjíríà tí iye rẹ̀ tó ₦1.3bn fún iléeṣẹ́ Tianero Nigeria Limited.

Àjọ tó ń gbógun ti ìwà àjẹbánu náà ní ìwà tí Mínísítà tẹ́lẹ̀ rí náà hù lòdì sí abala kọkàndínlógún, òfin ìwà àjẹbánu àtàwọn tó fara pẹ tọdún 2000.

Nínú ẹ̀sùn míì ni EFCC tún ní Hadi Sirika lọ́jọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kẹjọ ọdún 2022 ló ipò rẹ̀ láti fi gbé àkànṣe iṣẹ́ pápákọ̀ òfurufú ìpínlẹ̀ Katsina tí iye owó rẹ̀ tó ₦1.498bn fún iléeṣẹ́ Al-Buraq Global Investment Limited tó jẹ́ ti ọmọ rẹ̀, Fatima Hadi Sirika àti àna rẹ̀, Jalal Sule Hamma.

Wọ́n ní àwọn ìwà tí Hadi Sirika hù yìí lòdì sí òfin tó sì ní ìjìyà tó tọ́.

Ẹ ó rántí pé ní ìparí oṣù Kẹrin ọdún yìí ni EFCC ránṣẹ́ pé Hadi Sirika tí wọ́n sì fi sí àhámọ́ fún ọjọ́ mélòó kan níbi tí wọ́n ti fọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò.